Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 126

Orin fún ìgòkè.

126 Nígbà tí Olúwa mú ìkólọ Sioni padà,
    àwa dàbí ẹni tí ó ń lá àlá.
Nígbà náà ni ẹnu wa kún fún ẹ̀rín,
    àti ahọ́n wa kọ orin;
nígbà náà ni wọ́n wí nínú àwọn kèfèrí pé,
    Olúwa ṣe ohun ńlá fún wọn.
Olúwa ṣe ohun ńlá fún wa;
    nítorí náà àwa ń yọ̀.

Olúwa mú ìkólọ wa padà,
    bí ìṣàn omi ní gúúsù.
Àwọn tí ń fi omijé fún irúgbìn
    yóò fi ayọ̀ ka.
Ẹni tí ń fi ẹkún rìn lọ,
    tí ó sì gbé irúgbìn lọ́wọ́,
lóòtítọ́, yóò fi ayọ̀ padà wá,
    yóò sì ru ìtí rẹ̀.

Habakuku 3:13-19

13 Ìwọ jáde lọ láti tú àwọn ènìyàn rẹ sílẹ̀,
    àti láti gba ẹni ààmì òróró rẹ là;
Ìwọ ti run àwọn olórí kúrò nínú ilẹ̀ àwọn ènìyàn búburú,
    ó sì bọ ìhámọ́ra rẹ láti orí de ẹsẹ̀
14 Pẹ̀lú ọ̀kọ̀ rẹ̀ kí ó fi gún orí rẹ
    nígbà tí àwọn jagunjagun rẹ̀
jáde láti tú wá ká:
    ayọ̀ wọn sì ni láti jẹ tálákà run ní ìkọ̀kọ̀.
15 Ìwọ fi ẹṣin rẹ rìn Òkun já,
    ó sì da àwọn omi ńlá ru.

16 Mo gbọ́, ọkàn mi sì wárìrì,
    ètè mi sì gbọ̀n sí ìró náà;
ìbàjẹ́ sì wọ inú egungun mi lọ,
    ẹsẹ̀ mi sì wárìrì,
mo dúró ni ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ fún ọjọ́ ìdààmú
    láti de sórí àwọn ènìyàn tó ń dojúkọ wá.
17 Bí igi ọ̀pọ̀tọ́ ko tilẹ̀ tanná,
    tí èso kò sí nínú àjàrà;
tí igi olifi ko le so,
    àwọn oko ko sì mú oúnjẹ wá;
tí a sì ké agbo ẹran kúrò nínú agbo,
    tí kò sì sí ọwọ́ ẹran ni ibùso mọ́,
18 síbẹ̀, èmi ó láyọ̀ nínú Olúwa,
    èmi yóò sí máa yọ nínú Ọlọ́run ìgbàlà mi.

19 Olúwa Olódùmarè ni agbára mi,
    òun yóò sí ṣe ẹsẹ̀ mi bí ẹsẹ̀ abo àgbọ̀nrín,
    yóò sí mú mi rìn lórí ibi gíga.

Sí olórí akọrin lórí ohun èlò orin olókùn mi.

Matiu 21:28-32

Òwe àwọn ọmọ méjì

28 (A)“Kí ni ẹ rò nípa eléyìí? Ọkùnrin kan ti ó ní àwọn ọmọkùnrin méjì. Ó sọ fún èyí ẹ̀gbọ́n pé, ‘Ọmọ, lọ ṣiṣẹ́ nínú ọgbà àjàrà lónìí.’

29 “Ó sì dá baba rẹ̀ lóhùn pé, ‘Èmi kò ní í lọ,’ ṣùgbọ́n níkẹyìn ó yí ọkàn padà, ó sì lọ.

30 “Nígbà náà ni baba yìí tún sọ fún èyí àbúrò pé, ‘Lọ ṣiṣẹ́ ní oko.’ Ọmọ náà sì sọ pé, ‘Èmi yóò lọ, baba,’ ṣùgbọ́n kò lọ rárá.

31 “Nínú àwọn méjèèjì yìí, èwo ni ó ṣe ìfẹ́ baba wọn?”

Gbogbo wọn sì fohùn ṣọ̀kan pé, “Èyí ẹ̀gbọ́n ni.”

Jesu wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, àwọn agbowó òde àti àwọn panṣágà yóò wọ ìjọba ọ̀run síwájú yín. 32 Nítorí Johanu tọ́ yin wá láti fi ọ̀nà òdodo hàn yín, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbà á gbọ́, ṣùgbọ́n àwọn agbowó òde àti àwọn panṣágà ronúpìwàdà, bí ó tilẹ̀ ṣe pé ẹ rí àwọn ohun tí ń ṣẹlẹ̀ wọ̀nyí, ẹ kọ̀ láti ronúpìwàdà, ẹ kò gbà á gbọ́.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.