Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 28

Ti Dafidi.

28 Ìwọ Olúwa,
    mo ké pe àpáta mi;
    Má ṣe kọ etí dídi sí mi.
Tí ìwọ bá dákẹ́ sí mi,
    èmí yóò dàbí àwọn tí ó lọ sí ọ̀gbun.
Gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi fún àánú,
    bí mo ṣe ń ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́,
bí mo ṣe gbé àwọn ọwọ́ mi sókè
    sí ibi mímọ́ rẹ jùlọ.

Má ṣe fà mí lọ pẹ̀lú ènìyàn búburú àti,
    pẹ̀lú àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀,
tí ń sọ̀rọ̀ àlàáfíà sí aládùúgbò wọn
    ṣùgbọ́n tí ìwà ìkà ń bẹ nínú wọn.
San ẹ̀san wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn
    àti fún iṣẹ́ ibi wọn;
gba ẹ̀san wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ wọn;
    kí o sì san ẹ̀san wọn bí ó ti tọ́.

Nítorí pé wọn kò ka iṣẹ́ Olúwa sí,
    tàbí àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀
òun ó rún wọn wọlẹ̀
    kì yóò sì gbé wọn ró mọ́.

Alábùkún fún ni Olúwa!
    Nítorí pé ó ti gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.
Olúwa ni agbára mi àti asà mi;
    nínú rẹ̀ ni mo gbẹ́kẹ̀lé; àní, ó sì ràn mí lọ́wọ́.
Ọkàn mi sì gbé sókè fún ayọ̀
    àní pẹ̀lú orin mi mo fi ọpẹ́ fún un.

Olúwa ni agbára àwọn ènìyàn rẹ̀
    òun ni odi ìgbàlà àwọn ẹni ààmì òróró rẹ̀.
Ìwọ gba àwọn ènìyàn rẹ là, kí o sì bùkún àwọn ajogún rẹ;
    di olùṣọ́-àgùntàn wọn, kí o sì gbé wọn lékè títí ayérayé.

Gẹnẹsisi 39

Josẹfu àti aya Potiferi

39 (A)Nígbà tí wọ́n mú Josẹfu dé Ejibiti, Potiferi, ará Ejibiti tí i ṣe ọ̀kan nínú àwọn ìjòyè Farao. Òun ni olórí àwọn ọmọ-ogun Farao. Ó ra Josẹfu lọ́wọ́ àwọn ará Iṣmaeli tí wọ́n mú un lọ síbẹ̀.

Olúwa sì wà pẹ̀lú Josẹfu, ó sì bùkún un, ó sì ń gbé ní ilé ọ̀gá rẹ̀ ará Ejibiti. Nígbà tí ọ̀gá rẹ̀ rí i pé Olúwa wà pẹ̀lú rẹ̀, àti pé Olúwa jẹ́ kí ó máa ṣe àṣeyọrí nínú ohun gbogbo tí ó dáwọ́ rẹ̀ lé. Josẹfu sì rí ojúrere Potiferi, ó sì di aṣojú rẹ̀, Potiferi fi Josẹfu ṣe olórí ilé rẹ̀ àti ohun gbogbo tí ó ní. Láti ìgbà tí ó ti fi Josẹfu jẹ olórí ilé rẹ̀ àti ohun ìní rẹ̀ gbogbo, ni Ọlọ́run ti bẹ̀rẹ̀ sí ní bùkún àwọn ará Ejibiti nítorí Josẹfu. Ìbùkún Olúwa wà lórí gbogbo ohun tí Potiferi ní, nílé àti lóko. Ó sì fi Josẹfu ṣe àkóso gbogbo ohun tí ó ní. Kò sì ṣe ìyọnu lórí ohunkóhun mọ àyàfi nípa oúnjẹ tí ó ń jẹ láti ìgbà tí ó ti fi Josẹfu ṣe àkóso ilé e rẹ̀.

Josẹfu sì jẹ́ arẹwà ọkùnrin ní ìdúró àti ìrísí rẹ̀, lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, aya rẹ̀ ṣe àkíyèsí Josẹfu, ó sì wí fún un pé, “Wá bá mi lòpọ̀!”

Ṣùgbọ́n Josẹfu kọ̀, ó sì wí fún aya ọ̀gá rẹ̀ pé, “Kíyèsi, Olúwa mi kò fi ohunkóhun dù mi nínú ilé yìí, gbogbo ohun ìní rẹ̀ ni ó fi lé mi lọ́wọ́. Kò sí ẹni tí ó jù mi lọ nínú ilé yìí, ọ̀gá mi kò fi ohunkóhun dù mi àyàfi ìwọ, tí í ṣe aya rẹ̀. Báwo ni mo ṣe lè ṣe ohun búburú yìí, kí ń sì ṣẹ̀ sí Ọlọ́run?” 10 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ìgbà ni ó ń tẹnumọ́ èyí fún Josẹfu, Josẹfu kọ̀ láti bá a lòpọ̀. Ó tilẹ̀ kọ̀ láti máa dúró ni ibi tí ó bá wà.

11 Ní ọjọ́ kan, Josẹfu lọ sínú ilé láti ṣe iṣẹ́, kò sì sí èyíkéyìí nínú àwọn ìránṣẹ́ ní tòsí. 12 Ó sì di aṣọ Josẹfu mú, ó sì wí pé, “Wá bá mi lòpọ̀!” Ṣùgbọ́n Josẹfu fi aṣọ rẹ̀ sílẹ̀ sí i lọ́wọ́, ó sì sá jáde.

13 Nígbà tí ó rí i pé ó ti fi aṣọ rẹ̀ sílẹ̀ sí òun lọ́wọ́, ó sì ti sá jáde, 14 ó pe àwọn ìránṣẹ́ ilé náà, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ wò ó, ọkọ ọ̀ mi mú Heberu kan wọlé tọ̀ wá wá láti fi wá ṣe ẹlẹ́yà. Ó wọlé tọ̀ mí wá, láti bá mi lòpọ̀, ṣùgbọ́n mo kígbe. 15 Nígbà tí ó gbọ́ pé mo gbé ohùn mi sókè, tí mo sì kígbe, ó jọ̀wọ́ aṣọ rẹ̀ sọ́dọ̀ mi, ó sì sá, ó bọ́ sóde.”

16 Ó sì fi aṣọ náà sọ́dọ̀ títí tí ọkọ rẹ̀ fi dé. 17 Ó rò fún un pé, “Ẹrú ará Heberu tí o rà wá ilé láti fi wá ṣẹlẹ́yà wá láti bá mi lòpọ̀. 18 Ṣùgbọ́n bí mo ti kígbe fún ìrànlọ́wọ́, ó sì sá kúrò nínú ilé.”

19 Nígbà tí Potiferi gbọ́ ọ̀rọ̀ aya rẹ̀ pé báyìí ni ẹrú rẹ̀ ṣe sí aya rẹ̀, ó bínú gidigidi. 20 Ó sì ju Josẹfu sí ẹ̀wọ̀n, níbi tí a ń ju àwọn ẹlẹ́wọ̀n ọba sí.

Ṣùgbọ́n, nígbà tí Josẹfu wà nínú ẹ̀wọ̀n níbẹ̀, 21 (B)Olúwa sì wà pẹ̀lú rẹ̀, ó sì ṣàánú fún un, ó sì mú kí ó rí ojúrere àwọn alábojútó ọgbà ẹ̀wọ̀n (wọ́dà). 22 Nítorí náà, alábojútó ọgbà ẹlẹ́wọ̀n fi Josẹfu ṣe alákòóso ohun gbogbo tí ó wà nínú ẹ̀wọ̀n, àti ohun tí wọn ń ṣe níbẹ̀. 23 Wọ́dà náà kò sì mikàn nípa gbogbo ohun tí ó fi sí abẹ́ àkóso Josẹfu, nítorí pé Olúwa wà pẹ̀lú Josẹfu, ó sì ń jẹ́ kí ó ṣe àṣeyọrí nínú ohun gbogbo tí ó dáwọ́lé.

Romu 9:14-29

14 (A)Ǹjẹ́ àwa yóò ha ti wí? Àìṣòdodo ha wà lọ́dọ̀ Ọlọ́run bí? Kí a má ri! 15 (B)Nítorí ó wí fún Mose pé,

“Èmi ó ṣàánú fún ẹni tí èmi yóò ṣàánú fún,
    èmi yóò sì ṣe ìyọ́nú fún ẹni tí èmi yóò ṣe ìyọ́nú fún.”

16 Ǹjẹ́ bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ti ẹni tí ó fẹ́, kì í sì í ṣe ti ẹni tí ń sáré, bí kò ṣe ti Ọlọ́run tí ń ṣàánú. 17 (C)Nítorí ìwé mímọ́ wí fún Farao pé, “Nítorí èyí náà ni mo ṣe gbé ọ dìde, kí èmi kí ó le fi agbára mi hàn lára rẹ, àti kí a bá à le máa ròyìn orúkọ mi ká gbogbo ayé.” 18 (D)Nítorí náà ni ó ṣe ń ṣàánú fún ẹni tí ó wù ú, ẹni tí ó wù ú a sì mú ní ọkàn le.

19 Ìwọ ó sì wí fún mi pé, “Kín ni ó ha tún bá ni wí sí? Nítorí ta ni ó ń de ìfẹ́ rẹ lọ́nà?” 20 (E)Bẹ́ẹ̀ kọ́, ìwọ ènìyàn, tà ni ìwọ tí ń dá Ọlọ́run lóhùn? “Ohun tí a mọ, a ha máa wí fún ẹni tí ó mọ ọ́n pé, ‘Èéṣe tí ìwọ fi mọ mi báyìí?’ ” 21 (F)Amọ̀kòkò kò ha ni agbára lórí amọ̀, nínú ìṣù kan náà láti ṣe apá kan nínú ohun èlò sí ọlá, àti apá kan nínú ohun èlò sí àìlọ́lá?

22 (G)Ǹjẹ́ bí Ọlọ́run bá fẹ́ fi ìbínú rẹ̀ hàn ńkọ́? Tí ó sì fẹ́ sọ agbára rẹ̀ di mí mọ̀, tí ó sì mú sùúrù púpọ̀ fún àwọn ohun èlò ìbínú tí a ṣe fún ìparun; 23 (H)Àti kí ó lè sọ ọ̀rọ̀ ògo rẹ̀ di mí mọ̀ lára àwọn ohun èlò àánú tí ó ti pèsè ṣáájú fún ògo, 24 (I)Àní àwa, tí ó ti pè, kì í ṣe nínú àwọn Júù nìkan, ṣùgbọ́n nínú àwọn Kèfèrí pẹ̀lú? 25 (J)Bí ó ti wí pẹ̀lú ní Hosea pé,

“Èmi ó pe àwọn tí kì í ṣe ènìyàn mi, ní ènìyàn mi,
    àti ẹni tí kí í ṣe àyànfẹ́ ní àyànfẹ́.”

26 (K)Yóò sì ṣe,

“Ní ibi ti a gbé ti sọ fún wọn pé,
    ‘ẹ̀yin kì í ṣe ènìyàn mi,’
    níbẹ̀ ni a ó gbé pè wọ́n ní ‘ọmọ Ọlọ́run alààyè.’ ”

27 (L)Isaiah sì kígbe nítorí Israẹli pé:

“Bí iye àwọn ọmọ Israẹli bá rí bí iyanrìn Òkun,
    apá kan ni ó gbàlà.
28 Nítorí Olúwa yóò mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ lórí ilẹ̀ ayé,
    yóò parí rẹ̀, yóò sì ké e kúrò ní òdodo.”

29 (M)Àti bí Isaiah ti wí tẹ́lẹ̀:

“Bí kò ṣe bí Olúwa àwọn Ọmọ-ogun
    ti fi irú-ọmọ sílẹ̀ fún wa,
àwa ìbá ti dàbí Sodomu,
    a bá sì ti sọ wá dàbí Gomorra.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.