Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 83:1-4

Orin. Saamu ti Asafu.

83 Ọlọ́run, má ṣe dákẹ́;
    Má ṣe dákẹ́, Ọlọ́run má ṣe dúró jẹ́ẹ́.
Wo bí àwọn ọ̀tá rẹ ti ń rọ́kẹ̀kẹ̀ lọ,
    bi àwọn ọ̀tá rẹ ti ń gbé ohùn wọn sókè.
Pẹ̀lú àrékérekè ni wọn dìtẹ̀ sí àwọn ènìyàn rẹ;
    wọn sí dìtẹ̀ mọ́ àwọn tí o fẹ́.
Wọn wí pé, “wá, ẹ jẹ́ kí á pa wọ́n run bí orílẹ̀-èdè,
    kí orúkọ Israẹli ma bá a sí ní ìrántí mọ́.”

Saamu 83:13-18

13 Ìwọ Ọlọ́run, ṣe wọ́n bí ààjà,
    bí ìyàngbò níwájú afẹ́fẹ́.
14 Bí iná ti í jó igbó,
    àti bí ọ̀wọ́-iná ti ń mú òkè ńlá gbiná,
15 Bẹ́ẹ̀ ni kí o fi ẹ̀fúùfù líle rẹ lépa wọn
    dẹ́rùbà wọn lójú pẹ̀lú ìjì rẹ.
16 Fi ìtìjú kún ojú wọn,
    kí àwọn ènìyàn bá à lè ṣe àfẹ́rí orúkọ rẹ àti kí o fi ìjì líle rẹ dẹ́rùbà, ìwọ Olúwa.

17 Jẹ́ kí ojú kí ó tì wọ́n, kí wọ́n sì dààmú láéláé
    kí wọ́n ṣègbé sínú ẹ̀gàn
18 Jẹ́ kí wọn mọ̀ pé ìwọ, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Olúwa:
    pé ìwọ nìkan ní Ọ̀gá-ògo jùlọ lórí gbogbo ayé.

Eksodu 4:10-31

10 Mose sì sọ fún Olúwa pé, “Èmi jẹ́ akólòlò, èmi kì í ṣe ẹni tó lè sọ̀rọ̀ já gaara láti ìgbà àtijọ́ wá tàbí láti ìgbà ti o ti ń bá ìránṣẹ́ rẹ sọ̀rọ̀, mo jẹ́ ẹni ti ahọ́n rẹ̀ lọ́, tí ó sì ń lọ́ra àti sọ̀rọ̀.”

11 Olúwa sì sọ fún un pé, “Ta ni ó fún ènìyàn ni ẹnu? Ta ni ó mú un ya odi tàbí adití? Ta ni ó mú un ríran, tàbí mú un fọ́jú? Ǹjẹ́ kì í ṣe Èmi Olúwa? 12 Lọ nísinsin yìí, èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti sọ̀rọ̀. Èmi yóò sì kọ́ ọ ni ohun ti ìwọ yóò sọ.”

13 Mose dáhùn ó wí pé, “Olúwa jọ̀wọ́ rán ẹlòmíràn láti lọ ṣe iṣẹ́ yìí.”

14 Ìbínú Ọlọ́run ru sókè sí Mose, ó sì sọ pé, “Aaroni ará Lefi arákùnrin rẹ ńkọ́? Mo mọ̀ pé ó lè sọ̀rọ̀ já gaara, ó ti wà ní ọ̀nà rẹ̀ báyìí láti pàdé e rẹ. Inú rẹ̀ yóò sì dùn ti ó bá rí ọ. 15 Ìwọ yóò sọ̀rọ̀ fún un, ìwọ yóò sì fi ọ̀rọ̀ sí i lẹ́nu: Èmi yóò ràn yín lọ́wọ́ láti sọ̀rọ̀. Èmi yóò kọ́ ọ yín ni ohun ti ẹ ó ṣe. 16 Òun yóò bá ọ sọ̀rọ̀ sí àwọn ènìyàn, yóò sì dàbí i pé ẹnu un rẹ ni a gbà sọ ọ̀rọ̀ náà, ìwọ yóò sì dàbí Ọlọ́run ní iwájú rẹ̀. 17 Ṣùgbọ́n mú ọ̀pá yìí ni ọwọ́ rẹ kí ìwọ bá à lè fi ṣe àwọn iṣẹ́ ààmì ìyanu pẹ̀lú rẹ̀.”

Mose padà sí Ejibiti

18 Mose padà sí ọ̀dọ̀ Jetro baba ìyàwó rẹ̀, ó sì sọ fún un pé, “Jọ̀wọ́ jẹ́ kí n padà tọ àwọn ènìyàn mi lọ ni ilẹ̀ Ejibiti láti wò bóyá wọ́n ṣì wà láààyè síbẹ̀.”

Jetro sì dáhùn, ó wí pé, “Máa lọ ni àlàáfíà.”

19 (A)Nísinsin yìí, Olúwa ti sọ fún Mose ni ilẹ̀ Midiani pé, “Máa padà lọ sí Ejibiti, nítorí àwọn ti ó fẹ́ pa ọ ti kú.” 20 Mose mú ìyàwó rẹ̀ àti àwọn ọmọ rẹ̀, ó kó wọn lé orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò rẹ̀ padà sí Ejibiti. Ó sì mú ọ̀pá Ọlọ́run sí ọwọ́ rẹ̀.

21 Olúwa sì sọ fún Mose pé, “Ní ìgbà tí ìwọ bá padà sí Ejibiti rí i pé ìwọ ṣe iṣẹ́ ìyanu ni iwájú Farao. Èmi ti fún ọ lágbára láti ṣe é. Èmi yóò sì sé àyà rẹ̀ le, òun kì yóò jẹ́ kí àwọn ènìyàn náà kí ó lọ. 22 Lẹ́yìn náà, kí o sọ fún Farao pé, ‘Èyí ni Olúwa sọ: Israẹli ní àkọ́bí ọmọ mi ọkùnrin, 23 (B)mo sọ fún ọ, “Jẹ́ kí ọmọ mi lọ, ki òun kí ó lè máa sìn mí.” Ṣùgbọ́n ìwọ kọ̀ láti jẹ́ kí ó lọ; nítorí náà, èmi yóò pa àkọ́bí ọmọ rẹ ọkùnrin.’ ”

24 Ní ọ̀nà ìrìnàjò rẹ, ni ibi tí wọ́n gbé sùn ní ilé èrò ní alẹ́, Olúwa pàdé Mose, ó sì fẹ́ láti pa á. 25 Ṣùgbọ́n Sippora mú ọ̀bẹ òkúta mímú, ó sì kọ ọmọ rẹ̀ ní ilà abẹ́, ó sì fi awọ rẹ̀ kan ẹsẹ̀ Mose. Sippora sì wí pé, “Ọkọ ẹlẹ́jẹ̀ ni ìwọ jẹ́ sí mi.” 26 Nítorí náà Olúwa yọ̀ǹda rẹ láti ìgbà tí ó ti wí pé, “Ẹlẹ́jẹ̀ ni ìwọ í ṣe.” Èyí tó túmọ̀ sí ìkọlà abẹ́.

27 Olúwa sì sọ fún Aaroni pé, “Lọ sínú aginjù láti lọ pàdé Mose.” Ní ìgbà náà ni ó lọ pàdé Mose ní orí òkè Ọlọ́run, ó sì fi ẹnu kò ó ní ẹnu. 28 Ní ìgbà náà ni Mose sì sọ ohun gbogbo tí Ọlọ́run ti rán fún Aaroni àti nípa gbogbo iṣẹ́ ìyanu tí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún un láti ṣe ní iwájú Farao.

29 Mose àti Aaroni pe gbogbo àwọn àgbàgbà Israẹli jọ. 30 Aaroni sọ ohun gbogbo tí Olúwa sọ fún Mose fún wọn, ó sì ṣe iṣẹ́ ààmì náà ní ojú àwọn ènìyàn náà. 31 Wọ́n sì gbàgbọ́. Nígbà tí wọ́n gbọ́ pé Olúwa ti bẹ àwọn ọmọ Israẹli wò àti pé Olúwa ti gbọ́ nípa ìpọ́njú wọn, wọ́n tẹríba, wọ́n sì sìn Ín. Ó sì ṣe àwọn iṣẹ́ ààmì náà níwájú àwọn ènìyàn náà.

Ìfihàn 3:1-6

Sí ìjọ ní Sardi

“Àti sí angẹli ìjọ ni Sardi kọ̀wé:

Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni ẹni tí ó ni Ẹ̀mí méje Ọlọ́run, àti ìràwọ̀ méje wí pé:

Èmi mọ iṣẹ́ rẹ̀, àti pé ìwọ ní orúkọ pé ìwọ ń bẹ láààyè, ṣùgbọ́n ìwọ ti kú. Jí, kí o sì fi ẹsẹ̀ ohun tí ó kù múlẹ̀, tàbí tí ó ṣetán láti kú: Nítorí èmi kò rí iṣẹ́ rẹ ni pípé níwájú Ọlọ́run. Nítorí náà rántí bí ìwọ ti gbà, àti bí ìwọ ti gbọ́, kí o sì pa á mọ́, kí o sì ronúpìwàdà. Ǹjẹ́, bí ìwọ kò ba ṣọ́ra, èmi yóò dé sí ọ bí olè, ìwọ kì yóò sì mọ́ wákàtí tí èmi yóò dé sí ọ.

Ìwọ ní orúkọ díẹ̀ ní Sardi, tí kò fi aṣọ wọn yí èérí; wọn yóò sì máa ba mi rìn ní aṣọ funfun: nítorí wọ́n yẹ. (A)Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun, òun náà ni a ó fi aṣọ funfun wọ̀; èmi kì yóò pa orúkọ rẹ̀ kúrò nínú ìwé ìyè, ṣùgbọ́n èmi yóò jẹ́wọ́ orúkọ rẹ̀ níwájú Baba mi, àti níwájú àwọn angẹli rẹ̀. Ẹni tí ó ba létí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.