Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 73:1-20

ÌWÉ KẸTA

Saamu 73–89

Saamu ti Asafu.

73 Nítòótọ́ Ọlọ́run dára fún Israẹli,
    fún àwọn ọlọ́kàn funfun.

Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti èmi, ẹsẹ̀ mi ti yẹ̀ tán;
    ìrìn mi fẹ́rẹ̀ yọ̀ tán.
Nítorí èmi ń ṣe ìlara àwọn tó ń ṣe féfé
    nígbà tí mo bá rí àlàáfíà àwọn ènìyàn búburú.

Wọn kò ṣe wàhálà;
    ara wọn mókun wọn sì lágbára.
Wọn kò ní ìpín nínú àjàgà tó ń ṣẹlẹ̀ sí ènìyàn;
    a kò pọ́n wọn lójú nípa ẹlòmíràn.
Ìgbéraga ni ọ̀ṣọ́ ọrùn wọn;
    ìwà ipá bò wọ́n mọ́lẹ̀ bí aṣọ.
Láti inú ọkàn àrékérekè ni àìṣòdodo ti wá;
    ẹ̀rí ọkàn búburú wọn kò ní òdínwọ̀n
Wọn ń ṣẹ̀sín, wọn sì ń sọ̀rọ̀-òdì ní ti
    ìnilára, wọ́n ń sọ̀rọ̀ láti ibi gíga.
Wọ́n ń gbé ẹ̀mí wọn lé ọ̀run
    ahọ́n wọn gba ipò ayé.
10 Nítorí náà àwọn ènìyàn wọn yípadà sí wọn
    wọ́n sì mu omi ní ọ̀pọ̀lọpọ̀.
11 Wọ́n wí pé, “Báwo ni Ọlọ́run yóò ṣe mọ̀?
    Ọ̀gá-ògo ha ní ìmọ̀ bí?”

12 Bí àwọn ènìyàn búburú ṣe rí nìyí
    ènìyàn asán, wọ́n ń pọ̀ ní ọrọ̀.

13 Nítòótọ́ nínú asán ni mo pa ọkàn mi mọ́;
    nínú asán ni mo wẹ ọwọ́ mi ní àìlẹ́ṣẹ̀.
14 Ní gbogbo ọjọ́ ni a ń yọ mí lẹ́nu;
    a sì ń jẹ mí ní yà ní gbogbo òwúrọ̀.

15 Bí mo bá wí pé, “Èmi ó wí báyìí,”
    Èmi ó ṣẹ̀ sí ìran àwọn ọmọ rẹ̀.
16 Nígbà tí mo gbìyànjú láti mọ èyí,
    Ó jẹ́ ìnilára fún mi.
17 Títí mo fi wọ ibi mímọ́ Ọlọ́run;
    Nígbà náà ni òye ìgbẹ̀yìn wọn yé mi.

18 Lóòtítọ́ ìwọ gbé wọn lórí ilẹ̀ yíyọ́
    ìwọ jù wọ́n sílẹ̀ sínú ìparun.
19 Báwo ní a ti mú wọn lọ sínú ìdahoro yìí
    bí ẹni pé ní ìṣẹ́jú kan!
Ìbẹ̀rù ni a fi ń run wọ́n pátápátá!
20 Bí àlá nígbà tí ènìyàn bá jí,
    bẹ́ẹ̀ ni nígbà tí ìwọ bá dìde, Olúwa,
    ìwọ yóò ṣe àbùkù àwòrán wọn.

Òwe 8:32-9:6

32 “Nítorí náà báyìí, ẹ̀yin ọmọ mi,
    ìbùkún ni fún àwọn tí ó pa ọ̀nà mi mọ́,
33 Fetí sí ìtọ́sọ́nà mi kí o sì gbọ́n;
    má ṣe pa á tì sápá kan.
34 Ìbùkún ni fún ẹni tí ó fetísílẹ̀ sí mi,
    tí ń ṣọ́nà ní ẹnu-ọ̀nà mi lójoojúmọ́,
    tí ń dúró ní ẹnu-ọ̀nà mi.
35 Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá rí mi rí ìyè
    ó sì rí ojúrere gbà lọ́dọ̀ Olúwa.
36 Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ̀ láti rí ń pa ara rẹ̀ lára
    gbogbo ẹni tí ó kórìíra mi fẹ́ ikú.”

Ìpè ti ọgbọ́n àti àìgbọ́n

Ọgbọ́n ti kọ́ ilé rẹ̀,
    ó ti gbẹ́ òpó o rẹ̀ méjèèjì,
ó ti fi ilé pọn tí, ó ti fọ̀nà rokà.
    Ó sì ti ṣètò o tábìlì oúnjẹ rẹ̀
ó ti rán àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ jáde, ó sì ń pè,
    láti ibi tí ó ga jù láàrín ìlú.
“Jẹ́ kí gbogbo àwọn aláìgbọ́n wọ ibí wá!”
    Ó ń wí fún àwọn tí kò lọ́gbọ́n pé
“Wá, ẹ wá fẹ́ oúnjẹ mi
    sì mu wáìnì tí mo ti pò.
Fi ìwà àìmọ̀kan rẹ sílẹ̀ ìwọ yóò sì yè;
    rìn ní ọ̀nà òye.

Heberu 11:29-12:2

29 (A)Nípa ìgbàgbọ́ ni wọn la Òkun pupa kọjá bi ẹni pé ni ìyàngbẹ ilẹ̀: ti àwọn ara Ejibiti dánwò, tí wọ́n sì ri.

30 (B)Nípa ìgbàgbọ́ ni àwọn odi Jeriko wo lulẹ̀, lẹ́yìn ìgbà tí a yí wọn ká ni ọjọ́ méje.

31 (C)Nípa ìgbàgbọ́ ni Rahabu panṣágà kò ṣègbé pẹ̀lú àwọn tí kò gbọ́rọ̀ nígbà tí o tẹ́wọ́gbà àwọn ààmì ní àlàáfíà.

32 (D)Èwo ni èmi o sì tún máa wí sí i? Nítorí pé ìgbà yóò kùnà fún mi láti sọ ti Gideoni, àti Baraki, àti Samsoni, àti Jefta; àti Dafidi, àti Samuẹli, àti ti àwọn wòlíì: 33 (E)Àwọn ẹni nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ tiwọn ṣẹ́gun ilẹ̀ ọba, tí wọn ṣiṣẹ́ òdodo, tiwọn gba ìlérí, tiwọn dí àwọn kìnnìún lénu, 34 (F)Tí wọ́n pa agbára iná, tí wọ́n bọ́ lọ́wọ́ ojú idà, tí a sọ di alágbára nínú àìlera, tí wọ́n dí akọni nínú ìjà, wọ́n lé ogun àwọn àjèjì sá. 35 (G)Àwọn obìnrin ri òkú wọn gbà nípa àjíǹde: a sì da àwọn ẹlòmíràn lóró, wọ́n kọ̀ láti gba ìdásílẹ̀; kí wọn ba lè rí àjíǹde tí o dára jù gbà; 36 Àwọn ẹlòmíràn sì rí ìjìyà ẹ̀sín, àti nínà, àti ju bẹ́ẹ̀ lọ, ti ìdè àti ti túbú: 37 A sọ wọ́n ni òkúta, a fi ayùn rẹ́ wọn sì méjì, a dán wọn wò a fi idà pa wọn: wọ́n rìn káàkiri nínú awọ àgùntàn àti nínú awọ ewúrẹ́; wọn di aláìní, olùpọ́njú, ẹni tí a ń da lóró; 38 Àwọn ẹni tí ayé ko yẹ fún: Wọ́n ń kiri nínú aṣálẹ̀, àti lórí òkè, àti nínú ihò àti nínú abẹ́ ilẹ̀.

39 Gbogbo àwọn wọ̀nyí tí a jẹ́rìí rere sí nípa ìgbàgbọ́, wọn kò sì rí ìlérí náà gbà: 40 Nítorí Ọlọ́run ti pèsè ohun tí ó dára jù sílẹ̀ fún wa, pé láìsí wa, kí a má ṣe wọn pé.

Ìbáwí àwọn ọmọ Ọlọ́run

12 Nítorí náà bí a ti fi ìkùùkuu àwọsánmọ̀ tí o kún fún àwọn ẹlẹ́rìí tó báyìí yí wa ká, ẹ jẹ́ kí a pa ohun ìdíwọ́ gbogbo tì sí apá kan, àti ẹ̀ṣẹ̀ tí o rọrùn láti di mọ́ wa, kí a sì máa fi sùúrù súré ìje tí a gbé ka iwájú wa, (H)Kí a máa wo Jesu Olùpilẹ̀ṣẹ̀ àti aláṣepé ìgbàgbọ́ wa; ẹni nítorí ayọ̀ tí a gbé ka iwájú rẹ, tí o faradà àgbélébùú láìka ìtìjú sí, tí ó sì jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọlọ́run.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.