Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Fún adarí orin. Tí ohun orin “Lílì.” Ti orin àwọn ọmọ Kora. Maskili. Orin ìgbéyàwó.
45 Ọkàn mi mọ ọ̀rọ̀ rere
gẹ́gẹ́ bí mo ṣe ń sọ ohun tí mo ti ṣe fún ọba
ahọ́n mi ni kálámù ayára kọ̀wé.
2 Ìwọ yanjú ju àwọn ọmọ ènìyàn lọ:
a da oore-ọ̀fẹ́ sí ọ ní ètè:
nítorí náà ni Ọlọ́run ṣe bùkún fún ọ láéláé.
6 (A)Ọlọ́run láé, àti láéláé ni ìtẹ́ rẹ,
ọ̀pá aládé ìjọba rẹ, ọ̀pá aládé òtítọ́ ni.
7 Ìwọ fẹ́ olódodo, ìwọ sì kórìíra ìwà búburú
nígbà náà Ọlọ́run, Ọlọ́run rẹ ti yàn ọ́ ṣe olórí àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ,
nípa fífi ààmì òróró ayọ̀ kùn ọ́.
8 Gbogbo aṣọ rẹ̀ ni ó ń rùn pẹ̀lú òjìá àti aloe àti kasia;
láti inú ààfin tí a fi eyín erin ṣe
orin olókùn tẹ́ẹ́rẹ́ mú inú rẹ̀ dùn.
9 Àwọn ọmọbìnrin àwọn ọba
wà nínú àwọn àyànfẹ́ rẹ̀,
ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ni ayaba náà gbé dúró
nínú wúrà ofiri.
1 Orin àwọn orin tí í ṣe orin Solomoni.
Olólùfẹ́
2 Fi ìfẹnukonu ìfẹ́ kò mí ní ẹnu,
nítorí ìfẹ́ rẹ dára ju ọtí wáìnì lọ.
3 Òórùn ìkunra rẹ fanimọ́ra.
Orúkọ rẹ rí bí ìkunra tí a tú jáde
abájọ tí àwọn wúńdíá fi fẹ́ ọ.
4 Fà mí lọ pẹ̀lú rẹ, kí a lọ kíákíá
ọba ti mú mi wá sínú yàrá rẹ̀.
Ọ̀rẹ́
Àwa yọ̀ inú wa sì dùn sí ọ;
a gbé ìfẹ́ rẹ ga ju ọtí wáìnì lọ.
Olólùfẹ́
Wọ́n fẹ́ ọ nítòótọ́!
5 Èmi dúdú mo sì ní ẹwà.
Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu
dúdú bí àgọ́ Kedari,
bí aṣọ títa ti Solomoni
6 Má ṣe wò mí nítorí wí pé mo dúdú,
nítorí oòrùn mú mi dúdú,
ọmọkùnrin ìyá mi bínú sí mi
ó sì fi mí ṣe olùtọ́jú ọgbà àjàrà;
ọgbà àjàrà tèmi ni èmi kò tọ́jú.
7 Wí fún mi, ìwọ ẹni tí ọkàn mí fẹ́,
níbo ni ìwọ ń da agbo ẹran lọ.
Níbi tí ìwọ mú agbo ẹran rẹ sinmi ní ọ̀sán,
kí ni ìdí tí èmi yóò fi jẹ́ obìnrin asán
ní ẹ̀bá agbo ẹran àwọn ọ̀rẹ́ rẹ.
Ọ̀rẹ́
8 Bí ìwọ kò bá mọ̀,
ìwọ arẹwà jùlọ nínú àwọn obìnrin.
Bá ọ̀nà tí agbo ẹran rìn lọ,
kí o sì bọ́ àwọn ọmọ ewúrẹ́ rẹ.
Ní ẹ̀bá àgọ́ àwọn olùṣọ́-àgùntàn.
Olùfẹ́
9 Olùfẹ́ mi,
mo fi ọ́ wé ẹṣin mi nínú kẹ̀kẹ́ Farao.
10 Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ dára ní ohun ọ̀ṣọ́,
ọrùn rẹ sì yẹ ọ̀ṣọ́ ìlẹ̀kẹ̀
11 A ó fi wúrà ṣe òrùka etí fún ọ,
a ó fi fàdákà ṣe ìlẹ̀kẹ̀.
Olólùfẹ́
12 Nígbà tí ọba wà ní orí ìjókòó rẹ̀,
òróró ìkunra mi tú òórùn jáde.
13 Ìdì òjìá ni olùfẹ́ mi jẹ sí mi,
òun ó sinmi lé àárín ọmú mi.
14 Bí ìdì ìtànná Henina ni olùfẹ́ mi rí sí mi
láti inú ọgbà àjàrà ti En-Gedi.
Olólùfẹ́
15 Báwo ni o ti lẹ́wà tó, olólùfẹ́ mi!
Háà, Báwo ni o ṣe lẹ́wà tó!
Ìwọ ní ojú ẹyẹlé.
Olólùfẹ́
16 Báwo ni o ṣe dára tó, olùfẹ́ mi!
Háà, Báwo ni o ṣe wu ni!
Ibùsùn wa ní ìtura.
Olùfẹ́
17 Ìtànṣán ilé wa jẹ́ ti igi kedari
ẹkẹ́ ilé wa jẹ́ ti igi firi.
1 Jakọbu, ìránṣẹ́ Ọlọ́run àti ti Jesu Kristi Olúwa,
Sí àwọn ẹ̀yà méjìlá tí ó fọ́n káàkiri, orílẹ̀-èdè.
Àlàáfíà.
Àwọn ìṣòro àti àwọn ìdánwò
2 Ẹ̀yin ará mi, nígbà tí ẹ̀yin bá bọ́ sínú onírúurú ìdánwò, ẹ ka gbogbo rẹ̀ sí ayọ̀; 3 nítorí tí ẹ̀yin mọ̀ pé, ìdánwò ìgbàgbọ́ yín ń ṣiṣẹ́ sùúrù. 4 Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí sùúrù kí ó ṣiṣẹ́ àṣepé, kí ẹ̀yin kí ó lè jẹ́ pípé àti aláìlábùkù tí kò ṣe aláìní ohunkóhun. 5 Bí ó bá ku ọgbọ́n fún ẹnikẹ́ni, kí ó béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run ẹni tí fi fún gbogbo ènìyàn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀, tí kì í sì ka àlébù sí; a ó sì fi fún un. 6 Ṣùgbọ́n nígbà tí òun bá béèrè ní ìgbàgbọ́, ní àìṣiyèméjì rárá. Nítorí ẹni tí ó ń sé iyèméjì dàbí ìgbì omi Òkun, tí à ń ti ọwọ́ afẹ́fẹ́ bì síwá bì sẹ́yìn, tí a sì ń rú u sókè. 7 Kí irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ má ṣe rò pé, òun yóò rí ohunkóhun gbà lọ́wọ́ Olúwa; 8 Ó jẹ ènìyàn oníyèméjì aláìlèdúró ní ọ̀nà rẹ̀ gbogbo.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.