Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Fún adarí orin. Fún Jedutuni. Ti Asafu. Saamu.
77 Mó kígbe sí Ọlọ́run fún ìrànlọ́wọ́;
mo kígbe sí Ọlọ́run láti gbọ́ tèmi.
2 Nígbà tí mo wà nínú ìpọ́njú,
mo wá Olúwa;
ní òru ni mo na ọwọ́ mi jáde ní àìkáárẹ̀
ọkàn mí sì kọ̀ láti tù ú nínú.
3 Èmi rántí rẹ, Ọlọ́run,
mo sì kẹ́dùn;
mo ṣe àròyé, ẹ̀mí mi sì rẹ̀wẹ̀sì. Sela.
4 Ìwọ kò fẹ́ kí èmi fi ojú ba oorun,
mo dààmú tó bẹ́ẹ̀ tí ń kò le sọ̀rọ̀.
5 Mo ronú nípa ọjọ́ ìgbàanì;
ọdún pípẹ́ sẹ́yìn;
6 Mo rántí orin mi ní òru.
Èmi ń bá àyà mi sọ̀rọ̀,
ọkàn mi sì ń ṣe àwárí jọjọ.
7 “Olúwa yóò ha kọ̀ títí láé?
Ki yóò ha ṣe ojúrere rẹ̀ mọ́?
8 Ṣe ìfẹ́ rẹ̀ àti àánú rẹ̀ ti kú lọ láéláé?
Ìlérí rẹ̀ ha kùnà títí ayé?
9 Ọlọ́run ha gbàgbé láti máa ṣàánú?
Ní ìbínú rẹ̀, ó ha sé ojúrere rẹ̀ mọ́?” Sela.
10 Èmi wí pé, “Èyí ní ẹ̀dùn ọkàn mi,
pé ọwọ́ ọ̀tún Ọ̀gá-ògo jùlọ ti yípadà”.
11 Èmi ó rántí iṣẹ́ Olúwa:
bẹ́ẹ̀ ni, èmi ó rántí iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ ọjọ́ pípẹ́.
12 Èmi ṣàṣàrò lórí iṣẹ́ rẹ gbogbo
pẹ̀lú, ènìyàn sì máa sọ̀rọ̀ gbogbo iṣẹ́ agbára rẹ.
13 Ọlọ́run, Ọ̀nà rẹ jẹ́ mímọ́.
Ọlọ́run wo ni ó sì tóbi bí Ọlọ́run wa?
14 Ìwọ ni Ọlọ́run tó ń ṣe ìyanu;
ìwọ fi agbára rẹ hàn nínú àwọn ènìyàn.
15 Pẹ̀lú ọwọ́ agbára rẹ ni ìwọ ra àwọn ènìyàn padà,
àwọn ọmọ Jakọbu àti Josẹfu. Sela.
16 Nígbà tí àwọn omi rí Ọlọ́run,
nígbà tí àwọn omi rí ọ,
ẹ̀rù bà wọ́n,
nítòótọ́ ara ibú kò balẹ̀.
17 Àwọn ojú ọ̀run tú omi sílẹ̀,
àwọsánmọ̀ fi àrá dáhùn;
ọfà rẹ̀ ń tàn sẹ́yìn àti síwájú
18 Àrá rẹ̀ ni a gbọ́ nínú ìjì,
ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀ sí gbogbo ayé;
ayé bẹ̀rù, wọ́n sì wárìrì.
19 Ipa rẹ̀ gba Òkun, ọ̀nà rẹ̀ ń bẹ nínú Òkun,
Ọ̀nà la omi alágbára kọjá ipa rẹ̀ ń bẹ nínú líla omi alágbára kọjá,
nítòótọ́ a kò rí ojú ẹsẹ̀ rẹ̀.
20 Ó tọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́ ẹran
nípa ọwọ́ Mose àti Aaroni.
9 “Ìwọ rí ìpọ́njú àwọn baba ńlá wa ní Ejibiti; ìwọ gbọ́ igbe ẹkún wọn ní Òkun pupa. 10 Ìwọ rán iṣẹ́ ààmì àti iṣẹ́ ìyanu sí Farao, sí gbogbo àwọn ìjòyè rẹ̀ àti sí gbogbo ènìyàn ilẹ̀ ẹ rẹ̀, nítorí ìwọ mọ ìwà ìgbéraga tí àwọn ará Ejibiti hù sí wọn. Ìwọ ra orúkọ fún ara à rẹ, èyí tí ó sì wà títí di òní yìí. 11 Ìwọ pín Òkun níwájú wọn, nítorí kí wọn lè kọjá ní ìyàngbẹ ilẹ̀, ṣùgbọ́n ìwọ sọ àwọn tí ń lépa wọn sínú ibú, bí òkúta sínú omi ńlá. 12 Ní ọ̀sán ìwọ darí i wọn pẹ̀lú ọ̀wọn àwọsánmọ̀ àti ní òru ni ìwọ darí i wọn pẹ̀lú ọ̀wọn iná láti fún wọn ní ìmọ́lẹ̀ ní ọ̀nà tí wọn yóò gbà.
13 “Ìwọ sọ̀kalẹ̀ wá sí orí òkè Sinai; ìwọ bá wọn sọ̀rọ̀ láti ọ̀run. Ìwọ fún wọn ní ìlànà àti àwọn òfin tí ó jẹ́ òdodo tí ó sì tọ́ àti ìlànà tí ó dára. 14 Ìwọ mú ọjọ́ ìsinmi rẹ mímọ́ di mí mọ̀ fún wọn, o sì fún wọn ní àwọn ìlànà, àwọn àṣẹ àti àwọn òfin láti ọwọ́ Mose ìránṣẹ́ rẹ. 15 Ìwọ fún wọn ní oúnjẹ láti ọ̀run wá nígbà tí ebi ń pa wọ́n àti nígbà òǹgbẹ, o fún wọn ní omi láti inú àpáta; o sì sọ fún wọn pé, kí wọ́n lọ láti lọ gba ilẹ̀ náà tí ìwọ ti jẹ́ ẹ̀jẹ́ láti fi fún wọn nípa ìgbọ́wọ́sókè.
13 (A)Nítorí náà, ẹ má ṣe tún jẹ́ kí a máa dá ara wa lẹ́jọ́ mọ́. Ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀, ẹ pinu nínú ọkàn yín láti má ṣe fi ohun ìkọ̀sẹ̀ tàbí òkúta ìdìgbòlù kankan sí ọ̀nà arákùnrin tàbí arábìnrin yín. 14 Mo mọ̀ dájú gbangba bí ẹni tí ó wà nínú Jesu Olúwa pé, kò sí ohun tó ṣe àìmọ́ fún ara rẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ka ohunkóhun sí àìmọ́, òun ni ó ṣe àìmọ́ fún. 15 (B)Bí inú arákùnrin tàbí arábìnrin rẹ ba bàjẹ́ nítorí oúnjẹ rẹ, ìwọ kò rìn nínú ìfẹ́ mọ́. Má ṣe fi oúnjẹ rẹ sọ ẹni tí Kristi kú fún di ẹni ègbé. 16 (C)Nítorí náà, ẹ má ṣe jẹ́ kí a máa sọ̀rọ̀ ohun tí ẹ mọ̀ sí rere ní búburú. 17 Nítorí ìjọba ọ̀run kì í ṣe jíjẹ àti mímu, bí kò ṣe nípa ti òdodo, àlàáfíà àti ayọ̀ nínú Ẹ̀mí Mímọ́, 18 nítorí ẹni tí ó bá sin Kristi nínú nǹkan wọ̀nyí ni ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run, tí ó sì ní ìyìn lọ́dọ̀ ènìyàn.
19 (D)Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a ṣa gbogbo ipá wa láti máa lépa àlàáfíà, àti ohun tí àwa yóò fi gbé ara wa ró. 20 (E)Má ṣe bi iṣẹ́ Ọlọ́run ṣubú nítorí oúnjẹ. Gbogbo oúnjẹ ni ó mọ́, ṣùgbọ́n ohun búburú ni fún ẹni náà tí ó jẹ ohunkóhun tí ó le mú ẹlòmíràn kọsẹ̀. 21 (F)Ó dára kí a má tilẹ̀ jẹ ẹran tàbí mu wáìnì tàbí ṣe ohunkóhun tí yóò mú arákùnrin tàbí arábìnrin rẹ ṣubú.
22 (G)Nítorí náà, ohun tí ìwọ bá gbàgbọ́ nípa gbogbo nǹkan wọ̀nyí, pa á mọ́ ní àárín ìwọ àti Ọlọ́run. Alábùkún fún ni ẹni náà tí kò dá ara rẹ̀ lẹ́bi nínú ohun tí ó yàn. 23 Ṣùgbọ́n ẹni tí ó ṣe iyèméjì, ó jẹ̀bi bí ó ba jẹ ẹ́, nítorí jíjẹ ẹ́ rẹ̀ kò ti inú ìgbàgbọ́ wá; bẹ́ẹ̀ sì ni, ohun gbogbo tí kò bá ti inú ìgbàgbọ́ wá, ẹ̀ṣẹ̀ ni.
15 Àwa tí a jẹ́ alágbára nínú ìgbàgbọ́ yẹ kí ó máa ru ẹrù àìlera àwọn aláìlera, kí a má sì ṣe ohun tí ó wu ara wa. 2 Olúkúlùkù wa gbọdọ̀ máa ṣe ohun tí ó wu ọmọnìkejì rẹ̀ sí rere, láti gbé e ró.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.