Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 78

Maskili ti Asafu.

78 Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ gbọ́ ẹ̀kọ́ mi;
    tẹ́tí rẹ sí ọ̀rọ̀ ẹnu mi.
(A)Èmi ó la ẹnu mi ní òwe,
    èmi o sọ ohun ìkọ̀kọ̀, ohun ti ọjọ́ pípẹ́;
Ohun tí a ti gbọ́ tí a sì ti mọ̀,
    ohun tí àwọn baba wa ti sọ fún wa.
Àwa kì yóò pa wọ́n mọ́
    kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọmọ,
ní fífi ìyìn Olúwa, àti ipa rẹ̀
    àti iṣẹ́ ìyanu tó ti ṣe hàn
fún ìran tí ń bọ̀.
Ó gbé ẹ̀rí kalẹ̀ ní Jakọbu
    o sì fìdí àṣẹ múlẹ̀ ní Israẹli,
èyí tí ó pàṣẹ fún àwọn baba ńlá wa
    láti kọ́ àwọn ọmọ wọn,
Nítorí náà, àwọn ìran tí ń bọ̀ yóò mọ̀ wọ́n
    bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ tí a kò tí ì bí
    tí yóò dìde tí wọn yóò sọ fún àwọn ọmọ wọn
Nígbà náà ni wọ́n ò fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọn sínú Ọlọ́run
    wọn kò sì ní gbàgbé iṣẹ́ Ọlọ́run
    ṣùgbọ́n wọn ó pa àṣẹ rẹ̀ mọ́.
Kí wọn kí ó má ṣe dàbí àwọn baba ńlá wọn,
    ìran alágídí àti ọlọ́tẹ̀,
    ìran tí ọkàn wọn kò ṣọ òtítọ́ si olóore,
    àti ẹ̀mí ẹni tí kò bá Ọlọ́run dúró ṣinṣin.

Àwọn ọkùnrin Efraimu, tí ó há mọ́ ọ tí wọ́n mú ọrun,
    wọ́n yípadà ní ọjọ́ ogun
10 Wọn kò pa májẹ̀mú Ọlọ́run mọ́
    wọn sì kọ̀ láti máa gbé nínú òfin rẹ̀
11 Wọ́n gbàgbé ohun tí ó ti ṣe,
    àwọn ìyanu tí ó ti fihàn wọ́n.
12 Ó ṣe ìyanu níwájú àwọn baba wọn ní ilẹ̀ Ejibiti, ní agbègbè Ṣoani.
13 Ó pín Òkun ní yà, ó sì mú wọn kọjá
    Ó mù kí omi naà dúró bi odi gíga.
14 Ní ọ̀sán, ó fi ìkùùkuu àwọsánmọ̀ ṣe amọ̀nà wọn
    àti ní gbogbo òru pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ iná.
15 Ó sán àpáta ní aginjù
    ó sì fún wọn ní omi mímu lọ́pọ̀lọpọ̀
    bí ẹni pé láti inú ibú wá.
16 Ó mú ìṣàn omi jáde láti inú àpáta
    omi ṣíṣàn sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí odò.

17 Wọ́n sì tún tẹ̀síwájú láti dẹ́ṣẹ̀ sí i
    ní ìṣọ̀tẹ̀ sí Ọ̀gá-ògo ní aginjù.
18 Wọ́n mọ̀ ọ́n mọ̀ dán Ọlọ́run wò
    nípa bíbéèrè fún oúnjẹ tí wọn bẹ̀bẹ̀ fún
19 Wọ́n sọ̀rọ̀-òdì sí Ọlọ́run, wí pé
    “Ọlọ́run ha lè tẹ́ tábìlì ní aginjù?
20 Nígbà tí ó lu àpáta, omi tú jáde,
    odò sì sàn lọ́pọ̀lọpọ̀
ṣùgbọ́n òun ha lè fún wa lóúnjẹ
    ó ha le pèsè ẹran fún àwọn ènìyàn rẹ̀”
21 Nígbà tí Olúwa gbọ́ wọn, ó bínú gidigidi;
iná rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ sí Jakọbu,
ìbínú rẹ̀ sì rú sí Israẹli,
22 Nítorí wọn kò gba Ọlọ́run gbọ́,
    wọn kò sì gbẹ́kẹ̀lé ìgbàlà rẹ̀.
23 Síbẹ̀ ó pàṣẹ fún ìràwọ̀ ojú ọ̀run,
    ó sì ṣí ìlẹ̀kùn ọ̀run sílẹ̀;
24 (B)Ó rọ manna fún àwọn ènìyàn láti jẹ,
    ó fún wọn ní ọkà láti ọ̀run.
25 Àwọn ènìyàn jẹ oúnjẹ àwọn angẹli;
    Ó fún wọn ní oúnjẹ ní àjẹyó,
26 Ó mú afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn láti ọ̀run wá
    ó mú afẹ́fẹ́ gúúsù wá nípa agbára rẹ̀.
27 Ó rọ òjò ẹran sílẹ̀ sórí wọn bí erùpẹ̀ ilẹ̀,
    àti ẹyẹ abìyẹ́ gẹ́gẹ́ bí iyanrìn etí Òkun
28 Ó jẹ́ kí wọn jáde ní ibùdó wọn,
    yíká àgọ́ wọn.
29 Wọ́n jẹ, wọ́n sì yó jọjọ
    nítorí ó ti fún wọn ní ohun tí wọn fìtara bẹ̀bẹ̀ fún
30 Ṣùgbọ́n wọn kò kúrò nínú oúnjẹ tí wọn fìtara bẹ̀bẹ̀ fún,
    nígbà tí oúnjẹ wọn sì wà ní ẹnu wọn,
31 Ìbínú Ọlọ́run dìde sí wọn
    ó pa àwọn tí ó jùlọ nínú wọn,
    ó sì lu àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin Israẹli bolẹ̀.

32 Nínú gbogbo ìwọ̀nyí, wọ́n ń dẹ́ṣẹ̀ síwájú;
    nínú gbogbo iṣẹ́ ìyanu rẹ̀, wọ́n kò gbàgbọ́
33 O fi òpin sí ayé wọn nínú asán
    àti ọdún wọn nínú ìpayà.
34 Nígbàkígbà tí Ọlọ́run bá pa wọ́n,
    wọn yóò wá a kiri;
    wọn yóò fi ìtara yípadà sí i.
35 Wọ́n rántí pé Ọlọ́run ní àpáta wọn;
    wí pé Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo jùlọ ni olùràpadà àpáta wọn
36 Ṣùgbọ́n nígbà náà ni wọ́n yóò pọ́n ọn pẹ̀lú ẹnu wọ́n
    wọ́n fi ahọ́n wọ́n purọ́ fún un;
37 (C)Ọkàn wọn kò sòtítọ́ sí i,
    wọn kò jẹ́ olódodo sí májẹ̀mú rẹ̀.
38 Síbẹ̀ ó ṣàánú;
    ó dárí àìṣedéédéé wọn jì
òun kò sì pa wọ́n run
    nígbà púpọ̀ ló ń yí ìbínú rẹ̀ padà
kò sì ru ìbínú rẹ̀ sókè
39 Ó rántí pé ẹlẹ́ran ara ni wọ́n,
    afẹ́fẹ́ tó ń kọjá tí kò lè padà.

40 Nígbà gbogbo ní wọn ń ṣọ̀tẹ̀ sí i ní aginjù
    wọn mú un bínú nínú ilẹ̀ tí ó di ahoro!
41 Síwájú àti síwájú wọ́n dán Ọlọ́run wò;
    wọ́n mú ẹni mímọ́ Israẹli bínú.
42 Wọ́n kò rántí agbára rẹ̀:
    ní ọjọ́ tí ó rà wọ́n padà lọ́wọ́ àwọn aninilára,
43 Ní ọjọ́ tí ó fi iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ hàn ní Ejibiti,
    àti iṣẹ́ ààmì rẹ̀ ni ẹkùn Ṣoani
44 Ó sọ omi wọn di ẹ̀jẹ̀;
    wọn kò lè mu láti odò wọn.
45 Ó rán ọ̀wọ́ eṣinṣin láti pa wọ́n run,
    àti ọ̀pọ̀lọ́ tí ó bá wọn jẹun.
46 Ó fi ọkà wọn fún láńtata,
    àwọn ìre oko wọn fún eṣú.
47 Ó fi yìnyín ba àjàrà wọn jẹ́
    ó bá èso sikamore wọn jẹ́.
48 Ó fi ohun ọ̀sìn wọn fún yìnyín,
    agbo ẹran wọn fún mọ̀nàmọ́ná.
49 Ó mú kíkorò ìbínú rẹ̀ wá sí wọn lára,
    ìrunú àti ìkáàánú, àti ìpọ́njú,
    nípa rírán angẹli apanirun sí wọn.
50 Ó pèsè ipa fún ìbínú rẹ̀,
    òun kò gbà wọ́n lọ́wọ́ ikú,
    ṣùgbọ́n ó fi ẹ̀mí wọ́n fún àjàkálẹ̀-ààrùn.
51 Ó kọlu àwọn àkọ́bí ọmọ ọkùnrin Ejibiti
    Olórí agbára wọn nínú àgọ́ Hamu
52 Ṣùgbọ́n ó mú àwọn ènìyàn rẹ̀ jáde bí ọ̀wọ́ ẹran;
    ó ṣọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí àgùntàn nínú aginjù.
53 Ó dáàbò bò wọ́n dáradára, nítorí náà ni ẹ̀rù kò ṣe bà wọ́n
    ṣùgbọ́n Òkun padé mọ́ àwọn ọ̀tá wọn.
54 Bákan náà ni ó mú wọn wá sí etí ilẹ̀ mímọ́ rẹ̀
    òkè tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ti gbà
55 Ó lé kèfèrí jáde níwájú wọn
    ó sì fi títa okùn pín ilẹ̀ náà fún wọn gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìní;
    ó mú àwọn ẹ̀yà Israẹli jókòó ní ilẹ̀ wọn.

56 Ṣùgbọ́n wọn dán Ọlọ́run wò
    wọn sì ṣọ̀tẹ̀ sí Ọ̀gá-ògo;
    wọn kò pa àṣẹ rẹ̀ mọ́.
57 Ṣùgbọ́n wọ́n yípadà,
    wọn jẹ́ aláìṣòdodo gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wọn
wọ́n sì pẹ̀yìndà sí apákan bí ọrun ẹ̀tàn.
58 Wọ́n bí i nínú pẹ̀lú ibi gíga wọn;
    wọn rú owú rẹ̀ sókè nípa òrìṣà wọn
59 Nígbà tí Ọlọ́run gbọ́ wọn,
    inú bí i gidigidi;
ó kọ Israẹli pátápátá.
60 Ó kọ àgọ́ Ṣilo sílẹ̀,
    àgọ́ tí ó ti gbé kalẹ̀ láàrín àwọn ènìyàn.
61 Ó rán àpótí ẹ̀rí, agbára rẹ̀ lọ sí ìgbèkùn,
    dídán ògo rẹ̀ lọ sí ọwọ́ àwọn ọ̀tá.
62 Ó fi àwọn ènìyàn rẹ̀ lé idà lọ́wọ́,
    ó sì bínú sí àwọn ohun ìní rẹ̀.
63 Iná run àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wọn,
    àwọn ọmọbìnrin wọn kò sì ní orin ìgbéyàwó:
64 A fi àlùfáà wọn fún idà,
    àwọn opó wọn kò sì le è sọkún.

65 Olúwa sì jí gẹ́gẹ́ bí ẹni ojú oorun,
    gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin ti i jí kúrò nínú ìraníyè ọtí.
66 Ó kọlu àwọn ọ̀tá rẹ̀ padà;
    ó fi wọn sínú ìtìjú ayérayé.
67 Nígbà náà ni ó kọ́ àgọ́ Josẹfu,
    kò sì yan ẹ̀yà Efraimu;
68 Ṣùgbọ́n ó yan ẹ̀yà Juda,
    òkè Sioni, èyí tí ó fẹ́ràn.
69 Ó kọ́ ibi mímọ́ rẹ̀, ibi gíga,
    gẹ́gẹ́ bí ayé tí ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ títí láé.
70 Ó yan Dafidi ìránṣẹ́ rẹ̀
    ó mú láti inú àwọn agbo ẹran;
71 Ó mú un jáde nínú ìtọ́jú àgùntàn
    láti jẹ́ olùṣọ́-àgùntàn àwọn ènìyàn rẹ̀ Jakọbu
    àti Israẹli ogún un rẹ̀.
72 Dafidi sì ṣọ́ wọn pẹ̀lú òtítọ́ inú ọkàn;
    pẹ̀lú ọwọ́ òye ni ó fi darí wọn.

Joṣua 24:25-33

25 Ní ọjọ́ náà Joṣua dá májẹ̀mú fún àwọn ènìyàn, ó sì fi òfin àti ìlànà fún wọn ní Ṣekemu. 26 Joṣua sì kọ gbogbo ìdáhùn àwọn ènìyàn wọ̀nyí sí inú Ìwé Òfin Ọlọ́run. Lẹ́yìn náà ó gbé òkúta ńlá kan, ó gbé e kalẹ̀ ní abẹ́ igi óákù ní ẹ̀bá ibi mímọ́ Olúwa.

27 “E wò ó!” ó wí fún gbogbo ènìyàn pé, “Òkúta yìí ni yóò jẹ́ ẹlẹ́rìí fún wa, nítorí ó ti gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tí Olúwa ti sọ fún wa. Yóò jẹ́ ẹlẹ́rìí yín tí ẹ bá ṣe àìṣòótọ́ sí Ọlọ́run yín.”

28 Lẹ́yìn náà ni Joṣua jẹ́ kí àwọn ènìyàn lọ, olúkúlùkù sí ilẹ̀ ìní rẹ̀.

Ikú Joṣua àti Eleasari

29 Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Joṣua ọmọ Nuni ìránṣẹ́ Olúwa, kú ní ẹni àádọ́fà ọdún (110) 30 Wọ́n sì sin ín sí ilẹ̀ ìní rẹ̀, ní Timnati Serah ni ilẹ̀ orí òkè Efraimu, ní ìhà àríwá Òkè Gaaṣi.

31 Israẹli sì sin Olúwa ní gbogbo ọjọ́ ayé Joṣua àti ní gbogbo ọjọ́ àwọn àgbàgbà tí ó wà lẹ́yìn ikú rẹ̀ tí wọ́n sì rí gbogbo iṣẹ́ ńlá tí Olúwa ṣe fún Israẹli.

32 (A)Egungun Josẹfu, èyí tí àwọn ọmọ Israẹli kó kúrò ní Ejibiti, ni wọ́n sin ní Ṣekemu ní ìpín ilẹ̀ tí Jakọbu rà fún ọgọ́ọ̀rún (100) fàdákà ní ọwọ́ Hamori, baba Ṣekemu. Èyí sì jẹ́ ilẹ̀ ìní àwọn ọmọ Josẹfu.

33 Eleasari ọmọ Aaroni sì kú, wọ́n sì sin ín ní Gibeah, tí a ti pín fún ọmọ rẹ̀ Finehasi ní òkè ilẹ̀ Efraimu.

1 Kọrinti 14:20-25

20 (A)Ará, ẹ má ṣe jẹ ọmọdé ni òye, ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ ọmọdé ní àrankàn, ṣùgbọ́n ni òye ẹ jẹ́ àgbà. 21 (B)A tí kọ ọ́ nínú òfin pé,

“Nípa àwọn aláhọ́n mìíràn
    àti elétè àjèjì
ní èmi ó fi ba àwọn ènìyàn yìí sọ̀rọ̀;
    síbẹ̀ wọn kì yóò gbọ́ tèmi,”
ni Olúwa wí.

22 Nítorí náà àwọn ahọ́n jásí ààmì kan, kì í ṣe fún àwọn tí ó gbàgbọ́, bí kò ṣe fún àwọn aláìgbàgbọ́: ṣùgbọ́n ìsọtẹ́lẹ̀ kì í ṣe fún àwọn tí kò gbàgbọ́ bí kò ṣe fún àwọn tí ó gbàgbọ́. 23 Ǹjẹ́ bí gbogbo ìjọ bá péjọ sí ibi kan, tí gbogbo wọn sí ń fi èdè fọ̀, bí àwọn tí ó jẹ́ aláìlẹ́kọ̀ọ́ àti aláìgbàgbọ́ bá wọlé wá, wọn kí yóò ha wí pé ẹ̀yin ń ṣe òmùgọ̀? 24 Ṣùgbọ́n bí gbogbo yín bá ń sọtẹ́lẹ̀, ti ẹnìkan tí kò gbàgbọ́ tàbí tí ko ni ẹ̀kọ́ bá wọlé wá, gbogbo yin ní yóò fi òye ẹ̀ṣẹ̀ yé e, gbogbo yin ní yóò wádìí rẹ̀. 25 Bẹ́ẹ̀ ní a ó sì fi àṣírí ọkàn rẹ̀ hàn; bẹ́ẹ̀ ni òun ó sì dojúbolẹ̀, yóò sí sin Ọlọ́run yóò sì sọ pé, “Nítòótọ́ Ọlọ́run ń bẹ láàrín yín!”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.