Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 30

Saamu. Orin. Fún ìyàsímímọ́ Tẹmpili. Ti Dafidi.

30 Èmi yóò kókìkí i rẹ, Olúwa,
    nítorí ìwọ ni ó gbé mi lékè
    tí ìwọ kò sì jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi kí ó yọ̀ mí.
Olúwa Ọlọ́run mi, èmi ké pè ọ́, fún ìrànlọ́wọ́
    ìwọ sì ti wò mí sàn.
Olúwa, ìwọ ti yọ ọkàn mi jáde kúrò nínú isà òkú,
    mú mi padà bọ̀ sípò alààyè kí èmi má ba à lọ sínú ihò.

Kọ orin ìyìn sí Olúwa, ẹ̀yin olódodo;
    kí ẹ sì fi ọpẹ́ fún orúkọ rẹ̀ mímọ́.
Nítorí pé ìbínú rẹ̀ wà fún ìgbà díẹ̀,
    ojúrere rẹ̀ wà títí ayérayé;
Ẹkún lè pẹ́ títí di alẹ́,
    Ṣùgbọ́n ayọ̀ yóò wá ní òwúrọ̀.

Ní ìgbà ayé mi, mo wí pé,
    “a kì yóò ṣí mi ní ipò padà.”
Nípa ojúrere rẹ, Olúwa,
    ìwọ ti gbé mi kalẹ̀ bí òkè tí ó ní agbára;
ìwọ pa ojú rẹ mọ́,
    àyà sì fò mí.

Sí ọ Olúwa, ni mo ké pè é;
    àti sí Olúwa ni mo sọkún fún àánú:
“Èrè kí ni ó wà nínú ikú ìparun mi,
    nínú lílọ sí ihò mi?
Eruku yóò a yìn ọ́ bí?
    Ǹjẹ́ yóò sọ nípa òdodo rẹ?
10 Gbọ́, Olúwa, kí o sì ṣàánú fún mi;
    ìwọ Olúwa, jẹ́ olùrànlọ́wọ́ mi.”

11 Ìwọ ti yí ìkáàánú mi di ijó fún mi;
    ìwọ sì ti bọ́ aṣọ ọ̀fọ̀ mi, o sì fi aṣọ ayọ̀ wọ̀ mí,
12 nítorí ìdí èyí ni kí ọkàn mi máa yìn ọ́, kí o má sì ṣe dákẹ́.
    Ìwọ Olúwa Ọlọ́run mi, èmi yóò máa fi ọpẹ́ fún ọ títí láé.

Lefitiku 13:1-17

Àwọn òfin fún àwọn ààrùn ara tí ó le ràn

13 Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá ní ìwú, èélá tàbí ààmì dídán kan ní ara rẹ̀, èyí tí ó le di ààrùn awọ ara tí ó le ràn ká. Ẹ gbọdọ̀ mú un tọ́ Aaroni àlùfáà lọ tàbí sí ọ̀dọ̀ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀ tí ó jẹ́ àlùfáà. Àlùfáà náà ni ó gbọdọ̀ yẹ egbò ara rẹ̀ wò: bí irun egbò náà bá di funfun tí egbò náà sì dàbí i pé ó jinlẹ̀ kọjá awọ ara: èyí jẹ́ ààrùn ara tí ó le è ràn: Bí àlùfáà bá yẹ̀ ẹ́ wò kí ó sọ ọ́ di mí mọ̀ pé aláìmọ́ ni ẹni náà. Bí àpá ara rẹ̀ bá funfun tí ó sì dàbí ẹni pé kò jinlẹ̀ jù awọ ara, tí irun rẹ̀ kò sì yípadà sí funfun kí àlùfáà fi ẹni náà pamọ́ fún ọjọ́ méje. Ní ọjọ́ keje ni kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò, bí ó bá rí i pé egbò náà wà síbẹ̀ tí kò sì ràn ká àwọ̀ ara, kí ó tún fi pamọ́ fún ọjọ́ méje mìíràn. Ní ọjọ́ keje ni kí àlùfáà tún padà yẹ̀ ẹ́ wò, bí egbò náà bá ti san tí kò sì ràn ká awọ ara rẹ̀. Kí àlùfáà pè é ní mímọ́. Kí ọkùnrin náà fọ aṣọ rẹ̀, yóò sì mọ́ Ṣùgbọ́n bí èélá náà bá ń ràn ká awọ ara rẹ̀ lẹ́yìn ìgbà tí ó ti fi ara rẹ̀ han àlùfáà láti sọ pé ó ti mọ́. Ó tún gbọdọ̀ fi ara rẹ̀ hàn níwájú àlùfáà. Kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò, bí èélá náà bá ràn ká awọ ara rẹ̀, kí àlùfáà fihàn pé kò mọ́. Ààrùn ara tí ń ràn ni èyí.

“Ẹnikẹ́ni tí ó bá ní ààrùn awọ ara tí ń ràn yìí ni kí a mú wá sọ́dọ̀ àlùfáà. 10 Kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò bí ìwú funfun kan bá wà lára rẹ̀: èyí tí ó ti sọ irun ibẹ̀ di funfun: tí a sì rí ojú egbò níbi ìwú náà. 11 Ààrùn ara búburú gbá à ni èyí, kí àlùfáà jẹ́ kí ó di mí mọ̀ pé irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò mọ́: kí ó má ṣe ya ẹni náà sọ́tọ̀ fún àyẹ̀wò torí pé aláìmọ́ ni ẹni náà jẹ́ tẹ́lẹ̀.

12 “Bí ààrùn náà bá ràn yíká gbogbo awọ ara rẹ̀ tí àlùfáà sì yẹ̀ ẹ́ wò, tí ó rí i pé ààrùn náà ti gba gbogbo ara rẹ̀ láti orí títí dé ẹsẹ̀, 13 àlùfáà yóò yẹ̀ ẹ́ wò, bí ààrùn náà bá ti ran gbogbo awọ ara rẹ̀, kí àlùfáà sọ pé ó di mímọ́, torí pé gbogbo ara ẹni náà ti di funfun, ó ti mọ́. 14 Ṣùgbọ́n bí ẹran-ara rẹ̀ bá tún hàn jáde: Òun yóò di àìmọ́. 15 Bí àlùfáà bá ti rí ẹran-ara rẹ̀ kan kí ó pè é ni aláìmọ́. Ẹran-ara rẹ̀ di àìmọ́ torí pé ó ní ààrùn tí ń ràn. 16 Bí ẹran-ara rẹ̀ bá yípadà sí funfun, kí o farahan àlùfáà. 17 Kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò: bí egbò rẹ̀ bá ti di funfun kí àlùfáà pe ẹni náà ni mímọ́. Òun yóò sì di mímọ́.

Heberu 12:7-13

Ẹ máa ní sùúrù lábẹ́ ìbáwí: Ọlọ́run bá wa lò bí ọmọ ni; nítorí pé ọmọ wo ni ń bẹ ti baba kì í bá wí? Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin ba wà láìsí ìbáwí, nínú èyí tí gbogbo ènìyàn ti jẹ alábápín, ǹjẹ́ ọmọ àlè ni yín, ẹ kì í sì ṣe ọmọ. Pẹ̀lúpẹ̀lú àwa ni baba wa nípa ti ara tí o ń tọ́ wa, àwa sì ń bu ọlá fún wọn: kò ha yẹ kí a kúkú tẹríba fún Baba àwọn ẹ̀mí, kí a sì yè? 10 Nítorí wọ́n tọ́ wa fún ọjọ́ díẹ̀ bí o bá ti dára lójú wọn; ṣùgbọ́n òun (tọ́ wa) fún èrè wa, kí àwa lè ṣe alábápín ìwà mímọ́ rẹ̀. 11 Gbogbo ìbáwí kò dàbí ohun ayọ̀ nísinsin yìí bí kò ṣe ìbànújẹ́; ṣùgbọ́n níkẹyìn yóò so èso àlàáfíà fún àwọn tí a tọ́ nípa rẹ̀, àní èso òdodo.

12 (A)Nítorí náà, ẹ na ọwọ́ tí ó rọ, àti eékún àìlera; 13 (B)“Kí ẹ sì ṣe ipa ọ̀nà tí ó tọ́ fún ẹsẹ̀ yin,” kí èyí tí ó rọ má bá a kúrò lórí ike ṣùgbọ́n kí a kúkú wò ó sàn.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.