Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
105 (A)Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, ké pe orúkọ rẹ̀:
Jẹ́ kí a mọ ohun tí ó ṣe láàrín àwọn orílẹ̀-èdè;
2 Kọrin sí i, kọrin ìyìn sí i;
sọ ti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ gbogbo.
3 Ṣògo nínú orúkọ mímọ́ rẹ̀:
Jẹ́ kí ọkàn àwọn tí ń wá Olúwa kí ó yọ̀.
4 Wá Olúwa àti ipá rẹ̀;
wa ojú rẹ̀ nígbà gbogbo.
5 Rántí àwọn ìyanu tí ó ti ṣe,
ìyanu rẹ̀, àti ìdájọ́ tí ó sọ,
6 Ẹ̀yin ìran Abrahamu ìránṣẹ́ rẹ̀,
ẹ̀yin ọmọkùnrin Jakọbu, àyànfẹ́ rẹ̀.
16 Ó pe ìyàn sórí ilẹ̀ náà
ó sì pa gbogbo ìpèsè oúnjẹ wọn run;
17 Ó sì rán ọkùnrin kan síwájú wọn
Josẹfu tí a tà gẹ́gẹ́ bí ẹrú.
18 Wọn fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ bọ ẹsẹ̀ rẹ̀
a gbé ọrùn rẹ̀ sínú irin
19 Títí ọ̀rọ̀ tí ó sọtẹ́lẹ̀ fi ṣẹ
títí ọ̀rọ̀ Olúwa fi dá a láre.
20 Ọba ránṣẹ́ lọ tú u sílẹ̀
àwọn aláṣẹ ènìyàn tú u sílẹ̀
21 Ó fi jẹ olúwa lórí ilẹ̀ rẹ̀
aláṣẹ lórí ohun gbogbo tí ó ní,
22 Gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀, kí ó máa
ṣe àkóso àwọn ọmọ-aládé
kí ó sì kọ́ àwọn àgbàgbà rẹ̀ ní ọgbọ́n.
45 Kí wọn kí ó lè máa pa àṣẹ rẹ̀ mọ́
kí wọn kí ó lè kíyèsi òfin rẹ̀.
Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
22 (A)Nígbà tí Israẹli sì ń gbé ní ibẹ̀, Reubeni wọlé tọ Biliha, àlè (ìyàwó tí a kò fi owó fẹ́ lọ́wọ́ àwọn òbí rẹ̀) baba rẹ̀ lọ, ó sì bá a lòpọ̀, Israẹli sì gbọ́ ọ̀rọ̀ náà.
Jakọbu sì bí ọmọkùnrin méjìlá:
23 Àwọn ọmọ Lea:
Reubeni tí í ṣe àkọ́bí Jakọbu,
Simeoni, Lefi, Juda, Isakari àti Sebuluni.
24 Àwọn ọmọ Rakeli:
Josẹfu àti Benjamini.
25 Àwọn ọmọ Biliha ìránṣẹ́bìnrin Rakeli:
Dani àti Naftali.
26 Àwọn ọmọ Silipa ìránṣẹ́bìnrin Lea:
Gadi àti Aṣeri.
Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ tí Jakọbu bí ní Padani-Aramu.
27 (B)Jakọbu sì padà dé ilé lọ́dọ̀ Isaaki baba rẹ̀ ni Mamre ní tòsí i Kiriati-Arba (Hebroni). Níbi tí Abrahamu àti Isaaki gbé. 28 Ẹni ọgọ́sàn-án (180) ọdún ni Isaaki. 29 Isaaki sì kú láìpẹ́ lẹ́yìn ìpadàbọ̀ Jakọbu, a sì sin ín pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀ ní ọjọ́ ogbó rẹ̀. Esau àti Jakọbu ọmọ rẹ̀ sì sin ín.
Ní Berea
10 Lọ́gán àwọn arákùnrin sì rán Paulu àti Sila lọ ṣí Berea lóru. Nígbà tí wọ́n sí dé ibẹ̀, wọ́n wọ inú Sinagọgu àwọn Júù lọ. 11 Àwọn Júù Berea sì ní ìyìn ju àwọn tí Tẹsalonika lọ, ní tí pé wọn fi tọkàntọkàn gbà ọ̀rọ̀ náà. Wọ́n sì ń wá inú ìwé mímọ́ lójoojúmọ́ bí nǹkan wọ̀nyí bá rí bẹ́ẹ̀. 12 Nítorí náà púpọ̀ nínú wọn gbàgbọ́; àti nínú àwọn obìnrin Giriki ọlọ́lá, àti nínú àwọn ọkùnrin ti kì í ṣe díẹ̀.
13 Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn Júù tí Tẹsalonika mọ̀ pé, Paulu ń wàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní Berea, wọ́n wá síbẹ̀ pẹ̀lú, wọ́n rú àwọn ènìyàn sókè. 14 Nígbà náà ni àwọn arákùnrin rán Paulu jáde lọ́gán láti lọ títí de etí Òkun: ṣùgbọ́n Sila àti Timotiu dúró ní Berea. 15 Àwọn tí ó sin Paulu wá sì mú un lọ títí dé Ateni; nígbà tí wọ́n sì gba àṣẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ wá fún Sila àti Timotiu pé, ki wọn ó yára tọ òun wá, wọ́n lọ.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.