Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Orin. Saamu ti Asafu.
83 Ọlọ́run, má ṣe dákẹ́;
Má ṣe dákẹ́, Ọlọ́run má ṣe dúró jẹ́ẹ́.
2 Wo bí àwọn ọ̀tá rẹ ti ń rọ́kẹ̀kẹ̀ lọ,
bi àwọn ọ̀tá rẹ ti ń gbé ohùn wọn sókè.
3 Pẹ̀lú àrékérekè ni wọn dìtẹ̀ sí àwọn ènìyàn rẹ;
wọn sí dìtẹ̀ mọ́ àwọn tí o fẹ́.
4 Wọn wí pé, “wá, ẹ jẹ́ kí á pa wọ́n run bí orílẹ̀-èdè,
kí orúkọ Israẹli ma bá a sí ní ìrántí mọ́.”
13 Ìwọ Ọlọ́run, ṣe wọ́n bí ààjà,
bí ìyàngbò níwájú afẹ́fẹ́.
14 Bí iná ti í jó igbó,
àti bí ọ̀wọ́-iná ti ń mú òkè ńlá gbiná,
15 Bẹ́ẹ̀ ni kí o fi ẹ̀fúùfù líle rẹ lépa wọn
dẹ́rùbà wọn lójú pẹ̀lú ìjì rẹ.
16 Fi ìtìjú kún ojú wọn,
kí àwọn ènìyàn bá à lè ṣe àfẹ́rí orúkọ rẹ àti kí o fi ìjì líle rẹ dẹ́rùbà, ìwọ Olúwa.
17 Jẹ́ kí ojú kí ó tì wọ́n, kí wọ́n sì dààmú láéláé
kí wọ́n ṣègbé sínú ẹ̀gàn
18 Jẹ́ kí wọn mọ̀ pé ìwọ, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Olúwa:
pé ìwọ nìkan ní Ọ̀gá-ògo jùlọ lórí gbogbo ayé.
Omí di ẹ̀jẹ̀
14 Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, “Ọkàn Farao ti di líle, ó kọ̀ láti jẹ́ kí àwọn ènìyàn náà ó lọ. 15 Tọ Farao lọ ni òwúrọ̀ kùtùkùtù bí ó ti ń lọ sí etí odò, dúró ni etí bèbè odò Naili láti pàdé rẹ, mú ọ̀pá rẹ tí ó di ejò ni ọwọ́ rẹ. 16 Sọ fún un pé, ‘Olúwa Ọlọ́run àwọn Heberu rán mi sí ọ láti sọ fún ọ pé: Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mi kí ó lọ, kí wọn kí ó lè sìn mi ni aginjù. Ṣùgbọ́n títí di àkókò yìí, ìwọ kò gba. 17 (A)Èyí ni Olúwa wí: Nípa èyí ni ìwọ yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa. Wò ó, èmi yóò fi ọ̀pá ti ó wà ní ọwọ́ mi, èmi yóò ná omi tí ó wà nínú odò Naili yóò sì di ẹ̀jẹ̀. 18 Àwọn ẹja tí ó wà nínú odò Naili yóò kú, odò náà yóò sì máa rùn, àwọn ará Ejibiti kò sì ni lè mu omi rẹ̀.’ ”
19 Olúwa sọ fún Mose, “Sọ fún Aaroni, ‘Mú ọ̀pá rẹ kí ó sì na ọwọ́ rẹ jáde lórí àwọn omi Ejibiti. Lórí àwọn odò kéékèèkéé àti odò ńlá, lórí àbàtà àti adágún omi, wọn yóò sì di ẹ̀jẹ̀.’ Ẹ̀jẹ̀ yóò wà ni ibi gbogbo ni Ejibiti, àní nínú ọpọ́n àti nínú kete omi àti nínú ìkòkò tí a pọn omi sí nínú ilé.”
20 Mose àti Aaroni sí ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún wọn. Ó gbé ọ̀pá rẹ̀ sókè ni iwájú Farao àti àwọn ìjòyè rẹ̀, ó sì lu omi odò Naili, omi odò náà sì yípadà sí ẹ̀jẹ̀. 21 Ẹja inú odò Naili sì kú, odò náà ń rùn gidigidi tí ó fi jẹ́ pé àwọn ará Ejibiti kò le è mu omi inú rẹ̀. Ẹ̀jẹ̀ sì wà ni ibi gbogbo ni ilẹ̀ Ejibiti.
22 Ṣùgbọ́n àwọn apidán ilẹ̀ Ejibiti sì ṣe bákan náà pẹ̀lú agbára òkùnkùn wọn, ọkàn Farao sì yigbì síbẹ̀ kò sì fetí sí wọn gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ. 23 Dípò bẹ́ẹ̀, ó yíjú padà, ó sì lọ sí ààfin rẹ̀, kò sì jẹ́ kí àwọn nǹkan wọ̀nyí wà ni oókan àyà rẹ̀. 24 Nígbà náà ni gbogbo àwọn ará Ejibiti bẹ̀rẹ̀ sí í gbẹ́ etí odò Naili láti wá omi tí wọn yóò mu, nítorí wọn kò le è mu omi tí ó wà nínú odò náà.
Àwọn ọ̀pọ̀lọ́ bo orí ilẹ̀
25 Ọjọ́ méje sì kọjá ti Olúwa ti lu odò Naili.
Jesu àti Beelsebulu
22 (A)(B) Nígbà náà ni wọ́n mú ọkùnrin kan tó ni ẹ̀mí èṣù tọ̀ ọ́ wá, tí ó afọ́jú, tí ó tún ya odi. Jesu sì mú un láradá kí ó le sọ̀rọ̀, ó sì ríran. 23 Ẹnu sì ya gbogbo àwọn ènìyàn. Wọ́n wí pé, “Èyí ha lè jẹ́ Ọmọ Dafidi bí?”
24 (C)Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn Farisi gbọ́ èyí, wọ́n wí pé, “Nípa Beelsebulu nìkan, tí í ṣe ọba ẹ̀mí èṣù ni ọkùnrin yìí fi lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.”
25 Jesu tí ó mọ èrò wọn, ó wí fún wọn pé, “Ìjọbakíjọba tí ó bá yapa sí ara rẹ̀ yóò parun, ìlúkílùú tàbí ilékílé tí ó bá yapa sí ara rẹ̀ kì yóò dúró. 26 Bí èṣù bá sì ń lé èṣù jáde, a jẹ́ wí pé, ó ń yapa sí ara rẹ̀. Ìjọba rẹ yóò ha ṣe le dúró? 27 Àti pé, bi èmi bá ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde nípa Beelsebulu, nípa ta ni àwọn ènìyàn yín fi ń lé wọn jáde? Nítorí náà ni wọn yóò ṣe má ṣe ìdájọ́ yín. 28 Ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ pé nípa Ẹ̀mí Ọlọ́run ni èmi fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, a jẹ́ pé ìjọba Ọlọ́run ti dé bá yín.
29 “Tàbí, báwo ni ẹnikẹ́ni ṣe lè wọ ilé alágbára lọ kí ó sì kó ẹrù rẹ̀, bí kò ṣe pé ó kọ́kọ́ di alágbára náà? Nígbà náà ni ó tó lè kó ẹrù rẹ̀ lọ.
30 (D)“Ẹni tí kò bá wà pẹ̀lú mi, òun lòdì sí mi, ẹni tí kò bá mi kójọpọ̀ ń fọ́nká. 31 Nítorí èyí, mo wí fún yín, gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àti ọ̀rọ̀-òdì ni a yóò dárí rẹ̀ jí ènìyàn, ṣùgbọ́n ìṣọ̀rọ̀-òdì-sí Ẹ̀mí Mímọ́ kò ní ìdáríjì. 32 Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀-òdì sí Ọmọ ènìyàn, a ó dáríjì í, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá sọ ọ̀rọ̀-òdì sí ẹ̀mí mímọ́, a kì yóò dáríjì í, ìbá à ṣe ní ayé yìí tàbí ní ayé tí ń bọ̀.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.