Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 24

Ti Dafidi. Saamu.

24 (A)Ti Olúwa ni ilẹ̀, àti ẹ̀kún rẹ̀,
    ayé àti àwọn tí ó tẹ̀dó sínú rẹ̀;
Nítorí ó fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀ lórí Òkun
    ó sì gbé e kalẹ̀ lórí àwọn ìṣàn omi.

Ta ni yóò gun orí òkè Olúwa lọ?
    Ta ni yóò dúró ní ibi mímọ́ rẹ̀?
(B)Ẹni tí ó ní ọwọ́ mímọ́ àti àyà funfun,
    ẹni tí kò gbé ọkàn rẹ̀ sókè sí asán
    tí kò sì búra èké.

Òun ni yóò rí ìbùkún gbà láti ọ̀dọ̀ Olúwa,
    àti òdodo lọ́wọ́ Ọlọ́run ìgbàlà rẹ̀.
Èyí ni ìran àwọn tí ń ṣe àfẹ́rí rẹ̀,
    tí ń ṣe àfẹ́rí rẹ̀, Ọlọ́run Jakọbu. Sela.

Ẹ gbé orí yín sókè, háà! Ẹ̀yin ọ̀nà;
    Kí á sì gbe yín sókè, ẹyin ìlẹ̀kùn ayérayé!
    Kí ọba ògo le è wọlé.
Ta ni ọba ògo náà?
    Olúwa tí ó lágbára tí ó sì le,
    Olúwa gan an, tí ó lágbára ní ogun.
Gbé orí yín sókè, ẹyin ọ̀nà;
    kí a sì gbé e yín sókè, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn ayérayé,
    kí Ọba ògo le è wọlé wá.
10 Ta ni Ọba ògo náà?
    Olúwa àwọn ọmọ-ogun
    Òun ni Ọba ògo náà. Sela.

Numeri 10:11-36

Àwọn ọmọ Israẹli kúrò ní Sinai

11 Ní ogúnjọ́ oṣù kejì, ní ọdún kejì ni ìkùùkuu kúrò lórí tabanaku ẹ̀rí. 12 Àwọn ọmọ Israẹli sì gbéra kúrò ní aginjù Sinai wọ́n sì rin ìrìnàjò wọn káàkiri títí tí ìkùùkuu fi dúró sí aginjù Parani. 13 Wọ́n gbéra nígbà àkọ́kọ́ yìí nípa àṣẹ Olúwa láti ẹnu Mose.

14 Àwọn ìpín ti ibùdó Juda ló kọ́kọ́ gbéra tẹ̀lé wọn lábẹ́ ogun wọn Nahiṣoni ọmọ Amminadabu ni ọ̀gágun wọn. 15 Netaneli ọmọ Ṣuari ni ọ̀gágun ti ẹ̀yà Isakari; 16 Eliabu ọmọ Heloni ni ọ̀gágun ni ìpín ti ẹ̀yà Sebuluni. 17 Nígbà náà ni wọ́n sọ tabanaku kalẹ̀ àwọn ọmọ Gerṣoni àti Merari tó gbé àgọ́ sì gbéra.

18 Àwọn ìpín ti ibùdó ti Reubeni ló gbéra tẹ̀lé wọn, lábẹ́ ọ̀págun wọn. Elisuri ọmọ Ṣedeuri ni ọ̀gágun wọn. 19 Ṣelumieli ọmọ Suriṣaddai ni ọ̀gágun ti ẹ̀yà Simeoni. 20 Eliasafu ọmọ Deueli ni ọ̀gágun ìpín ti ẹ̀yà Gadi. 21 Nígbà náà ni àwọn ọmọ Kohati tí ń ru ohun mímọ́ náà gbéra. Àwọn ti àkọ́kọ́ yóò sì ti gbé tabanaku dúró kí wọn tó dé.

22 Àwọn ìpín tó wà ní ibùdó Efraimu ló tún kàn lábẹ́ ọ̀págun wọn. Eliṣama ọmọ Ammihudu ni ọ̀gágun wọn. 23 Gamalieli ọmọ Pedasuri ni ọ̀gágun ìpín ti ẹ̀yà Manase. 24 Abidani ọmọ Gideoni ni ọ̀gágun ìpín ti ẹ̀yà Benjamini.

25 Lákòótan, àwọn ọmọ-ogun tó ń mójútó ẹ̀yìn ló tún kàn, àwọn ni ìpín ti ibùdó Dani lábẹ́ ọ̀págun wọn. Ahieseri ọmọ Ammiṣaddai ni ọ̀gágun wọn. 26 Pagieli ọmọ Okanri ni ìpín ti ẹ̀yà Aṣeri, 27 Ahira ọmọ Enani ni ọ̀gágun ti ẹ̀yà Naftali; 28 Báyìí ni àwọn ọmọ Israẹli ṣe tò jáde gẹ́gẹ́ bí ogun nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò wọn.

29 Mose sì sọ fún Hobabu ọmọ Reueli ará Midiani tí í ṣe àna rẹ̀ pé, “A ń gbéra láti lọ sí ibi tí Olúwa sọ pé, ‘Èmi ó fi fún un yín.’ Bá wa lọ, àwa ó ṣe ọ́ dáradára nítorí pé Olúwa ti ṣèlérí ohun rere fún Israẹli.”

30 Ó sì dáhùn pé, “Rárá, èmi kò ní bá yín lọ, mò ń padà lọ sí ilẹ̀ mi àti sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn mi.”

31 Mose sì sọ pé, “Jọ̀wọ́ ma fi wá sílẹ̀, ìwọ mọ ibi tí a lè pa ibùdó sí nínú aginjù, ìwọ yóò sì jẹ́ ojú fún wa. 32 Bí o bá bá wa lọ, a ó sì pín fún ọ nínú ohun rere yówù tí Olúwa bá fún wa.”

33 Wọ́n sì gbéra láti orí òkè Olúwa ní ìrìn ọjọ́ mẹ́ta. Àpótí ẹ̀rí Olúwa ń lọ níwájú wọn fún gbogbo ọjọ́ mẹ́ta yìí láti wá ibi ìsinmi fún wọn. 34 Ìkùùkuu Olúwa wà lórí wọn lọ́sàn nígbà tí wọ́n gbéra kúrò ní ibùdó.

35 (A)Nígbàkígbà tí àpótí ẹ̀rí bá gbéra Mose yóò sì wí pé,

“Dìde, Olúwa!
    Kí a tú àwọn ọ̀tá rẹ ká,
    kí àwọn tí ó kórìíra rẹ sì sálọ níwájú rẹ.”

36 Nígbàkígbà tí àpótí ẹ̀rí bá sinmi yóò wí pé;

“Padà, Olúwa,
    Sọ́dọ̀ àwọn àìmoye ẹgbẹẹgbẹ̀rún Israẹli.”

Luku 1:57-80

Ìbí Johanu onítẹ̀bọmi

57 Nígbà tí ọjọ́ Elisabeti pé tí yóò bí; ó sì bí ọmọkùnrin kan. 58 Àwọn aládùúgbò, àti àwọn ìbátan rẹ̀ gbọ́ bí Olúwa ti fi àánú ńlá hàn fún un, wọ́n sì bá a yọ̀.

59 (A)Ó sì ṣe, ní ọjọ́ kẹjọ wọ́n wá láti kọ ọmọ náà nílà; wọ́n sì fẹ́ sọ orúkọ rẹ̀ ní Sekariah, gẹ́gẹ́ bí orúkọ baba rẹ̀. 60 Ìyá rẹ̀ sì dáhùn, ó ní, “Bẹ́ẹ̀ kọ́! Johanu ni a ó pè é.”

61 Wọ́n sì wí fún un pé, “Kò sí ọ̀kan nínú àwọn ará rẹ̀ tí à ń pè ní orúkọ yìí.”

62 Wọ́n sì ṣe àpẹẹrẹ sí baba rẹ̀, bí ó ti ń fẹ́ kí a pè é. 63 Ó sì béèrè fún wàláà, ó sì kọ ọ wí pé, “Johanu ni orúkọ rẹ̀.” Ẹnu sì ya gbogbo wọn. 64 Ẹnu rẹ̀ sì ṣí lọ́gán, okùn ahọ́n rẹ̀ sì tú, ó sì sọ̀rọ̀, ó sì ń yin Ọlọ́run. 65 Ẹ̀rù sì ba gbogbo àwọn tí ń bẹ ní agbègbè wọn: a sì ròyìn gbogbo nǹkan wọ̀nyí ká gbogbo ilẹ̀ òkè Judea. 66 Ó sì jẹ́ ohun ìyanu fún gbogbo àwọn tí ó gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n sì tò ó sínú ọkàn wọn, wọ́n ń wí pé, “Irú-ọmọ kín ni èyí yóò jẹ́?” Nítorí tí ọwọ́ Olúwa wà pẹ̀lú rẹ̀.

Orin Ṣakariah

67 Sekariah baba rẹ̀ sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, ó sì sọtẹ́lẹ̀, ó ní:

68 “Olùbùkún ni Olúwa Ọlọ́run Israẹli;
    nítorí tí ó ti bojú wò, tí ó sì ti dá àwọn ènìyàn rẹ̀ nídè,
69 Ó sì ti gbé ìwo ìgbàlà sókè fún wa
    ní ilé Dafidi ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀;
70 (bí ó ti sọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu àwọn wòlíì rẹ̀ mímọ́ tipẹ́tipẹ́),
71 Pé, a ó gbà wá là lọ́wọ́
    àwọn ọ̀tá wa àti lọ́wọ́ àwọn tí ó kórìíra wá.
72 Láti ṣe àánú tí ó ṣèlérí fún àwọn baba wa,
    àti láti rántí májẹ̀mú rẹ̀ mímọ́,
73 ìbúra tí ó ti bú fún Abrahamu baba wa,
74 láti gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa,
    kí àwa kí ó lè máa sìn láìfòyà,
75     ni ìwà mímọ́ àti ní òdodo níwájú rẹ̀, ní ọjọ́ ayé wa gbogbo.

76 (B)“Àti ìwọ, ọmọ mi, wòlíì Ọ̀gá-ògo jùlọ ni a ó máa pè ọ́:
    nítorí ìwọ ni yóò ṣáájú Olúwa láti tún ọ̀nà rẹ̀ ṣe;
77 (C)láti fi ìmọ̀ ìgbàlà fún àwọn ènìyàn rẹ̀
    fún ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ wọn,
78 (D)nítorí ìyọ́nú Ọlọ́run wà;
    nípa èyí tí ìlà-oòrùn láti òkè wá bojú wò wá,
79 (E)Láti fi ìmọ́lẹ̀ fún àwọn tí ó jókòó ní
    òkùnkùn àti ní òjìji ikú,
àti láti fi ẹsẹ̀ wa lé ọ̀nà àlàáfíà.”

80 (F)Ọmọ náà sì dàgbà, ó sì le ní ọkàn, ó sì ń gbé ní ijù títí ó fi di ọjọ́ ìfihàn rẹ̀ fún Israẹli.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.