Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Gẹnẹsisi 32:22-31

Jakọbu bá Ọlọ́run ja ìjàkadì

22 Ó sì dìde ní òru ọjọ́ náà, ó mú àwọn aya rẹ̀ méjèèjì, àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ méjèèjì, àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mọ́kọ̀ọ̀kànlá, wọ́n sì kọjá ní ìwọdò Jabbok. 23 Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti rán wọn kọjá odò tán sí òkè odò, ó sì rán àwọn ohun ìní rẹ̀ kọjá pẹ̀lú. 24 (A)Ó sì ku Jakọbu nìkan, ọkùnrin kan sì bá a ja ìjàkadì títí ó fi di àfẹ̀mọ́júmọ́. 25 Ṣùgbọ́n nígbà tí ọkùnrin náà rí i pé òun kò le borí Jakọbu, ó fọwọ́ kàn án ní ọ̀ọ́kán ibi tí eegun itan ti bẹ̀rẹ̀, egungun náà sì yẹ̀ kúrò lórí ike, bí ó ti ń ja ìjàkadì. 26 Nígbà náà ni ọkùnrin náà wí fún un pé, “Jẹ́ kí ń máa lọ, nítorí ojúmọ́ ti mọ́.”

Ṣùgbọ́n Jakọbu dá a lóhùn pé, “Èmi kò ní jẹ́ kí o lọ, àyàfi bí o bá súre fún mi.”

27 Ọkùnrin náà béèrè orúkọ rẹ̀.

Ó sì wí fún un pé, “Jakọbu ni òun ń jẹ́.”

28 (B)Nígbà náà ni ọkùnrin náà wí pé, “Orúkọ rẹ kì yóò jẹ́ Jakọbu mọ́ bí kò ṣe Israẹli, nítorí pé ìwọ ti bá Ọlọ́run àti ènìyàn jà, o sì borí.”

29 (C)Jakọbu sì bẹ ọkùnrin náà pé, “Sọ orúkọ rẹ fún mi.”

Ṣùgbọ́n ọkùnrin náà sá à dáhùn pé, “Èéṣe tí o ń béèrè orúkọ mi?” Lẹ́yìn náà ó súre fún Jakọbu níbẹ̀.

30 Jakọbu sì pe orúkọ ibẹ̀ ní Penieli pé, “Mo rí Ọlọ́run ní ojúkojú, síbẹ̀ a dá ẹ̀mí mi sí.”

31 Bí ó sì ti ń kọjá Penieli, oòrùn ràn bá a, ó sì ń tiro nítorí itan rẹ̀.

Saamu 17:1-7

Àdúrà ti Dafidi

17 Gbọ́, Olúwa, ẹ̀bẹ̀ òtítọ́ mi;
    fi etí sí igbe mi.
Tẹ́tí sí àdúrà mi
    tí kò ti ètè ẹ̀tàn jáde.
Kí ìdáláre mi wá láti ọ̀dọ̀ rẹ;
    kí ojú rẹ kí ó rí ohun tí ó tọ́.

Ìwọ ti dán àyà mi wò,
    ìwọ sì bẹ̀ mí wò ní òru, o sì ti wádìí mi,
ìwọ kì yóò rí ohunkóhun èmi ti pinnu pé,
    ẹnu mi kì yóò ṣẹ̀.
Bí ó ṣe ti iṣẹ́ ènìyàn nípa ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ,
    èmi ti pa ara mi mọ́
    kúrò ní ọ̀nà àwọn ìkà.
Ìrìn mí ti jẹ mọ́ ọ̀nà rẹ;
    ẹsẹ̀ mi kì yóò yọ̀.

Èmi ké pè ọ́, Ọlọ́run, nítorí tí ìwọ yóò dá mi lóhùn
    dẹ etí rẹ sí mi kí o sì gbọ́ àdúrà mi.
Fi ìṣeun ìyanu ìfẹ́ ńlá rẹ hàn
    ìwọ tí ó fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ gba àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ là
    lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá tí ó dìde sí wọn.

Saamu 17:15

15 Ṣùgbọ́n ní tèmi, èmi yóò máa wo ojú rẹ ní òdodo;
    nígbà tí èmi bá jí, èmi yóò ní ìtẹ́lọ́rùn nígbà tí èmi bá rí àwòrán rẹ.

Romu 9:1-5

Ọlọ́run yan Israẹli

Òtítọ́ ni èmi ń sọ nínú Kristi, èmi kò ṣèké, ọkàn mi sì ń jẹ́ mi ní ẹ̀rí nínú Ẹ̀mí Mímọ́. Pé mo ní ìbìnújẹ́ púpọ̀, àti ìkáàánú ìgbà gbogbo ni ọkàn mi. (A)Nítorí mo fẹ́rẹ lè gbàdúrà pé kí èmi tìkára mi kúrò lọ́dọ̀ Kristi nítorí àwọn ará mi, àwọn ìbátan mi nípa ti ara. (B)Àwọn ẹni tí i ṣe Israẹli; tí àwọn ẹni tí ìsọdọmọ í ṣe, àti ògo, àti májẹ̀mú, àti ìfúnilófin, àti ìsìn Ọlọ́run, àti àwọn ìlérí. Tí ẹni tí àwọn Baba í ṣe, àti láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹni tí Kristi ti wá nípa ti ara, ẹni tí ó borí ohun gbogbo, Ọlọ́run olùbùkún láéláé. Àmín.

Matiu 14:13-21

Jesu bọ́ ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ènìyàn

13 (A)Nígbà tí Jesu gbọ́ ìròyìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ó kúrò níbẹ̀, ó bá ọkọ̀ ojú omi lọ sí ibi kọ́lọ́fín kan ní èbúté láti dá wà níbẹ̀. Nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, ọ̀pọ̀ ènìyàn sì fi ẹsẹ̀ rìn tẹ̀lé e láti ọ̀pọ̀ ìlú wọn. 14 Nígbà ti Jesu gúnlẹ̀, tí ó sì rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, inú rẹ̀ yọ́ sí wọn, ó sì mú àwọn aláìsàn láradá.

15 Nígbà ti ilẹ̀ ń ṣú lọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọ́n sì wí pé, “Ibi yìí jìnnà sí ìlú ilẹ̀ sì ń ṣú lọ. Rán àwọn ènìyàn lọ sí àwọn ìletò kí wọ́n lè ra oúnjẹ jẹ.”

16 Ṣùgbọ́n Jesu fèsì pé, “Kò nílò kí wọ́n lọ kúrò. Ẹ fún wọn ní oúnjẹ.”

17 Wọ́n sì dalóhùn pé, “Àwa kò ní ju ìṣù àkàrà márùn-ún àti ẹja méjì lọ níhìn-ín.”

18 Ó wí pé, “Ẹ mú wọn wá fún mi níhìn-ín yìí.” 19 (B)Lẹ́yìn náà, ó wí fún àwọn ènìyàn kí wọ́n jókòó lórí koríko. Lẹ́yìn náà, ó mú ìṣù àkàrà márùn-ún àti ẹja méjì. Ó gbé ojú rẹ̀ sí ọ̀run. Ó béèrè ìbùkún Ọlọ́run lórí oúnjẹ náà, Ó sì bù ú, ó sì fi àkàrà náà fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn láti pín in fún àwọn ènìyàn. 20 Gbogbo wọn sì jẹ àjẹyó. Lẹ́yìn náà àwọn ọmọ-ẹ̀yìn kó àjẹkù jọ, ó kún agbọ̀n méjìlá. 21 Iye àwọn ènìyàn ni ọjọ́ náà jẹ́ ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (5,000) ọkùnrin, Láìka àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.