Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Fún adarí orin. Tí ohùn orin “àgbọ̀nrín òwúrọ̀.” Saamu ti Dafidi.
22 (A)Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí sílẹ̀?
Èéṣe tí o fi jìnnà láti gbà mí là,
àní sí igbe ìkérora mi?
2 Ọlọ́run mi, ní ọ̀sán gangan ni mo kígbe, ṣùgbọ́n ìwọ kò dá mi ní ohùn:
àti ní òru èmi kò dákẹ́.
3 Ṣùgbọ́n síbẹ̀ ẹni mímọ́ ni ìwọ;
ẹni tí ó tẹ ìyìn Israẹli dó;
4 Àwọn baba ńlá wa ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú rẹ;
wọ́n ní ìgbẹ́kẹ̀lé, ìwọ sì gbà wọ́n.
5 Ìwọ ni wọ́n sun ẹkún sí, wọ́n sì ní ìgbàlà;
ìwọ ni wọ́n gbẹ́kẹ̀lé, a kò sì dójútì wọ́n.
6 Ṣùgbọ́n kòkòrò ní mo jẹ́, kì í sì í ṣe ènìyàn;
mo di ẹlẹ́gàn àwọn ènìyàn, ẹlẹ́yà àwọn ènìyàn
7 Gbogbo àwọn tí ó rí mí fi mí ṣe ẹlẹ́yà;
wọ́n yọ ètè ẹ̀gàn wọn sí mi, wọ́n sì ń mi orí wọn pé.
8 “Ó gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé Olúwa;
jẹ́ kí Olúwa gbà á là.
Jẹ́ kí ó gbà á là,
nítorí pé, ó ní ayọ̀ nínú rẹ̀.”
9 Síbẹ̀ ìwọ ni ó ti mú mi wá láti inú;
ìwọ ni ó mú mi wà láìléwu, nígbà tí mo rọ̀ mọ́ ọmú ìyá mi.
10 Ìwọ ni a fi mí lé lọ́wọ́ láti inú ìyá mi wá,
nígbà tí ìyá mí sì ti bí mi, ìwọ ni Ọlọ́run mi.
11 Má ṣe jìnnà sí mi,
nítorí pé ìyọnu súnmọ́ tòsí
kò sì ṣí ẹnìkan tí yóò ṣe ìrànlọ́wọ́.
12 Ọ̀pọ̀ akọ màlúù yí mi ká;
àwọn màlúù alágbára Baṣani rọ̀gbà yí mi ká.
13 Wọ́n ya ẹnu wọn sì mi bí i kìnnìún tí ń dọdẹ kiri,
tí ń ké ramúramù.
14 A dà mí jáde gẹ́gẹ́ bí omi,
gbogbo egungun mi ti yẹ̀ kúrò ní oríkèé rẹ̀.
Ọkàn mi sì dàbí i ìda;
tí ó yọ́ láàrín inú mi.
15 Agbára mí ti gbẹ bí àpáàdì,
ahọ́n mí sì tilẹ̀ mọ́ párí ẹ̀rẹ̀kẹ́ ẹ mi;
ìwọ ti tẹ́ mi sínú eruku ikú.
Ìdáhùn Jobu
17 “Ẹ̀mí mi bàjẹ́,
ọjọ́ mi ni a ti gé kúrú,
isà òkú dúró dè mí.
2 Nítòótọ́ àwọn ẹlẹ́yà wà lọ́dọ̀ mi,
ojú mi sì tẹ̀mọ́ ìmúnibínú wọn.
3 “Fi fún mi Olúwa, ìlérí tí ìwọ fẹ́;
ta ni yóò le ṣe ààbò fún mi?
4 Nítorí pé ìwọ ti sé wọ́n láyà kúrò nínú òye;
nítorí náà ìwọ kì yóò gbé wọn lékè.
5 Ẹni tí ó sọ ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn dídún fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ fún èrè,
òun ni ojú àwọn ọmọ rẹ̀ yóò mú òfo.
6 “Ọlọ́run ti sọ mi di ẹni òwe fún àwọn ènìyàn;
níwájú wọn ni mo dàbí ẹni ìtutọ́ sí ní ojú.
7 Ojú mí ṣú bàìbàì nítorí ìbìnújẹ́,
gbogbo ẹ̀yà ara mi sì dàbí òjìji.
8 Àwọn olódodo yóò yanu sí èyí,
ẹni aláìṣẹ̀ sì bínú sí àwọn àgàbàgebè.
9 Olódodo pẹ̀lú yóò di ọ̀nà rẹ̀ mú,
àti ọlọ́wọ́ mímọ́ yóò máa lera síwájú.
10 “Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti gbogbo yín,
ẹ yípadà, kí ẹ si tún padà nísinsin yìí;
èmi kò le rí ọlọ́gbọ́n kan nínú yín.
11 Ọjọ́ tí èmi ti kọjá, ìrò mi ti fà yá,
àní ìrò ọkàn mi.
12 Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ń ṣọ́ òru di ọ̀sán;
wọ́n ní, ìmọ́lẹ̀ súnmọ́ ibi tí òkùnkùn dé.
13 Bí mo tilẹ̀ ní ìrètí, ipò òku ní ilé mi;
mo ti tẹ́ ibùsùn mi sínú òkùnkùn.
14 Èmi ti wí fún ìdíbàjẹ́ pé, ìwọ ni baba mi,
àti fún kòkòrò pé, ìwọ ni ìyá mi àti arábìnrin mi,
15 ìrètí mi ha dà nísinsin yìí?
Bí ó ṣe ti ìrètí mi ni, ta ni yóò rí i?
16 Yóò sọ̀kalẹ̀ lọ sínú ipò òkú,
nígbà tí a jùmọ̀ sinmi pọ̀ nínú erùpẹ̀ ilẹ̀?”
Ìkìlọ̀ fún aláìgbàgbọ́
7 (A)Nítorí náà gẹ́gẹ́ bi Ẹ̀mí Mímọ́ tí wí:
“Lónìí bí ẹ̀yin bá gbọ́ ohùn rẹ̀,
8 Ẹ má ṣe sé ọkàn yín le,
bí ìgbà ìṣọ̀tẹ̀,
bí i ní ọjọ́ ìdánwò ní aginjù:
9 Níbi tí àwọn baba yín ti dán mi wò,
tí wọ́n sì rí iṣẹ́ mi ní ogójì ọdún.
10 Nítorí náà a mú inú bí mi si ìran náà,
mo sì wí pé, ‘Nígbà gbogbo ni wọn ṣìnà ní ọkàn wọn;
wọn kò sì mọ ọ̀nà mi.’
11 Bí mo tí búra nínú ìbínú mi,
‘wọn kí yóò wọ inú ìsinmi mi.’ ”
12 Ẹ kíyèsára, ará, kí ọkàn búburú ti àìgbàgbọ́ má ṣe wà nínú ẹnikẹ́ni yín, ní lílọ kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run alààyè. 13 Ṣùgbọ́n ẹ máa gba ara yín ní ìyànjú ní ojoojúmọ́, níwọ̀n ìgbà tí a bá ń pè ní “Òní,” kí a má ba à sé ọkàn ẹnikẹ́ni nínú yín le nípa ẹ̀tàn ẹ̀ṣẹ̀. 14 Nítorí àwa di alábápín pẹ̀lú Kristi, bí àwa bá di ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìgbẹ́kẹ̀lé wa mú ṣinṣin títí dé òpin; 15 (B)Nígbà tí a ń wí pé:
“Lónìí bí ẹ̀yin bá gbọ́ ohùn rẹ̀,
ẹ má sé ọkàn yin le,
bí ìgbà ìṣọ̀tẹ̀.”
16 (C)Àwọn ta ni ó gbọ́ tí ó sì tún ṣọ̀tẹ̀? Kì í ha ṣe gbogbo àwọn tí o jáde kúrò ní Ejibiti ní abẹ́ àkóso Mose? 17 (D)Àwọn ta ni ó sì bínú sí fún ogójì ọdún? Kì í ha ṣe sí àwọn tí ó dẹ́ṣẹ̀, òkú àwọn tí ó sùn ní aginjù? 18 Àwọn wo ni ó búra fún pé wọn kì yóò wọ inú ìsinmi òun, bí kò ṣe fún àwọn tí ó ṣe àìgbọ́ràn? 19 Àwa sì rí i pé wọn kò lè wọ inú rẹ̀ nítorí àìgbàgbọ́.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.