Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 105:1-6

105 (A)Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, ké pe orúkọ rẹ̀:
    Jẹ́ kí a mọ ohun tí ó ṣe láàrín àwọn orílẹ̀-èdè;
Kọrin sí i, kọrin ìyìn sí i;
    sọ ti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ gbogbo.
Ṣògo nínú orúkọ mímọ́ rẹ̀:
    Jẹ́ kí ọkàn àwọn tí ń wá Olúwa kí ó yọ̀.
Olúwa àti ipá rẹ̀;
    wa ojú rẹ̀ nígbà gbogbo.

Rántí àwọn ìyanu tí ó ti ṣe,
    ìyanu rẹ̀, àti ìdájọ́ tí ó sọ,
Ẹ̀yin ìran Abrahamu ìránṣẹ́ rẹ̀,
    ẹ̀yin ọmọkùnrin Jakọbu, àyànfẹ́ rẹ̀.

Saamu 105:37-45

37 Ó mú Israẹli jáde
    ti òun ti fàdákà àti wúrà,
    nínú ẹ̀yà rẹ̀ kò sí aláìlera kan.
38 Inú Ejibiti dùn nígbà tí wọn ń lọ,
    nítorí ẹ̀rù àwọn Israẹli ń bá wọ́n.

39 Ó ta àwọsánmọ̀ fún ìbòrí,
    àti iná láti fún wọn ní ìmọ́lẹ̀ lálẹ́
40 Wọn béèrè, ó sì mú ẹyẹ àparò wá,
    ó sì fi oúnjẹ ọ̀run tẹ́ wọn lọ́rùn.
41 Ó sì la àpáta, ó sì mú omi jáde;
    gẹ́gẹ́ bí odò tí ń sàn níbi gbígbẹ.

42 Nítorí ó rántí ìlérí mímọ́ rẹ̀
    àti Abrahamu ìránṣẹ́ rẹ̀.
43 Ó sì fi ayọ̀ mú àwọn ènìyàn rẹ̀ jáde
    pẹ̀lú ayọ̀ ní ó yan àyànfẹ́ rẹ̀
44 Ó fún wọn ní ilẹ̀ ìní náà,
    wọ́n sì jogún iṣẹ́ àwọn ènìyàn náà,
45 Kí wọn kí ó lè máa pa àṣẹ rẹ̀ mọ́
    kí wọn kí ó lè kíyèsi òfin rẹ̀.

Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Eksodu 16:22-30

22 Ní ọjọ́ kẹfà, wọ́n kó ìlọ́po méjì èyí tiwọn ń kó tẹ́lẹ̀: òṣùwọ̀n omeri méjì fún ẹnìkọ̀ọ̀kan; àwọn olórí ìjọ ènìyàn sì wá, wọ́n sì sọ èyí fún Mose. 23 (A)Ó sì wí fún wọn pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa pàṣẹ: ‘Ọ̀la jẹ́ ọjọ́ ìsinmi, ìsinmi mímọ́ fún Olúwa. Ẹ yan èyí ti ẹ̀yin ní yan, kí ẹ sì bọ èyí ti ẹ̀yin ní bọ̀. Ẹ tọ́jú èyí ti ó kù sílẹ̀, kí ẹ pa á mọ́ di òwúrọ̀.’ ”

24 Wọ́n sì tọ́jú rẹ̀ di òwúrọ̀ bí Mose ti pàṣẹ; kò sì rùn bẹ́ẹ̀ ni kò sì ní ìdin. 25 Mose sì wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ ẹ́ ní òní nítorí òní jẹ́ ọjọ́ ìsinmi Olúwa. Ẹ̀yin kò ni rí i ni orí ilẹ̀ ní ọjọ́ òní. 26 Ní ọjọ́ mẹ́fà ni kí ẹ fi kó o, ṣùgbọ́n ni ọjọ́ keje ọjọ́ ìsinmi, kò ní sí i fún un yín ni ọjọ́ náà.”

27 Síbẹ̀síbẹ̀ àwọn ènìyàn kan jáde lọ ní ọjọ́ keje láti kó o, ṣùgbọ́n wọn kò ri nǹkan kan kó. 28 Olúwa sì sọ fún Mose pé, “Yóò ti pẹ́ tó ti ẹ ó kọ̀ láti pa àṣẹ mi àti ìlànà mi mọ́? 29 Wò ó? Olúwa ti fún un yín ni ọjọ́ ìsinmi, nítorí náà, ni ọjọ́ kẹfà, ó fún un yín ni oúnjẹ ọjọ́ méjì; kí ẹnìkọ̀ọ̀kan dúró ni ibi tí ó gbé wà; kí ẹ má ṣe kúrò ni ibi tí ẹ wà ni ọjọ́ keje.” 30 Nítorí náà, àwọn ènìyàn sinmi ní ọjọ́ keje.

Matiu 19:23-30

23 (A)Nígbà náà, ní Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé, ó ṣòro fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọ̀run.” 24 Mo tún wí fún yín pé, “Ó rọrùn fún ìbákasẹ láti wọ ojú abẹ́rẹ́ jù fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọ́run.”

25 Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn gbọ́ èyí, ẹnu sì yà wọn gidigidi, wọ́n béèrè pé, “Ǹjẹ́ ta ni ó ha le là?”

26 (B)Ṣùgbọ́n Jesu wò wọ́n, ó sì wí fún wọn pé, “Ènìyàn ni èyí ṣòro fún; ṣùgbọ́n fún Ọlọ́run ohun gbogbo ni ṣíṣe.”

27 (C)Peteru sì wí fún un pé, “Àwa ti fi ohun gbogbo sílẹ̀, a sì tẹ̀lé ọ, kí ni yóò jẹ́ èrè wa?”

28 (D)Jesu dáhùn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé, ‘Nígbà ìsọdọ̀tun ohun gbogbo, nígbà tí Ọmọ Ènìyàn yóò jókòó lórí ìtẹ́ tí ó lógo, dájúdájú, ẹ̀yin ọmọ-ẹ̀yìn mi yóò sì jókòó lórí ìtẹ́ méjìlá láti ṣe ìdájọ́ ẹ̀yà Israẹli méjìlá. 29 Àti pé ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ilé tàbí arákùnrin tàbí arábìnrin tàbí baba tàbí ìyá tàbí àwọn ọmọ, tàbí ohun ìní rẹ̀ sílẹ̀ nítorí orúkọ mí, yóò gba ọgọọgọ́rùn-ún èrè rẹ̀ láyé, wọn ó sì tún jogún ìyè àìnípẹ̀kun. 30 Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ àwọn tí ó síwájú nísinsin yìí ni yóò kẹ́yìn, àwọn tí ó kẹ́yìn ni yóò sì síwájú.’

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.