Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Àlá Josẹfu
37 Jakọbu sì gbé ilẹ̀ Kenaani ní ibi ti baba rẹ̀ ti gbé.
2 Èyí ni àwọn ìtàn Jakọbu.
Nígbà tí Josẹfu di ọmọ ọdún mẹ́tà-dínlógún (17), ó ń ṣọ́ agbo ẹran pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀, àwọn ọmọ Biliha àti Silipa aya baba rẹ̀ Josẹfu sì ń ròyìn àwọn aburú tí wọ́n ń ṣe fún baba wọn.
3 Israẹli sì fẹ́ràn Josẹfu ju gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ tókù lọ, nítorí ní ọjọ́ ogbó rẹ̀ ni ó bí i. O sì dá aṣọ aláràbarà tí ó kún fún onírúurú ọnà lára fún un. 4 Nígbà tí àwọn arákùnrin rẹ̀ rí i pé baba àwọn fẹ́ràn rẹ̀ ju gbogbo wọn lọ, wọ́n kórìíra rẹ̀, wọ́n sì ń fi ẹ̀tanú bá a gbé, kò sì sí àlàáfíà láàrín wọn.
Àwọn arákùnrin Josẹfu tà á
12 Àwọn arákùnrin rẹ̀ sì da ẹran baba wọn lọ sí Ṣekemu. 13 Israẹli sì wí fún Josẹfu pé, “Ṣé o mọ̀ pé, àwọn arákùnrin rẹ ń da ẹran ní Ṣekemu, wá, jẹ́ kí n rán ọ sí wọn.”
Josẹfu sì dáhùn pé, “Èmi nìyí.”
14 O sì wí fún un pé, “Lọ wò bí àwọn arákùnrin rẹ àti àwọn agbo ẹran bá wà ní àlàáfíà, kí o sì wá jíṣẹ́ fún mi.” Ó sì rán Josẹfu lọ láti Àfonífojì Hebroni.
Nígbà tí Josẹfu dé Ṣekemu, 15 Ọkùnrin kan sì rí i tí ó ń rìn kiri inú pápá, ó sì bi í pé, “Kín ni ò ń wá?”
16 Ó sì dáhùn pé, “Àwọn arákùnrin mi ni mò ń wá, ǹjẹ́ o mọ ibi tí wọ́n wà pẹ̀lú agbo ẹran?”
17 Ọkùnrin náà dáhùn pé, “Wọ́n ti kúrò ní ìhín, mo gbọ́ tí wọ́n ń wí pé, ‘Ẹ jẹ́ kí a lọ sí Dotani.’ ”
Josẹfu sì wá àwọn arákùnrin rẹ̀ lọ, ó sì rí wọn ní tòsí Dotani. 18 Ṣùgbọ́n bí wọ́n sì ti rí i tí ń bọ̀ lókèèrè, kí ó sì tó dé ọ̀dọ̀ wọn, wọn gbìmọ̀ pọ̀ láti pa á.
19 “Alálàá ni ń bọ̀ yìí,” ni wọ́n ń wí fún ara wọn. 20 “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a pa á. Kí a sì ju òkú rẹ̀ sínú kòtò, a ó sì wí pé, ẹranko búburú ni ó pa á, kí a máa wo ọ̀nà tí àlá rẹ̀ yóò gbà ṣẹ.”
21 Nígbà tí Reubeni gbọ́ èyí, ó gbìyànjú láti gbà á sílẹ̀ ní ọwọ́ wọn, ó sì wí pé, “Ẹ má ṣe jẹ́ kí a gba ẹ̀mí rẹ̀, 22 Ẹ má ṣe jẹ́ kí a ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, ẹ má ṣe fọwọ́ kàn án, ẹ kúkú jù ú sínú kòtò láààyè nínú aginjù níbí.” Reubeni sọ èyí, kí ó ba à le gbà á kúrò lọ́wọ́ wọn, kí ó sì dá a padà lọ fún baba rẹ̀.
23 Nítorí náà, nígbà tí Josẹfu dé ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀, wọ́n bọ́ ẹ̀wù rẹ̀—Ẹ̀wù ọlọ́nà, aláràbarà tí ó wọ̀— 24 wọ́n mú un, wọ́n sì jù ú sínú kòtò. Kòtò náà sì ṣófo, kò sí omi nínú rẹ̀.
25 Bí wọ́n sì ti jókòó láti jẹun, wọ́n gbójú sókè, wọ́n sì rí àwọn oníṣòwò ará Iṣmaeli tí wọ́n ń wọ́ bọ̀ láti Gileadi. Ìbákasẹ wọn sì ru tùràrí, ìkunra àti òjìá, wọ́n ń lọ sí Ejibiti.
26 Juda wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé, “Èrè kí ni ó jẹ́ bí a bá pa arákùnrin wa tí a bo ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀ ti ọkàn wa sì ń dá wa lẹ́bi? 27 Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á tà á fún àwọn ará Iṣmaeli, kí àwa má sì pa á, ṣè bí àbúrò wa ni, ẹran-ara wa àti ẹ̀jẹ̀ wa ní i ṣe.” Àwọn arákùnrin rẹ̀ sì fi ara mọ́ ohun tí ó sọ.
28 (A)Nítorí náà, nígbà tí àwọn oníṣòwò ara Midiani ń kọjá, àwọn arákùnrin Josẹfu fà á jáde láti inú kòtò, wọ́n sì tà á fún àwọn ará Iṣmaeli ní ogún owó wúrà, wọ́n sì mú Josẹfu lọ sí ilẹ̀ Ejibiti.
105 (A)Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, ké pe orúkọ rẹ̀:
Jẹ́ kí a mọ ohun tí ó ṣe láàrín àwọn orílẹ̀-èdè;
2 Kọrin sí i, kọrin ìyìn sí i;
sọ ti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ gbogbo.
3 Ṣògo nínú orúkọ mímọ́ rẹ̀:
Jẹ́ kí ọkàn àwọn tí ń wá Olúwa kí ó yọ̀.
4 Wá Olúwa àti ipá rẹ̀;
wa ojú rẹ̀ nígbà gbogbo.
5 Rántí àwọn ìyanu tí ó ti ṣe,
ìyanu rẹ̀, àti ìdájọ́ tí ó sọ,
6 Ẹ̀yin ìran Abrahamu ìránṣẹ́ rẹ̀,
ẹ̀yin ọmọkùnrin Jakọbu, àyànfẹ́ rẹ̀.
16 Ó pe ìyàn sórí ilẹ̀ náà
ó sì pa gbogbo ìpèsè oúnjẹ wọn run;
17 Ó sì rán ọkùnrin kan síwájú wọn
Josẹfu tí a tà gẹ́gẹ́ bí ẹrú.
18 Wọn fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ bọ ẹsẹ̀ rẹ̀
a gbé ọrùn rẹ̀ sínú irin
19 Títí ọ̀rọ̀ tí ó sọtẹ́lẹ̀ fi ṣẹ
títí ọ̀rọ̀ Olúwa fi dá a láre.
20 Ọba ránṣẹ́ lọ tú u sílẹ̀
àwọn aláṣẹ ènìyàn tú u sílẹ̀
21 Ó fi jẹ olúwa lórí ilẹ̀ rẹ̀
aláṣẹ lórí ohun gbogbo tí ó ní,
22 Gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀, kí ó máa
ṣe àkóso àwọn ọmọ-aládé
kí ó sì kọ́ àwọn àgbàgbà rẹ̀ ní ọgbọ́n.
45 Kí wọn kí ó lè máa pa àṣẹ rẹ̀ mọ́
kí wọn kí ó lè kíyèsi òfin rẹ̀.
Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
5 (A)Mose ṣá kọ èyí nípa òdodo tí í ṣe ti òfin pé, “Ẹni tí ó ba ṣe, yóò yè nípa wọn.” 6 (B)Ṣùgbọ́n òdodo tí í ṣe ìgbàgbọ́ wí pé, “Má ṣe wí ni ọkàn rẹ̀ pé, ta ni yóò gòkè lọ si ọ̀run?” (èyí i ni ni, láti mú Kristi sọ̀kalẹ̀) 7 “tàbí, ta ni yóò sọ̀kalẹ̀ lọ si ọ̀gbun?” (èyí i ni ni, láti mú Kristi gòkè ti inú òkú wá). 8 (C)Ṣùgbọ́n kí ni ó wí? “Ọ̀rọ̀ náà wà létí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ní ẹnu rẹ̀, àti ní ọkàn rẹ̀,” èyí nì ni ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́, tí àwa ń wàásù; 9 (D)Pé, bí ìwọ bá fi ẹnu rẹ̀ jẹ́wọ́ “Jesu ní Olúwa,” tí ìwọ si gbàgbọ́ ní ọkàn rẹ pé, Ọlọ́run jí i dìde kúrò nínú òku, a ó gbà ọ́ là. 10 Nítorí ọkàn ni a fi ìgbàgbọ́ sí òdodo; ẹnu ni a sì ń fi ìjẹ́wọ́ sí ìgbàlà. 11 (E)Nítorí ìwé Mímọ́ wí pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà a gbọ́ ojú kò yóò tì í.” 12 (F)Nítorí kò si ìyàtọ̀ nínú Júù àti Helleni: nítorí Olúwa kan náà ni Olúwa gbogbo wọn, o si pọ̀ ni ọrọ̀ fún gbogbo àwọn ti ń ké pe e. 13 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá sá à ti pe orúkọ Olúwa ni a ó gbàlà.”
14 Ǹjẹ́ wọn ó ha ti ṣe ké pe ẹni tí wọn kò gbàgbọ́? Wọn ó ha sì ti ṣe gba ẹni tí wọn kò gbúròó rẹ̀ rí gbọ́? Wọn o ha sì ti ṣe gbọ́ láìsí oníwàásù? 15 (G)Wọ́n ó ha sì ti ṣe wàásù, bí kò ṣe pé a rán wọn? Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, “Ẹsẹ̀ àwọn tí ń wàásù ìhìnrere àlàáfíà ti dára tó, àwọn tí ń wàásù ìròyìn ayọ̀ ohun rere!”
Jesu rìn lójú omi
22 (A)Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ lẹ́yìn èyí, Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kí wọ́n bọ sínú ọkọ̀ wọn, àti kí wọ́n máa kọjá lọ ṣáájú rẹ̀ sí òdìkejì. Òun náà dúró lẹ́yìn láti tú àwọn ènìyàn ká lọ sí ilé wọn 23 Lẹ́yìn tí ó tú ìjọ ènìyàn ká tán, ó gun orí òkè lọ fúnrarẹ̀ láti lọ gba àdúrà. Nígbà tí ilẹ̀ ṣú, òun wà nìkan níbẹ̀, 24 (B)ní àkókò yìí ọkọ̀ ojú omi náà ti rin jìnnà sí etí bèbè Òkun, tí ìjì omi ń tì í síwá sẹ́yìn, nítorí ìjì ṣe ọwọ́ òdì sí wọn.
25 Ní déédé ago mẹ́rin òwúrọ̀, Jesu tọ̀ wọ́n wá, ó ń rìn lórí omi. 26 (C)Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rí i tí ó ń rìn lójú omi, ẹ̀rù ba wọn gidigidi, wọ́n rò pé “iwin ni” wọ́n kígbe tìbẹ̀rù tìbẹ̀rù.
27 Lójúkan náà, Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ mú ọkàn le! Èmi ni ẹ má ṣe bẹ̀rù.”
28 Peteru sì ké sí i pé, “Olúwa, bí ó bá jẹ́ pé ìwọ ni nítòótọ́, sọ pé kí n tọ̀ ọ́ wà lórí omi.”
29 (D)Jesu dá a lóhùn pé, “Ó dára, máa bọ̀ wá.”
Nígbà náà ni Peteru sọ̀kalẹ̀ láti inú ọkọ̀. Ó ń rìn lórí omi lọ sí ìhà ọ̀dọ̀ Jesu. 30 Nígbà tí ó rí afẹ́fẹ́ líle, ẹ̀rù bà á, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í rì. Ó kígbe lóhùn rara pé, “Gbà mí, Olúwa.”
31 (E)Lójúkan náà, Jesu na ọwọ́ rẹ̀, ó dìímú, ó sì gbà á. Ó sì wí fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ṣiyèméjì ìwọ onígbàgbọ́ kékeré?”
32 Àti pé, nígbà ti wọ́n sì gòkè sínú ọkọ̀, ìjì náà sì dúró jẹ́ẹ́. 33 (F)Nígbà náà ni àwọn to wà nínú ọkọ̀ náà foríbalẹ̀ fún un wọ́n wí pé, “Nítòótọ́ ọmọ Ọlọ́run ni ìwọ í ṣe.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.