Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 96

96 (A)Ẹ kọrin tuntun sí Olúwa:
    Ẹ kọrin sí Olúwa gbogbo ayé.
Ẹ kọrin sí Olúwa, yin orúkọ rẹ̀
    ẹ sọ ti ìgbàlà rẹ̀ ní ọjọ́ dé ọjọ́
Ẹ sọ ti ògo rẹ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè
    àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ láàrín gbogbo ènìyàn.

Nítorí títóbi ní Olúwa ẹni tí ìyìn tọ́ sí;
    òun ní o yẹ kí a bẹ̀rù ju gbogbo òrìṣà lọ
Nítorí asán ni gbogbo àwọn òrìṣà orílẹ̀-èdè
    ṣùgbọ́n Olúwa dá àwọn ọ̀run
Ọlá àti ọláńlá wà ní iwájú rẹ̀
    agbára àti ògo wà ní ibi mímọ́ rẹ̀.

Ẹ fi fún Olúwa, ẹ̀yin ìbátan ènìyàn
    Ẹ fi agbára àti ògo fún Olúwa
Ẹ fi ògo tí ó tọ́ sí Olúwa fún un;
    ẹ mú ọrẹ wá, kí ẹ sì wá sí àgbàlá rẹ̀
Ẹ máa sin Olúwa nínú ẹwà ìwà mímọ́ rẹ̀;
    ẹ wárìrì níwájú rẹ̀ gbogbo ayé.
10 Sọ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, “Olúwa jẹ ọba”
    a fi ìdí ayé múlẹ̀, tí kò sì lè yí;
    ẹni tí yóò fi òtítọ́ ṣe ìdájọ́ ènìyàn.

11 Jẹ́ kí àwọn ọ̀run kí ó yọ̀, kí ayé sì pariwo
    jẹ́ kí pápá Òkun kí ó hó pẹ̀lú ohun
gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀.
12     Jẹ́ kí oko kún fún ayọ̀
àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀:
nígbà náà ni gbogbo igi igbó yóò máa yọ̀
13     Wọn yóò kọrin níwájú Olúwa,
    nítorí tí ó ń bọ̀ wá,
Ó ń bọ̀ wá ṣe ìdájọ́ ayé
yóò fi òdodo ṣe ìdájọ́ ayé
    àti ti àwọn ènìyàn ni yóò fi òtítọ́ rẹ̀ ṣe.

Sefaniah 3:8-13

Nítorí náà ẹ dúró dè mí,” ni Olúwa wí,
    “títí di ọjọ́ náà tí èmi yóò fi jẹ́rìí sí yin;
nítorí ìpinnu mi ni láti kó orílẹ̀-èdè jọ
    kí èmi kí ó lè kó ilẹ̀ ọba jọ
àti láti da ìbínú mi jáde sórí wọn,
    àní gbogbo ìbínú gbígbóná mi.
Nítorí, gbogbo ayé
    ni a ó fi iná owú mi jẹ run.

“Nígbà náà ni èmi yóò yí èdè àwọn ènìyàn padà sí èdè mímọ́,
    nítorí kí gbogbo wọn bá a lè máa pe orúkọ Olúwa,
    láti fi ọkàn kan sìn ín.
10 Láti òkè odò Etiopia,
    àwọn olùjọsìn mi, àwọn ènìyàn mi tí ó ti fọ́nká,
    yóò mú ọrẹ wá fún mi.
11 Ní ọjọ́ náà ni a kì yóò sì dójútì
    nítorí gbogbo iṣẹ́ ibi ni tí ó ti ṣẹ̀ sí mi,
nígbà náà ni èmi yóò mu
    kúrò nínú ìlú yìí, àwọn tí ń yọ̀ nínú ìgbéraga wọn.
Ìwọ kì yóò sì gbéraga mọ́
    ní òkè mímọ́ mi.
12 Ṣùgbọ́n Èmi yóò fi àwọn ọlọ́kàn tútù
    àti onírẹ̀lẹ̀ sílẹ̀ pẹ̀lú ni àárín rẹ̀,
    wọn yóò sì gbẹ́kẹ̀lé orúkọ Olúwa.
13 Àwọn ìyókù Israẹli kì yóò hùwà
    ibi, wọn kì yóò sọ̀rọ̀ èké,
    bẹ́ẹ̀ ni a kì yóò rí ahọ́n àrékérekè ní
ẹnu wọn. Àwọn yóò jẹun, wọn yóò sì dùbúlẹ̀,
    bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kì yóò dẹ́rùbà wọ́n.”

Romu 10:5-13

(A)Mose ṣá kọ èyí nípa òdodo tí í ṣe ti òfin pé, “Ẹni tí ó ba ṣe, yóò yè nípa wọn.” (B)Ṣùgbọ́n òdodo tí í ṣe ìgbàgbọ́ wí pé, “Má ṣe wí ni ọkàn rẹ̀ pé, ta ni yóò gòkè lọ si ọ̀run?” (èyí i ni ni, láti mú Kristi sọ̀kalẹ̀) “tàbí, ta ni yóò sọ̀kalẹ̀ lọ si ọ̀gbun?” (èyí i ni ni, láti mú Kristi gòkè ti inú òkú wá). (C)Ṣùgbọ́n kí ni ó wí? “Ọ̀rọ̀ náà wà létí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ní ẹnu rẹ̀, àti ní ọkàn rẹ̀,” èyí nì ni ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́, tí àwa ń wàásù; (D)Pé, bí ìwọ bá fi ẹnu rẹ̀ jẹ́wọ́ “Jesu ní Olúwa,” tí ìwọ si gbàgbọ́ ní ọkàn rẹ pé, Ọlọ́run jí i dìde kúrò nínú òku, a ó gbà ọ́ là. 10 Nítorí ọkàn ni a fi ìgbàgbọ́ sí òdodo; ẹnu ni a sì ń fi ìjẹ́wọ́ sí ìgbàlà. 11 (E)Nítorí ìwé Mímọ́ wí pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà a gbọ́ ojú kò yóò tì í.” 12 (F)Nítorí kò si ìyàtọ̀ nínú Júù àti Helleni: nítorí Olúwa kan náà ni Olúwa gbogbo wọn, o si pọ̀ ni ọrọ̀ fún gbogbo àwọn ti ń ké pe e. 13 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá sá à ti pe orúkọ Olúwa ni a ó gbàlà.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.