Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Maskili ti Dafidi. Nígbà tí ó wà nínú ihò òkúta. Àdúrà.
142 Èmi kígbe sókè sí Olúwa;
Èmi gbé ohùn mi sókè sí Olúwa fún àánú.
2 Èmi tú àròyé mí sílẹ̀ níwájú rẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ní èmi fi iṣẹ́ mi hàn níwájú rẹ̀.
3 Nígbà tí ẹ̀mí mi ṣàárẹ̀ nínú mi,
ìwọ ni ẹni tí ó mọ ọ̀nà mi.
Ní ipa ọ̀nà tí èmi ń rìn
ènìyàn ti dẹ okùn fún mi ní ìkọ̀kọ̀
4 Wo ọwọ́ ọ̀tún mi kí ó sì rì i
kò sí ẹni tí ó ṣe àníyàn mi
èmi kò ní ààbò;
kò sí ẹni tí ó náání ọkàn mi.
5 Èmi kígbe sí ọ, Olúwa:
èmi wí pé, “ìwọ ni ààbò mi,
ìpín mi ní ilẹ̀ alààyè.”
6 Fi etí sí igbe mi,
nítorí tí èmi wà nínú àìnírètí
gbà mí lọ́wọ́ àwọn tí ń lépa mi,
nítorí wọ́n lágbára jù mí lọ
7 Mú ọkàn mi jáde kúrò nínú túbú,
kí èmi lè máa yin orúkọ rẹ.
Nígbà náà ni àwọn olódodo yóò yí mi káàkiri
nítorí ìwọ yóò fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ba mi ṣe.
15 “Nítorí ọjọ́ Olúwa súnmọ́ etílé
lórí gbogbo àwọn kèfèrí.
Bí ìwọ ti ṣe, bẹ́ẹ̀ ni a ó ṣe sí ìwọ náà;
ẹ̀san rẹ yóò sì yípadà sí orí ara rẹ.
16 Gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀ ṣe mu lórí òkè mímọ́ mi
bẹ́ẹ̀ ni gbogbo kèfèrí yóò máa mu títí
Wọn yóò mu wọn yóò sì mu àmutẹ́rùn
wọn yóò sì wà bí ẹni pé wọn kò wà rí
17 Ṣùgbọ́n ìgbàlà yóò wà lórí òkè Sioni
Wọn yóò sì jẹ́ mímọ́
àti ilé Jakọbu yóò sì ní ìní wọn
18 Ilé Jakọbu yóò sì jẹ́ iná
àti ilé Josẹfu ọwọ́ iná
ilé Esau yóò jẹ àgékù koríko
wọn yóò fi iná sí i,
wọn yóò jo run.
Kì yóò sí ẹni tí yóò kù ní ilé Esau.”
Nítorí Olúwa ti sọ̀rọ̀.
19 Àwọn ará gúúsù yóò ni òkè Esau,
àwọn ará ẹsẹ̀ òkè yóò ni
ilẹ̀ àwọn ará Filistini ní ìní.
Wọn yóò sì ni oko Efraimu àti Samaria;
Benjamini yóò ní Gileadi ní ìní.
20 Àwọn ìgbèkùn Israẹli tí ó wà ní Kenaani
yóò ni ilẹ̀ títí dé Sarefati;
àwọn ìgbèkùn láti Jerusalẹmu tí ó wà ní Sefaredi
yóò ni àwọn ìlú gúúsù ní ìní
21 Àwọn tó ń gba ni là yóò sì gòkè Sioni wá
láti jẹ ọba lé orí àwọn òkè Esau.
Ìjọba náà yóò sì jẹ́ ti Olúwa.
10 (A)Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọ́n bí i pé, “Èéṣe tí ìwọ ń fi òwe bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀?”
11 Ó sì da wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin ni a ti fi fún láti mọ ohun ìjìnlẹ̀ ìjọba ọ̀run, ṣùgbọ́n kì í ṣe fún wọn. 12 Ẹnikẹ́ni tí ó ní, òun ni a ó fún sí i, yóò sì ní lọ́pọ̀lọpọ̀. Ṣùgbọ́n lọ́wọ́ ẹni tí kò ní, ni a ó ti gbà èyí kékeré tí ó ní náà. 13 Ìdí nìyìí tí mo fi ń fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀:
“Ní ti rí rí, wọn kò rí;
ní ti gbígbọ́ wọn kò gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò sì yé wọn.
14 (B)Sí ara wọn ni a ti mú àsọtẹ́lẹ̀ wòlíì Isaiah ṣẹ:
“ ‘Ní gbígbọ́ ẹ̀yin yóò gbọ́ ṣùgbọ́n kì yóò sì yé yín;
ní rí rí ẹ̀yin yóò rí, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kì yóò sì mòye.
15 Nítorí àyà àwọn ènìyàn yìí sébọ́
etí wọn sì wúwo láti gbọ́
ojú wọn ni wọ́n sì dì
nítorí kí àwọn má ba à fi ojú wọn rí
kí wọ́n má ba à fi etí wọn gbọ́
kí wọn má ba à fi àyà wọn mọ̀ òye,
kí wọn má ba à yípadà, kí èmi ba à le mú wọn láradá.’
16 (C)Ṣùgbọ́n ìbùkún ni fún ojú yín, nítorí wọ́n ríran, àti fún etí yín, nítorí ti wọ́n gbọ́. 17 Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ọ̀pọ̀ àwọn wòlíì àti ènìyàn Ọlọ́run ti fẹ́ rí ohun tí ẹ̀yin ti rí, ki wọ́n sì gbọ́ ohun tí ẹ ti gbọ́, ṣùgbọ́n kò ṣe é ṣe fún wọn.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.