Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Fún adarí orin. Ti Dafidi.
11 Ìgbẹ́kẹ̀lé mi wà nínú Olúwa.
Báwo ní ẹ̀yin ó ṣe sọ fún ọkàn mi pé:
“Fò gẹ́gẹ́ bi ẹyẹ lọ si orí òkè rẹ.
2 Wò ó nítorí náà, ènìyàn búburú fa ọfà rẹ̀;
wọn ti fi ọfà wọn sí ojú okùn
láti tafà níbi òjìji
sí àyà ẹni ìdúró ṣinṣin.
3 Nígbà tí ìpìlẹ̀ bá bàjẹ́
kí ni olódodo yóò ṣe?”
4 Olúwa ń bẹ nínú tẹmpili mímọ́ rẹ̀;
Olúwa ń bẹ lórí ìtẹ́ rẹ̀ ní ọ̀run.
Ó ń wo àwọn ọmọ ènìyàn;
ojú rẹ̀ ń yẹ̀ wọ́n wò.
5 Olúwa ń yẹ olódodo wò,
ṣùgbọ́n ènìyàn búburú àti àwọn tí o fẹ́ ìwà ipá
ni ọkàn rẹ̀ kórìíra.
6 Sí orí àwọn ènìyàn búburú ni yóò rọ̀jò
ẹ̀yín iná àti imí-ọjọ́ tí ń jó;
àti ìjì gbígbóná ní yóò jẹ ìpín wọn.
7 Nítorí, olódodo ní Olúwa,
o fẹ́ràn òdodo;
ẹni ìdúró ṣinṣin yóò sì rí i.
13 Solomoni ọba sì ṣa asìnrú ènìyàn jọ ní gbogbo Israẹli; àwọn tí ń sìnrú náà jẹ́ ẹgbàá-mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ènìyàn (30,000). 14 Ó sì rán wọn lọ sí Lebanoni, ẹgbàárùn-ún (10,000) lóṣooṣù, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n lo oṣù kan ní Lebanoni, wọn a sì gbé ilé ní oṣù méjì. Adoniramu ni ó ṣe olórí àwọn asìnrú náà. 15 (A)Solomoni sì ní ẹgbàá-márùn-dínlógójì (70,000) ènìyàn tí ń ru ẹrù àti ọ̀kẹ́ mẹ́rin (80,000) gbẹ́nàgbẹ́nà lórí òkè, 16 àti àwọn ìjòyè nínú àwọn tí a fi ṣe olórí iṣẹ́ Solomoni jẹ́ ẹgbẹ̀rìndínlógún ó-lé-ọgọ́rùn-ún (3,300) ènìyàn, tí ó ń ṣe aláṣẹ àwọn ènìyàn tí ń ṣiṣẹ́ náà. 17 Ọba sì pàṣẹ, wọ́n sì mú òkúta wá, òkúta iyebíye, àti òkúta gbígbẹ́ láti fi ìpìlẹ̀ ilé náà lé ilẹ̀. 18 Àwọn oníṣọ̀nà Solomoni àti Hiramu àti àwọn òṣìṣẹ́ láti Gebali sì gbẹ́ wọn, wọ́n sì pèsè igi àti òkúta láti fi kọ́ ilé náà.
Àwọn aya àti ọkọ
21 Ẹ máa tẹríba fún ara yín ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run.
22 (A)Ẹ̀yin aya, ẹ máa tẹríba fún àwọn ọkọ yín, gẹ́gẹ́ bí fún Olúwa. 23 Nítorí pé ọkọ ni ó ń ṣe orí aya, gẹ́gẹ́ bí Kristi tí i ṣe orí ìjọ, tí òun si ń ṣe ara rẹ̀, Òun sì ni Olùgbàlà rẹ̀. 24 Nítorí náà gẹ́gẹ́ bí ìjọ tí i tẹríba fún Kristi, bẹ́ẹ̀ sì ní kì àwọn aya máa ṣe sí ọkọ wọn ní ohun gbogbo.
25 Ẹ̀yin ọkọ, ẹ fẹ́ràn àwọn aya yín, gẹ́gẹ́ bí Kristi tí fẹ́ràn ìjọ, tí ó sì fi ara rẹ̀ fún un. 26 Kí òun lè sọ ọ́ di mímọ́ lẹ́yìn tí ó tí fi ọ̀rọ̀ wẹ̀ ẹ́ nínú agbada omí. 27 Kí òun lé mú un wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀ bí ìjọ tí ó ní ògo ní àìlábàwọ́n, tàbí àlébù kan, tàbí irú nǹkan bá-wọ̀n-ọn-nì: ṣùgbọ́n kí ó lè jẹ́ mímọ́ àti aláìlábùkù. 28 Bẹ́ẹ̀ ní ó tọ́ kí àwọn ọkùnrin máa fẹ́ràn aya wọn gẹ́gẹ́ bí ara àwọn fúnrawọn. 29 Nítorí kò sì ẹnìkan tí ó ti kórìíra ara rẹ̀; bí kò ṣe pé kí ó máa bọ́ ọ kí ó sì máa ṣìkẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Kristi sì ti ń ṣe sí ìjọ. 30 Nítorí pé àwa ni ẹ̀yà ara rẹ̀, àti tí ẹran-ara rẹ̀, àti egungun ara rẹ̀. 31 (B)Nítorí èyí ní ọkùnrin yóò fi baba àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, òun yóò sì dàpọ̀ mọ́ aya rẹ̀, àwọn méjèèjì yóò sì di ara kan. 32 Àṣírí ńlá ní èyí: ṣùgbọ́n èmí ń sọ nípá ti Kristi àti tí ìjọ. 33 Ṣùgbọ́n kí olúkúlùkù yín fẹ́ràn aya rẹ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òun fúnrarẹ̀; kí aya kí ó sì bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀.
Àwọn ọmọ àti àwọn òbí
6 Ẹ̀yin ọmọ, ẹ máa gbọ́ tí àwọn òbí i yín nínú Olúwa: nítorí pé èyí ní ó tọ́. 2 (C)“Bọ̀wọ̀ fún baba àti ìyá rẹ,” èyí tí í ṣe òfin kìn-ín-ní pẹ̀lú ìlérí, 3 (D)“ki ó lé dára fún ọ, àti kí ìwọ lè wà pẹ́ ní ayé.”
4 Àti ẹ̀yin baba, ẹ má ṣe mú àwọn ọmọ yín bínú, ṣùgbọ́n ẹ máa tọ́ wọn nínú ẹ̀kọ́ àti ìkìlọ̀ Olúwa.
Àwọn ẹrú àti olówó wọn
5 Ẹ̀yin ọmọ ọ̀dọ̀, ẹ máa gbọ́ ti àwọn olúwa yín nípá ti ara, pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìwárìrì, nínú òtítọ́ ọkàn yín, bí ẹni pé sí Kristi. 6 Gbọ́ ọ̀rọ̀ sí wọn lẹ́nu kì í ṣe láti rí ojúrere wọn nígbà tí ojú wọn bá ń bẹ lára rẹ, ṣùgbọ́n bí ẹrú Kristi, ní ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run láti inú ọkàn rẹ. 7 Ẹ máa fi gbogbo ọkàn yin ṣe iṣẹ́ ìsìn bí sí Olúwa, kì í sí ṣe sí ènìyàn. 8 Bí ẹ̀yin ti mọ̀ pé ohun rere tí olúkúlùkù bá ṣe òun náà ní yóò sí gbà padà lọ́dọ̀ Olúwa, ìbá à ṣe ẹrú, tàbí òmìnira.
9 Àti ẹ̀yin ọ̀gá, ẹ máa ṣe irú ìtọ́jú kan náà sí àwọn ẹrú yin, ẹ máa dín ìbẹ̀rù yín kù bí ẹ̀yin ti mọ̀ pé Olúwa ẹ̀yin tìkára yín ń bẹ ní ọ̀run; kò sì ṣí ojúsàájú ènìyàn lọ́dọ̀ rẹ̀.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.