Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 139:1-12

Fún adarí orin. Ti Dafidi. Saamu.

139 Olúwa, ìwọ tí wádìí mi,
    ìwọ sì ti mọ̀ mí.
Ìwọ mọ̀ ìjókòó mi àti ìdìde mi,
    ìwọ mọ̀ èrò mi ní ọ̀nà jíjìn réré.
Ìwọ yí ipa ọ̀nà mi ká àti ìdùbúlẹ̀ mi,
    gbogbo ọ̀nà mi sì di mí mọ̀ fún ọ.
Nítorí tí kò sí ọ̀rọ̀ kan ní ahọ́n mi,
    kíyèsi i, Olúwa, ìwọ mọ̀ ọ́n pátápátá.
Ìwọ sé mi mọ́ lẹ́yìn àti níwájú,
    ìwọ sì fi ọwọ́ rẹ lé mi.
Irú ìmọ̀ yìí jẹ ohun ìyanu fún mi jù;
    ó ga, èmi kò le mọ̀ ọ́n.

Níbo ní èmi yóò gbé lọ kúrò ni ọwọ́ ẹ̀mí rẹ?
    Tàbí níbo ni èmi yóò sáré kúrò níwájú rẹ?
Bí èmi bá gòkè lọ sí ọ̀run, ìwọ wà níbẹ̀;
    bí èmí ba sì tẹ́ ẹní mi ní ipò òkú,
    kíyèsi i, ìwọ wà níbẹ̀ pẹ̀lú.
Èmi ìbá mú ìyẹ́ apá òwúrọ̀,
    kí èmi sì lọ jókòó ní ìhà òpin Òkun;
10 Àní, níbẹ̀ náà ni ọwọ́ rẹ̀ yóò fà mí
    ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò sì dì mímú.
11 Bí mo bá wí pé, “Ǹjẹ́ kí òkùnkùn kí ó bò mí mọ́lẹ̀;
    kí ìmọ́lẹ̀ kí ó di òru yí mi ká.”
12 Nítòótọ́ òkùnkùn kì í ṣú lọ́dọ̀ rẹ;
    ṣùgbọ́n òru tan ìmọ́lẹ̀ bí ọ̀sán;
    àti òkùnkùn àti ọ̀sán, méjèèjì bákan náà ní fún ọ.

Saamu 139:23-24

23 Ọlọ́run, wádìí mi, kí o sì mọ ọkàn mí;
    dán mi wò, kí o sì mọ ìrò inú mi
24 Kí ó sì wò ó bí ipa ọ̀nà búburú
    kan bá wà nínú mi kí ó sì
    fi ẹsẹ̀ mi lé ọ̀nà àìnípẹ̀kun.

Isaiah 44:1-5

Israẹli tí a yàn

44 “Ṣùgbọ́n gbọ́ nísinsin yìí, ìwọ Jakọbu ìránṣẹ́ mi
    àti Israẹli, ẹni tí mo ti yàn.
Ohun tí Olúwa wí nìyìí
    ẹni tí ó dá ọ, ẹni tí ó ti mọ̀ ọ́n
láti inú ìyá rẹ wá,
    àti ẹni tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ pẹ̀lú:
Má ṣe bẹ̀rù, ìwọ Jakọbu, ìránṣẹ́ mi,
    Jeṣuruni ẹni tí mo ti yàn.
Nítorí èmi yóò da omi sí ilẹ̀ tí ń pòǹgbẹ
    àti àwọn odò ní ilẹ̀ gbígbẹ;
Èmi yóò tú Ẹ̀mí mi sí ara àwọn ọmọ rẹ,
    àti ìbùkún mi sórí àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ.
Wọn yóò dàgbàsókè gẹ́gẹ́ bí i koríko nínú pápá oko tútù,
    àti gẹ́gẹ́ bí igi Poplari létí odò tí ń sàn.
Ọ̀kan yóò wí pé, ‘Èmi jẹ́ ti Olúwa’;
    òmíràn yóò pe ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí orúkọ Jakọbu;
bẹ́ẹ̀ ni òmíràn yóò kọ ọ́ sí ọwọ́ rẹ̀, ‘Ti Olúwa,’
    yóò sì máa jẹ́ orúkọ náà Israẹli.

Heberu 2:1-9

Ìkìlọ̀ láti ṣe ìgbọ́ràn

Nítorí náà, ó yẹ kí àwa máa fi iyè sí àwọn nǹkan wọ̀n-ọn-nì gidigidi tí àwa ti gbọ́, kí a má ba à gbá wa lọ kúrò nínú wọn nígbà kan. Nítorí bí ọ̀rọ̀ tí a tí ẹnu àwọn angẹli sọ bá sì dúró ṣinṣin, àti tí olúkúlùkù ẹ̀ṣẹ̀ sí òfin àti àìgbọ́ràn gba ìjìyà tí ó tọ́ sí i, kín ni ohun náà tí ó mú wa lérò pé a lè bọ́ kúrò nínú ìjìyà bí a kò bá náání ìgbàlà ńlá yìí? Ìgbàlà tí Olúwa fúnrarẹ̀ kọ́kọ́ kéde, èyí tí a sì fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ fún wa láti ọwọ́ àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà lẹ́nu rẹ̀. Ọlọ́run jẹ́rìí sí i nípa àwọn iṣẹ́ ààmì àti ìyanu àti oríṣìíríṣìí iṣẹ́ agbára àti nípa ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ tí a pín gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀.

Jesu bí arákùnrin rẹ̀

Nítorí pé, kì í ṣe abẹ́ ìṣàkóso àwọn angẹli ni ó fi ayé tí ń bọ̀, tí àwa ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ sí. (A)Ṣùgbọ́n ibìkan wà tí ẹnìkan tí jẹ́rìí pé:

“Kí ni ènìyàn tí ìwọ fi ń ṣe ìrántí rẹ̀,
    tàbí ọmọ ènìyàn, tí ìwọ fi ń bẹ̀ ẹ́ wò?
Ìwọ dá a ní onírẹ̀lẹ̀ díẹ̀ ju àwọn angẹli lọ;
    ìwọ fi ògo àti ọlá de e ni adé,
    ìwọ sì fi í jẹ olórí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ:
    Ìwọ fi ohun gbogbo sábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.”

Ní ti fífi ohun gbogbo sábẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n àwa kò ì tí ì rí ohun kan tí ó kù tí kò sí ní abẹ́ àkóso rẹ̀. Síbẹ̀ nísinsin yìí àwa kò ì tí ì rí pé ó fi ohun gbogbo sábẹ́ ìṣàkóso rẹ̀ Ṣùgbọ́n àwa rí Jesu ẹni tí a rẹ̀ sílẹ̀ díẹ̀ ju àwọn angẹli lọ fún àkókò díẹ̀, àní Jesu, ẹni tí a fi ògo àti ọlá dé ní adé nítorí ìjìyà wa; kí ó lè tọ́ ikú wò fún olúkúlùkù ènìyàn nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.