Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
19 Nígbà náà ni angẹli Ọlọ́run tó ti ń ṣáájú ogun Israẹli lọ, padà o sì rìn ni ẹ̀yìn wọn; Òpó ìkùùkuu tí ń rìn ni iwájú wọn sì padà sí í rìn ni ẹ̀yìn wọn. 20 Ó sì wà láàrín àwọn ọmọ-ogun Ejibiti àti Israẹli. Ìkùùkuu sì ṣú òkùnkùn sí àwọn ará Ejibiti ni òru náà. Ṣùgbọ́n ó tan ìmọ́lẹ̀ sí àwọn Israẹli ni òru náà; Ọ̀kan kò sì súnmọ́ èkejì ni gbogbo òru náà.
21 Nígbà náà ni Mose na ọwọ́ rẹ̀ sí orí Òkun, ni gbogbo òru náà ni Olúwa fi lé Òkun sẹ́yìn pẹ̀lú ìjì líle láti ìlà-oòrùn wá, ó sì sọ ọ́ di ìyàngbẹ ilẹ̀. Omi Òkun sì pínyà, 22 (A)àwọn ọmọ Israẹli sì la ìyàngbẹ ilẹ̀ kọjá nínú Òkun pẹ̀lú ògiri omi ní ọ̀tún àti òsì.
23 Àwọn ará Ejibiti sì ń lépa wọn, gbogbo ẹṣin Farao, kẹ̀kẹ́ ogun àti àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀ wọ́ tọ̀ wọ́n lọ sínú Òkun. 24 Ní ìṣọ́ òwúrọ̀ Olúwa bojú wo ogun àwọn ará Ejibiti láàrín ọ̀wọ̀n iná àti ìkùùkuu, ó sì kó ìpayà bá àwọn ọmọ-ogun Ejibiti. 25 Ó sì yọ àgbá ẹsẹ̀ kẹ̀kẹ́ ogun wọn kí ó bá à le ṣòro fún wọn láti fi kẹ̀kẹ́ ogun náà rìn. Àwọn ará Ejibiti wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a sá àsálà kúrò ní iwájú àwọn ará Israẹli nítorí Olúwa ń bá wa jà nítorí wọn.”
26 Olúwa sì wí fún Mose pé, “Na ọwọ́ rẹ sí orí Òkun kí omi Òkun lè ya padà sórí àwọn ará Ejibiti, kẹ̀kẹ́ ogun wọn àti sórí ẹlẹ́ṣin wọn.” 27 Mose sì na ọwọ́ rẹ̀ sí orí Òkun, Òkun sì padà bọ́ sí ipò rẹ̀ nígbà ti ilẹ̀ mọ́. Àwọn ará Ejibiti ń sá fún omi Òkun, Olúwa sì gbá wọn sínú Òkun. 28 Omi Òkun sì ya padà, ó sì bo kẹ̀kẹ́ ogun àti àwọn ẹlẹ́ṣin: àní, gbogbo ọmọ-ogun Farao tiwọn wọ inú Òkun tọ àwọn ọmọ Israẹli lọ kò sí ọ̀kan nínú wọn tí ó yè.
29 Ṣùgbọ́n àwọn ará Israẹli la Òkun kọjá lórí ìyàngbẹ ilẹ̀ pẹ̀lú ògiri omi ni ọ̀tún àti òsì wọn. 30 Ni ọjọ́ yìí ni Olúwa gba Israẹli là kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Ejibiti; Israẹli sì rí òkú àwọn ará Ejibiti ni etí Òkun. 31 Nígbà ti àwọn ọmọ Israẹli rí iṣẹ́ ìyanu ńlá ti Olúwa ṣe fún wọn lára àwọn ará Ejibiti, àwọn ènìyàn bẹ̀rù Olúwa, wọ́n sì gba Olúwa àti Mose ìránṣẹ́ rẹ gbọ́.
114 Nígbà tí Israẹli jáde ní Ejibiti,
ilé Jakọbu láti inú ènìyàn àjèjì èdè
2 Juda wà ní ibi mímọ́,
Israẹli wà ní ìjọba.
3 (A)Òkun sì rí i, ó sì wárìrì:
Jordani sì padà sẹ́yìn.
4 Àwọn òkè ńlá ń fò bí àgbò àti
òkè kéékèèkéé bí ọ̀dọ́-àgùntàn.
5 Kí ni ó ṣe ọ́, ìwọ Òkun, tí ìwọ fi wárìrì?
Ìwọ Jordani, tí ìwọ fi padà sẹ́yìn?
6 Ẹ̀yin òkè ńlá kí ló dé ti ẹ fi ń fò bí àgbò,
àti ẹ̀yin òkè kéékèèkéé bí ọ̀dọ́-àgùntàn?
7 Wárìrì, ìwọ ilẹ̀, níwájú Olúwa;
ní iwájú Ọlọ́run Jakọbu
8 tí ó sọ àpáta di adágún omi,
àti òkúta-ìbọn di orísun omi.
Orin Mose àti Miriamu
15 (A)Nígbà náà ni Mose àti àwọn ọmọ Israẹli kọ orin yìí sí Olúwa:
Èmi yóò kọrin sí Olúwa,
nítorí òun pọ̀ ní ògo.
Ẹṣin àti ẹni tí ó gùn ún
ni ó ti sọ sínú Òkun.
2 (B)Olúwa ni agbára àti orin mi;
òun ti di Olùgbàlà mi,
òun ni Ọlọ́run mi, èmi ó yìn ín,
Ọlọ́run baba mi, èmi ó gbé e ga.
3 Ológun ni Olúwa,
Olúwa ni orúkọ rẹ,
4 Kẹ̀kẹ́ ogun Farao àti ogun rẹ̀
ni ó mú wọ inú Òkun.
Àwọn ọmọ-ogun Farao tó jáfáfá jùlọ
ni ó rì sínú Òkun pupa.
5 Ibú omi bò wọ́n mọ́lẹ̀;
wọ́n sì rì sí ìsàlẹ̀ omi Òkun bí òkúta.
6 “Ọwọ́ ọ̀tún rẹ, Olúwa,
pọ̀ ní agbára.
Ọwọ́ ọ̀tún rẹ, Olúwa,
fọ́ àwọn ọ̀tá túútúú.
7 “Nínú agbára ńlá rẹ ti ó tóbi
ìwọ bi àwọn ti ó dìde sí ọ ṣubú.
Ìwọ rán ìbínú gbígbóná rẹ;
Tí ó run wọ́n bí àgémọ́lẹ̀ ìdí koríko
8 Pẹ̀lú èémí imú rẹ ni
omi fi ń wọ́jọ pọ̀.
Ìṣàn omi dìde dúró bí odi;
ibú omi sì dìpọ̀ láàrín Òkun.
9 Ọ̀tá ń gbéraga, ó ń wí pé:
‘Èmi ó lépa wọn, èmi ó bá wọn.
Èmi ó pín ìkógun;
Èmi ó tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ mi lọ́run lára wọn.
Èmi yóò fa idà mi yọ,
ọwọ́ mi yóò pa wọ́n run.’
10 Ìwọ fẹ́ èémí rẹ,
òkun ru bò wọ́n mọ́lẹ̀.
Wọ́n rì bí òjé
ni àárín omi ńlá.
11 Ta ni nínú àwọn òrìṣà
tó dàbí rẹ, Olúwa?
Ta ló dàbí rẹ:
ní títóbi,
ní mímọ́ Ẹlẹ́rù ni yìn,
tí ń ṣe ohun ìyanu?
20 Miriamu wòlíì obìnrin, arábìnrin Aaroni, mú ohun èlò orin ni ọwọ́ rẹ̀, gbogbo àwọn obìnrin sì jáde tẹ̀lé e pẹ̀lú ìlù òun ijó. 21 Miriamu kọrin sí wọn báyìí pé:
“Ẹ kọrin sí Olúwa
Nítorí òun ni ológo jùlọ
Ẹṣin àti ẹni tí ó gùn ún
Ni òun bi ṣubú sínú Òkun.”
Aláìlera àti alágbára
14 Ẹ gba ẹni tí ó bá ṣe àìlera ní ìgbàgbọ́ mọ́ra, kí ẹ má ṣe tọpinpin ìṣeyèméjì rẹ̀. 2 Ẹnìkan gbàgbọ́ pé òun lè máa jẹ ohun gbogbo: ṣùgbọ́n ẹlòmíràn tí ó sì jẹ́ aláìlera ní ìgbàgbọ́ ń jẹ ewébẹ̀ nìkan. 3 (A)Kí ẹni tí ń jẹ ohun gbogbo má ṣe kẹ́gàn ẹni tí kò jẹ; kí ẹni tí kò sì jẹ ohun gbogbo kí ó má ṣe dá ẹni tí ń jẹ lẹ́bi: nítorí Ọlọ́run ti gbà á. 4 Ta ni ìwọ láti dá ọmọ ọ̀dọ̀ ẹlòmíràn lẹ́jọ́? Lójú olúwa tirẹ̀ ni òun dúró, tàbí ṣubú. Òun yóò sì dúró nítorí Ọlọ́run ní agbára láti mú kí òun dúró.
5 (B)Ẹnìkan bu ọlá fún ọjọ́ kan ju òmíràn; ẹlòmíràn bu ọlá fún ọjọ́ gbogbo bákan náà. Kí olúkúlùkù kí ó dá ara rẹ̀ lójú ní inú ara rẹ̀. 6 Ẹni tí ó bá ya ọjọ́ kan sí ọ̀tọ̀, ó ń yà á sọ́tọ̀ fún Olúwa. Ẹni tí ó ń jẹ ẹran, ó ń jẹ ẹran fún Olúwa, nítorí pé òun náà dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run; ẹni tí kò bá sì jẹ ẹran, kò jẹ ẹran fún Olúwa, òun náà dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run. 7 (C)Nítorí kò sí ẹnìkan tí ó wà láààyè fún ara rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí ó kú fún ara rẹ̀. 8 (D)Bí a bá wà láààyè, a wà láààyè fún Olúwa; bí a bá sì kú, a kú fún Olúwa. Nítorí náà, bí a wà láààyè, tàbí bí a kú, ti Olúwa ni àwa i ṣe. 9 Nítorí ìdí èyí náà ni Kristi ṣe kú, tí ó sì tún yè, kí ó bá le jẹ́ Olúwa òkú àti alààyè.
10 (E)Èéṣe nígbà náà tí ìwọ fi ń dá arákùnrin tàbí arábìnrin rẹ lẹ́jọ́? Tàbí èéṣe tí ìwọ fi ń gàn wọn? Nítorí gbogbo wa ni yóò dúró níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ Ọlọ́run. 11 (F)A ti kọ ìwé rẹ̀ pé:
“ ‘Níwọ́n ìgbà tí mo wà láààyè,’ ni Olúwa wí,
‘gbogbo eékún ni yóò wólẹ̀ fún mi;
gbogbo ahọ́n ni yóò jẹ́wọ́ fún Ọlọ́run.’ ”
12 Ǹjẹ́ nítorí náà, olúkúlùkù wa ni yóò jíyìn ara rẹ̀ fún Ọlọ́run.
Òwe aláìláàánú ọmọ ọ̀dọ̀
21 (A)Nígbà náà ni Peteru wá sọ́dọ̀ Jesu, ó béèrè pé, “Olúwa, nígbà mélòó ni arákùnrin mi yóò ṣẹ̀ mi, tí èmi yóò sì dáríjì í? Tàbí ní ìgbà méje ni?”
22 Jesu dáhùn pé, “Mo wí fún ọ, kì í ṣe ìgbà méje, ṣùgbọ́n ní ìgbà àádọ́rin méje.
23 (B)“Nítorí náà, ìjọba ọ̀run dàbí ọba kan tí ó fẹ́ ṣe ìṣirò pẹ̀lú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀. 24 Bí ó ti ń ṣe èyí, a mú ajigbèsè kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀ tí ó jẹ ẹ́ ní ẹgbàárùn-ún (10,000) tálẹ́ǹtì. 25 Nígbà tí kò tì í ní agbára láti san án, nígbà náà ni olúwa rẹ̀ pàṣẹ pé kí a ta òun àti ìyàwó àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó ní láti fi san gbèsè náà.
26 (C)“Nígbà náà ni ọmọ ọ̀dọ̀ náà wólẹ̀ lórí eékún níwájú rẹ. ‘Ó bẹ̀bẹ̀ pé, mú sùúrù fún mi, èmi yóò sì san gbogbo rẹ̀ fún ọ.’ 27 Nígbà náà, ni olúwa ọmọ ọ̀dọ̀ náà sì ṣàánú fún un. Ó tú u sílẹ̀, ó sì fi gbèsè náà jì í.
28 “Ṣùgbọ́n bí ọmọ ọ̀dọ̀ náà ti jáde lọ, ó rí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ ẹgbẹ́ rẹ̀ tí ó jẹ ẹ́ ní ọgọ́rùn-ún owó idẹ, ó gbé ọwọ́ lé e, ó fún un ní ọrùn, ó wí pé, ‘san gbèsè tí o jẹ mí lójú ẹsẹ̀.’
29 “Ọmọ ọ̀dọ̀ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ náà sì wólẹ̀ lórí eékún níwájú rẹ̀, ò ń bẹ̀ ẹ́ pé, ‘Mú sùúrù fún mi, èmi yóò sì san án fún ọ.’
30 “Ṣùgbọ́n òun kọ̀ fún un. Ó pàṣẹ kí a mú ọkùnrin náà, kí a sì jù ú sínú túbú títí tí yóò fi san gbèsè náà tán pátápátá. 31 Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, inú bí wọn gidigidi, wọ́n lọ láti lọ sọ fún olúwa wọn, gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀.
32 “Nígbà tí olúwa rẹ̀ pè ọmọ ọ̀dọ̀ náà wọlé, ó wí fún un pé, ‘Ìwọ ọmọ ọ̀dọ̀ búburú, níhìn-ín ni mo ti dárí gbogbo gbèsè rẹ jì ọ́ nítorí tí ìwọ bẹ̀ mi. 33 Kò ha ṣe ẹ̀tọ́ fún ọ láti ṣàánú fún àwọn ẹlòmíràn, gẹ́gẹ́ bí èmi náà ti ṣàánú fún ọ?’ 34 Ní ìbínú, olówó rẹ̀ fi í lé àwọn onítúbú lọ́wọ́ láti fi ìyà jẹ ẹ́, títí tí yóò fi san gbogbo gbèsè èyí ti ó jẹ ẹ́.
35 (D)“Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sì ni Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run yóò sí ṣe sì ẹnìkọ̀ọ̀kan, bí ẹ̀yin kò bá fi tọkàntọkàn dárí ji àwọn arákùnrin yín.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.