Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
114 Nígbà tí Israẹli jáde ní Ejibiti,
ilé Jakọbu láti inú ènìyàn àjèjì èdè
2 Juda wà ní ibi mímọ́,
Israẹli wà ní ìjọba.
3 (A)Òkun sì rí i, ó sì wárìrì:
Jordani sì padà sẹ́yìn.
4 Àwọn òkè ńlá ń fò bí àgbò àti
òkè kéékèèkéé bí ọ̀dọ́-àgùntàn.
5 Kí ni ó ṣe ọ́, ìwọ Òkun, tí ìwọ fi wárìrì?
Ìwọ Jordani, tí ìwọ fi padà sẹ́yìn?
6 Ẹ̀yin òkè ńlá kí ló dé ti ẹ fi ń fò bí àgbò,
àti ẹ̀yin òkè kéékèèkéé bí ọ̀dọ́-àgùntàn?
7 Wárìrì, ìwọ ilẹ̀, níwájú Olúwa;
ní iwájú Ọlọ́run Jakọbu
8 tí ó sọ àpáta di adágún omi,
àti òkúta-ìbọn di orísun omi.
Kíkọjá ni Òkun pupa
17 Ní ìgbà tí Farao jẹ́ kí àwọn ènìyàn ó lọ, Ọlọ́run kò mú wọn tọ ojú ọ̀nà ti ó la orílẹ̀-èdè àwọn Filistini kọjá, bí o tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀nà náà kúrú. Nítorí Ọlọ́run sọ pé, “Bí wọ́n bá dojúkọ ogun, wọ́n lè yí ọkàn wọn padà kí wọ́n padà sí ilẹ̀ Ejibiti.” 18 Nítorí náà Ọlọ́run darí àwọn ènìyàn rọkọ gba ọ̀nà aginjù ní apá Òkun Pupa. Àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti pẹ̀lú ìmúra fún ogun.
19 (A)Mose kó egungun Josẹfu pẹ̀lú rẹ̀ nítorí Josẹfu tí mú kí àwọn ọmọ Israẹli búra. Ó ti wí pé, “Dájúdájú Ọlọ́run yóò dìde fún ìrànlọ́wọ́ yín ẹ sì gbọdọ̀ kó egungun mi lọ pẹ̀lú yín kúrò níhìn-ín yìí.”
20 Wọ́n sì mú ọ̀nà wọn pọ̀n láti Sukkoti lọ, wọ́n sì pàgọ́ sí Etamu ní etí aginjù. 21 Olúwa sì ń lọ níwájú wọn, nínú ọ̀wọ̀n ìkùùkuu ní ọ̀sán láti máa ṣe amọ̀nà wọn àti ní òru nínú ọ̀wọ̀n iná láti máa tan ìmọ́lẹ̀ fún wọn, kí wọn lè máa lọ nínú ìrìnàjò wọn ní tọ̀sán tòru. 22 Ìkùùkuu náà kò kúrò ní ààyè rẹ̀ ní ọ̀sán, bẹ́ẹ̀ ni, ọ̀wọ̀n iná kò kúrò ní ààyè rẹ̀ ni òru, ní iwájú àwọn ènìyàn náà.
Fẹ́ràn ọmọnìkejì rẹ
11 (A)Nítorí èyí ni iṣẹ́ tí ẹ̀yin tí gbọ́ ni àtètèkọ́ṣe, pé ki àwa fẹ́ràn ara wa. 12 Kì í ṣe bí Kaini, tí í ṣe ẹni búburú, tí o sì pa arákùnrin rẹ̀. Nítorí kín ni ó sì ṣe pa á? Nítorí tí iṣẹ́ tirẹ̀ jẹ́ búburú ṣùgbọ́n tí arákùnrin rẹ̀ sì jẹ́ òdodo. 13 (B)Kì ẹnu má ṣe yà yín, ẹ̀yin ará mi, bí ayé bá kórìíra yín. 14 (C)Àwa mọ̀ pé àwa tí rékọjá láti inú ikú sínú ìyè, nítorí tí àwa fẹ́ràn àwọn ará. Ẹni tí kò ba ni ìfẹ́, ó ń gbé inú ikú. 15 Ẹnikẹ́ni tí ó ba kórìíra arákùnrin rẹ̀ apànìyàn ni: ẹ̀yin sì mọ́ pé kò sí apànìyàn tí ó ni ìyè àìnípẹ̀kun láti máa gbé inú rẹ̀.
16 (D)Nípa èyí ni àwa mọ ìfẹ́ nítorí tí ó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún wa: ó sì yẹ kí àwa fi ẹ̀mí wa lélẹ̀ fún àwọn ará.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.