Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Orin. Saamu ti Dafidi.
108 (A)Ọlọ́run, ọkàn mi dúró ṣinṣin
èmi ó máa kọrin, èmi ó máa fi ọkàn mi kọrin
2 Jí ohun èlò orin àti haapu
èmi ó jí ní kùtùkùtù
3 Èmi ó yìn ọ́, Ọlọ́run, nínú àwọn orílẹ̀-èdè
èmi ó kọrin rẹ nínú àwọn ènìyàn
4 Nítorí tí o tóbi ní àánú rẹ
ju àwọn ọ̀run lọ
àti òdodo rẹ dé àwọsánmọ̀
5 Gbé ara rẹ ga, Ọlọ́run, lórí àwọn ọ̀run,
àti ògo rẹ lórí gbogbo ayé.
6 (B)Kí a sì lè gba àwọn olùfẹ́ rẹ là;
fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ ṣe ìgbàlà,
kí o sì dá mi lóhùn
7 Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ láti ibi mímọ́ rẹ̀ pé:
“Èmi yóò yọ̀, èmi yóò pín Ṣekemu,
èmi yóò sì wọn Àfonífojì Sukkoti kúrò.
8 Gileadi ni tèmi, Manase ni tèmi,
Efraimu ni ìbòrí mi,
Juda ni olófin mi,
9 Moabu sì ni ìkòkò ìwẹsẹ̀ mi,
lórí Edomu ni èmi ó bọ́ bàtà mi sí,
lórí òkè Filistia ni èmi yóò hó ìhó ayọ̀.”
10 Ta ni yóò mú mi wá sí ìlú olódi?
Ta ni yóò sìn mí wá sí Edomu?
11 Ìwọ Ọlọ́run ha kọ́, ìwọ tí ó ti kọ̀ wá sílẹ̀.
Ọlọ́run ìwọ kì yóò bá àwọn jagunjagun wa jáde mọ́.
12 Fún wa ní ìrànlọ́wọ́ nínú ìpọ́njú,
nítorí ìrànlọ́wọ́ ènìyàn asán ni.
13 Nípasẹ̀ Ọlọ́run ni àwa ó ṣe akin
nítorí òun ó tẹ àwọn ọ̀tá wa mọ́lẹ̀.
3 Samuẹli sọ fún gbogbo ilé Israẹli pé, “Tí ẹ bá ń padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa pẹ̀lú gbogbo ọkàn yín, Ẹ yẹra kúrò lọ́dọ̀ ọlọ́run àjèjì àti Aṣtoreti kí ẹ sì fi ara yín jì fún Olúwa kí ẹ sì sin òun nìkan ṣoṣo, òun yóò sì gbà yín kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Filistini” 4 Nígbà náà ni àwọn ọmọ Israẹli yẹra fún Baali àti Aṣtoreti, wọ́n sì sin Olúwa nìkan ṣoṣo.
5 Nígbà náà ni, Samuẹli wí pé, “Ẹ kó gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jọ sí Mispa, èmi yóò bẹ̀bẹ̀ fún un yín lọ́dọ̀ Olúwa.” 6 Nígbà tí wọ́n sì ti péjọpọ̀ ní Mispa, wọ́n pọn omi, wọ́n sì dà á sílẹ̀ níwájú Olúwa. Ní ọjọ́ náà, wọ́n gbààwẹ̀, wọ́n sì jẹ́wọ́ pé, “Àwa ti ṣẹ̀ sí Olúwa.” Samuẹli sì jẹ́ olórí àwọn ọmọ Israẹli ní Mispa.
7 Nígbà tí àwọn Filistini gbọ́ pé àwọn Israẹli ti péjọ ní Mispa, àwọn aláṣẹ Filistini gòkè wá láti kọlù wọ́n. Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli gbọ́ èyí, Ẹ̀rù bà wọ́n nítorí àwọn Filistini. 8 Wọ́n sọ fún Samuẹli pé, “Má ṣe dákẹ́ kíké pe Olúwa Ọlọ́run wa fún wa, ké pè é kí ó lè gbà wá kúrò lọ́wọ́ àwọn Filistini.” 9 Nígbà náà ni Samuẹli mú ọ̀dọ́-àgùntàn tí ó jẹ́ ọmọ ọmú, ó sì fi rú ẹbọ sísun sí Olúwa. Ó sí ké pe Olúwa nítorí ilé Israẹli, Olúwa sì dá a lóhùn.
10 Nígbà tí Samuẹli ń ṣe ìrúbọ ẹbọ sísun, àwọn Filistini súnmọ́ tòsí láti bá Israẹli ja ogun. Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ náà, Olúwa sán àrá ńlá lu àwọn Filistini, ó sì mú jìnnìjìnnì bá wọn, a sì lé wọn níwájú àwọn ọmọ Israẹli. 11 Àwọn ọkùnrin Israẹli tú jáde láti Mispa. Wọ́n sì ń lépa àwọn Filistini, wọ́n sì pa wọ́n ní àpá rìn títí dé abẹ́ Beti-Kari.
12 Samuẹli mú òkúta kan ó sì fi lélẹ̀ láàrín Mispa àti Ṣeni, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Ebeneseri, wí pé, “Ibí ni Olúwa ràn wá lọ́wọ́ dé.” 13 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣẹ́gun Filistini, wọn kò sì wá sí agbègbè àwọn ọmọ Israẹli mọ́.
Ní gbogbo ìgbésí ayé Samuẹli, ọwọ́ Olúwa lòdì sí àwọn Filistini. 14 Àwọn ìlú láti Ekroni dé Gati tí àwọn Filistini ti gbà lọ́wọ́ Israẹli ni ó ti gbà padà fún Israẹli, ó sì gba gbogbo ilẹ̀ agbègbè rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìṣàkóso àwọn Filistini. Ìrẹ́pọ̀ sì wà láàrín Israẹli àti àwọn Amori.
15 Samuẹli tẹ̀síwájú gẹ́gẹ́ bí adájọ́ lórí Israẹli. Ní ọjọ́ ayé e rẹ̀.
Ìjọba ẹgbẹ̀rún ọdún
20 Mo sì rí angẹli kan ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, ti òun ti kọ́kọ́rọ́ ọ̀gbun, àti ẹ̀wọ̀n ńlá kan ní ọwọ́ rẹ̀. 2 O sì di Dragoni náà mú, ejò àtijọ́ nì, tí í ṣe èṣù, àti Satani, ó sì dè é ní ẹgbẹ̀rún ọdún. 3 Ó sì gbé e sọ sínú ọ̀gbun náà, ó sì tì í, ó sì fi èdìdì dì í lórí rẹ̀, kí ó má ba à tan àwọn orílẹ̀-èdè jẹ mọ́ títí ẹgbẹ̀rún ọdún náà yóò fi pé: Lẹ́yìn èyí, a kò le ṣàì tú u sílẹ̀ fún ìgbà díẹ̀.
4 (A)Mo sì rí àwọn ìtẹ́, wọ́n sì jókòó lórí wọn, a sì fi ìdájọ́ fún wọ́n: mo sì rí ọkàn àwọn tí a ti bẹ́ lórí nítorí ẹ̀rí Jesu, àti nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti àwọn tí kò sì foríbalẹ̀ fún ẹranko náà, àti fún àwòrán rẹ̀, tàbí tí kò sì gbà ààmì rẹ̀ ní iwájú wọn àti ní ọwọ́ wọn; wọ́n sì wà láààyè, wọ́n sì jẹ ọba pẹ̀lú Kristi ní ẹgbẹ̀rún ọdún. 5 Àwọn òkú ìyókù kò wà láààyè mọ́ títí ẹgbẹ̀rún ọdún náà yóò fi pé. Èyí ni àjíǹde èkínní. 6 Ẹni ìbùkún àti mímọ́ ni ẹni tí ó ní ipa nínú àjíǹde èkínní náà: lórí àwọn wọ̀nyí ikú ẹ̀ẹ̀kejì kò ní agbára, ṣùgbọ́n wọn ó jẹ́ àlùfáà Ọlọ́run àti ti Kristi, wọn ó sì máa jẹ ọba pẹ̀lú rẹ̀ ní ẹgbẹ̀rún ọdún.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.