Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 29

Saamu ti Dafidi.

29 Ẹ fi fún Olúwa, ẹ̀yin ẹ̀dá ọ̀run,
    Ẹ fi fún Olúwa, ògo àti alágbára.
Fi fún Olúwa, àní ògo orúkọ rẹ̀;
    sin Olúwa nínú ẹwà ìwà mímọ́.

Ohùn Olúwa n ré àwọn omi kọjá;
    Ọlọ́run ògo sán àrá,
    Olúwa san ara.
Ohùn Olúwa ní agbára;
    ohùn Olúwa kún fún ọláńlá.
Ohùn Olúwa fa igi kedari;
    Olúwa náà ló fọ́ igi kedari Lebanoni ya.
Ó mú Lebanoni fo bí i ọmọ màlúù,
    àti Sirioni bí ọmọ àgbáǹréré.
Ohùn Olúwa ń ya
    bí ọwọ́ iná mọ̀nà
Ohùn Olúwa ń mi aginjù.
    Olúwa mi aginjù Kadeṣi.
Ohùn Olúwa ní ó lọ igi óákù, ó n mú abo àgbọ̀nrín bí,
    ó sì bọ́ igi igbó sí ìhòhò.
Àti nínú tẹmpili rẹ̀ gbogbo ohùn wí pé “Ògo!”

10 Olúwa jókòó, Ó sì jẹ ọba lórí ìṣàn omi;
    Olúwa jókòó lórí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba títí láéláé.
11 Olúwa fi agbára fún àwọn ènìyàn rẹ̀;
    bùkún àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú àlàáfíà.

1 Samuẹli 3

Olúwa pe Samuẹli

Samuẹli ọmọkùnrin náà ṣe òjíṣẹ́ níwájú Olúwa ní abẹ́ Eli. Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì ọ̀rọ̀ Olúwa ṣọ̀wọ́n: kò sì sí ìran púpọ̀.

Ní alẹ́ ọjọ́ kan Eli ẹni tí ojú rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí di aláìlágbára, tí kò sì ríran dáradára, ó dùbúlẹ̀ ní ipò rẹ̀ bi ti àtẹ̀yìnwá. Nígbà tí iná kò tí ì kú Samuẹli dùbúlẹ̀ nínú tẹmpili Olúwa, níbi tí àpótí Olúwa gbé wà. Nígbà náà ni Olúwa pe Samuẹli.

Samuẹli sì dáhùn “Èmi nìyí” Ó sì sáré lọ sí ọ̀dọ̀ Eli ó sì wí pé, “Èmi nìyí nítorí pé ìwọ pè mí.”

Ṣùgbọ́n Eli wí fún un pé, “Èmi kò pè ọ́; padà lọ dùbúlẹ̀.” Nítorí náà ó lọ ó sì lọ dùbúlẹ̀.

Olúwa sì tún pè é, “Samuẹli!” Samuẹli tún dìde ó tọ Eli lọ, ó sì wí pé, “Èmi nìyìí, nítorí tí ìwọ pè mí.”

“Ọmọ mi, èmi kò pè ọ́, padà lọ dùbúlẹ̀.”

Ní àkókò yìí Samuẹli kò tí ì mọ̀ Olúwa: bẹ́ẹ̀ ni a kò sì tí ì fi ọ̀rọ̀ Olúwa hàn án.

Olúwa pe Samuẹli ní ìgbà kẹta, Samuẹli sì tún dìde, ó sì lọ sọ́dọ̀ Eli ó sì wí pé, “Èmi nìyìí; nítorí tí ìwọ pè mí.”

Nígbà náà ni Eli wá mọ̀ pé Olúwa ni ó ń pe ọmọ náà. Nítorí náà Eli sọ fún Samuẹli, “Lọ kí o lọ dùbúlẹ̀. Tí o bá sì pè ọ́, sọ wí pé, ‘máa wí, Olúwa nítorí tí ìránṣẹ́ rẹ ń gbọ́.’ ” Bẹ́ẹ̀ ni Samuẹli lọ, ó sì lọ dùbúlẹ̀ ní ààyè rẹ̀.

10 Olúwa wá, ó sì dúró níbẹ̀, ó pè é bí ó ṣe pè é ní ìgbà tí ó kọjá, “Samuẹli! Samuẹli!”

Nígbà náà ni Samuẹli dáhùn pé, “Máa wí nítorí tí ìránṣẹ́ rẹ ń gbọ́.”

11 Olúwa sọ fún Samuẹli pé, “Wò ó, èmi ṣetán láti ṣe ohun kan ní Israẹli tí yóò jẹ́ kí etí gbogbo ènìyàn tí ó gbọ́ ọ já gooro. 12 Ní ìgbà náà ni èmi yóò mú ohun gbogbo tí mo ti sọ sí ilé Eli ṣẹ láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin. 13 Nítorí èmi sọ fún un pé, Èmi yóò ṣe ìdájọ́ fún ilé rẹ̀ títí láé nítorí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ wọn tí òun mọ̀ nípa rẹ̀ nítorí àwọn ọmọ rẹ̀ sọ ọ̀rọ̀-òdì, òun kò sì dá wọn lẹ́kun. 14 Nítorí náà, mo búra sí ilé Eli, ‘Ìwà ẹ̀ṣẹ̀ ilé Eli ni a kì yóò fi ẹbọ tàbí ọrẹ mú kúrò láéláé.’ ”

15 Samuẹli dùbúlẹ̀ títí di òwúrọ̀ nígbà náà ó sì ṣí ìlẹ̀kùn ilé Olúwa, ó sì bẹ̀rù láti sọ ìran náà fún Eli. 16 Ṣùgbọ́n Eli pè é, ó sì wí pé, “Samuẹli, ọmọ mi.”

Samuẹli sì dáhùn pé, “Èmi nìyìí.”

17 Eli béèrè pé, “Kín ni ohun tí ó sọ fún ọ?” “Má ṣe fi pamọ́ fún mi. Kí Ọlọ́run mi ṣe bẹ́ẹ̀ sí ọ àti jù bẹ́ẹ̀ lọ pẹ̀lú, bí ìwọ bá fi ohunkóhun tí ó wí fún ọ pamọ́ fún mi.” 18 Samuẹli sọ gbogbo rẹ̀ fún un, kò sì fi ohun kankan pamọ́ fún un. Nígbà náà Eli wí pé, “Òun ni Olúwa; jẹ́ kí ó ṣe ohun tí ó dára ní ojú rẹ̀.”

19 Olúwa wà pẹ̀lú Samuẹli bí ó ṣe ń dàgbà, kò sì jẹ́ kí ọ̀kan nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ kùnà. 20 Gbogbo Israẹli láti Dani títí dé Beerṣeba mọ̀ pé a ti fa Samuẹli kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí wòlíì Olúwa. 21 Olúwa sì bẹ̀rẹ̀ sí ní fi ara hàn án ní Ṣilo, nítorí Olúwa ti fi ará hàn án fún Samuẹli ní Ṣilo nípa ọ̀rọ̀ Olúwa.

Ìṣe àwọn Aposteli 9:10-19

10 Ọmọ-ẹ̀yìn kan sì wà ní Damasku, tí a ń pè ni Anania! Olúwa sì wí fún un lójúran pé, “Anania!”

Ó sì wí pé, “Wò ó, èmi nìyí, Olúwa.”

11 Olúwa sì wí fún un pé, “Dìde kí ó sì lọ sí ilé Judasi ní Òpópónà Tààrà, kí ó sì béèrè ẹni tí a ń pè ni Saulu, ara Tarsu, sá wò ó, ó ń gbàdúrà. 12 Òun sì tí ri ọkùnrin kan lójúran ti a ń pè ni Anania, ó wọlé, ó sì fi ọwọ́ lé e, kí ó lè ríran.”

13 Anania sì dáhùn wí pé, “Olúwa mo tí gbúròó ọkùnrin yìí lọ́dọ̀ ọ̀pọ̀ ènìyàn, gbogbo búburú ti ó ṣe sí àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ ni Jerusalẹmu. 14 Ó sì gba àṣẹ láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí àlùfáà wá sí ìhín yìí, láti de gbogbo àwọn ti ń pe orúkọ rẹ.”

15 Ṣùgbọ́n Olúwa wí fún un pé, “Máa lọ; nítorí ohun èlò ààyò ni òun jẹ́ fún mi, láti gbé orúkọ mi lọ sí iwájú àwọn aláìkọlà, àti àwọn ọba, àti àwọn ọmọ Israẹli. 16 Nítorí èmi o fi gbogbo ìyà ti kò le ṣàìjẹ nítorí orúkọ mi hàn án.”

17 Anania sì lọ, ó sì wọ ilé náà, nígbà tí ó fi ọwọ́ rẹ̀ lé Saulu, ó sì wí pé, “Arákùnrin Saulu, Olúwa ni ó rán mi, Jesu tí ó fi ara hàn ọ lọ́nà tí ìwọ bá wá, kí ìwọ ba à lè ríran, kí ó sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́.” 18 Lójúkan náà nǹkan kan ti ó dàbí ìpẹ́ sì bọ kúrò lójú rẹ̀, ó sì ríran; ó sì dìde, a sì bamitiisi rẹ̀. 19 Nígbà tí ó sì jẹun, ara rẹ̀ mókun.

Saulu ní Damasku àti Jerusalẹmu

Saulu sì wá pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ní Damasku ní ọjọ́ púpọ̀

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.