Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
8 Gbọ́ ohùn olùfẹ́ mi!
Wò ó! Ibí yìí ni ó ń bọ̀.
Òun ń fò lórí àwọn òkè ńlá,
Òun bẹ́ lórí àwọn òkè kéékèèkéé
9 Olùfẹ́ mi dàbí abo egbin tàbí ọmọ àgbọ̀nrín
Wò ó! Níbẹ̀ ni ó wà lẹ́yìn ògiri wa
Ó yọjú ní ojú fèrèsé
Ó ń fi ara rẹ̀ hàn lójú fèrèsé ọlọ́nà
10 Olùfẹ́ mi fọhùn ó sì sọ fún mi pé,
“Dìde, Olólùfẹ́ mi,
arẹwà mi, kí o sì wà pẹ̀lú mi.
11 Wò ó! Ìgbà òtútù ti kọjá;
òjò ti rọ̀ dawọ́, ó sì ti lọ.
12 Àwọn òdòdó fi ara hàn lórí ilẹ̀
àsìkò ìkọrin àwọn ẹyẹ dé
a sì gbọ́ ohùn àdàbà ní ilẹ̀ wa.
13 Igi ọ̀pọ̀tọ́ mú èso tuntun jáde,
àwọn àjàrà nípa ìtànná wọ́n fún ni ní òórùn dídùn,
Dìde, wá, Olólùfẹ́ mi;
Arẹwà mi nìkan ṣoṣo, wá pẹ̀lú mi.”
30 Bí Isaaki ti súre tán tí Jakọbu ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde kúrò ní ọ̀dọ̀ baba rẹ̀ ni Esau ti oko ọdẹ dé. 31 Òun pẹ̀lú ṣe ẹran dídùn, ó sì gbé e tọ baba rẹ̀ wá, ó sì wí fún un pé, “Baba mi, dìde jókòó, kí o sì jẹ nínú ẹran igbó tí mo ti ṣè, kí o sì súre fún mi.”
32 Isaaki baba rẹ̀ sì bi í wí pé, “Ìwọ ta ni?”
Ó sì dáhùn pé “Èmi Esau, àkọ́bí rẹ ni.”
33 Nígbà náà ni Isaaki wárìrì gidigidi, ó sì wí pé, “Ta ni ẹni náà, tí ó ti pa ẹran igbó tí ó sì ti gbe wá fún mi, tí mo sì ti jẹ ẹ́ kí ó tó dé? Mo sì ti súre fún un, sì wò ó dájúdájú a ó sì bùkún un!”
34 Nígbà tí Esau gbọ́ ọ̀rọ̀ baba rẹ̀, ó ké, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní sọkún kíkorò, ó sì wí fún baba rẹ̀ pé, “Baba mi súre fún èmi náà, àní fún èmi náà pẹ̀lú.”
35 Ṣùgbọ́n Isaaki wí pé, “Àbúrò rẹ ti fi ẹ̀tàn wá, ó sì ti gba ìbùkún rẹ lọ.”
36 (A)Esau sì wí pé, “Lásán ni a pe orúkọ rẹ̀ ní Jakọbu (Arẹ́nijẹ) bí? Ní ìgbà méjì yìí ni ó ti tàn mí jẹ: ní àkọ́kọ́, ó gba ogún ìbí mi, nísinsin yìí, ó tún gba ìbùkún mi! Háà! Baba mi, ṣe o kò wá fi ìre kankan sílẹ̀ fun mi ni?”
37 Isaaki sì dá Esau lóhùn pé, “Mo ti fi ṣe olórí rẹ àti àwọn ìbátan rẹ ni mo fi ṣe ìránṣẹ́ fún un, àti ọkà àti wáìnì ni mo ti fi lé e lọ́wọ́ lọ́pọ̀lọpọ̀, kí ni ó tún kù tí ǹ bá tún fún ọ báyìí ọmọ mi?”
38 Esau sì wí fún baba rẹ̀ pé, “Ṣe ìre kan ṣoṣo ni ìwọ ní lẹ́nu ni baba mi? Súre fún èmi náà, baba mi.” Esau sì sọkún kíkankíkan.
39 Isaaki baba rẹ̀ sì dá a lóhùn pé,
“Ibùjókòó rẹ
yóò jìnnà sí ọ̀rá ilẹ̀,
àti sí ibi ìrì ọ̀run láti òkè wá.
40 Nípa idà rẹ ni ìwọ yóò máa gbé,
ìwọ yóò sì máa sin àbúrò rẹ,
ṣùgbọ́n ní ìkẹyìn, nígbà tí ìwọ bá di alágbára
ìwọ yóò já àjàgà rẹ̀
kúrò lọ́rùn rẹ.”
Jakọbu sálọ sí ọ̀dọ̀ Labani
41 Esau sì kórìíra Jakọbu nítorí ìre tí baba rẹ̀ sú fún un, ó sì wí fún ara rẹ̀ pé, “Baba mi sá à ti fẹ́rẹ kú, nígbà náà ni èmi ó pa Jakọbu, arákùnrin mi.”
42 Nígbà tí Rebeka sì gbọ́ ohun tí Esau àkọ́bí rẹ̀ wí, ó sì ránṣẹ́ sí Jakọbu, ó sì wí fun un pé, “Esau ẹ̀gbọ́n rẹ ń tu ara rẹ̀ nínú pẹ̀lú èrò à ti pa ọ́. 43 Nítorí náà ọmọ mi, ṣe ohun tí èmi yóò sọ fún ọ: Sálọ sọ́dọ̀ Labani ẹ̀gbọ́n mi ní Harani. 44 Jókòó sí ibẹ̀ títí di ìgbà tí ìbínú ẹ̀gbọ́n rẹ yóò fi rọ̀. 45 Nígbà tí ẹ̀gbọ́n rẹ kò bá bínú sí ọ mọ́, tí ó sì ti gbàgbé ohun tí ìwọ ṣe sí i, èmí ó ránṣẹ́ sí ọ láti padà wá. Èéṣe tí èmi ó fi pàdánù ẹ̀yin méjèèjì ní ọjọ́ kan náà?”
46 Nígbà náà ni Rebeka wí fún Isaaki pé, “Ayé sì sú mi nítorí àwọn ọmọbìnrin Hiti wọ̀nyí. Bí Jakọbu bá fẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọbìnrin Hiti wọ̀nyí, ó kúkú sàn kí n má wà láààyè.”
Ìbínú Ọlọ́run sí orílẹ̀ ayé
18 (A)Ṣùgbọ́n Ọlọ́run fi ìbínú rẹ̀ hàn láti ọ̀run wá sí gbogbo àìwà-bí-Ọlọ́run àti gbogbo àìṣòdodo ènìyàn, àwọn tí ń fi ìwà búburú dènà ìmọ̀ òtítọ́ lọ́dọ̀ ènìyàn. 19 Nítorí pé, nǹkan gbogbo tí a lè mọ nípa Ọlọ́run ni a ti fihàn fún wọn, nítorí Ọlọ́run ti fi í hàn fún wọn. 20 (B)Nítorí pé láti ìgbà dídá ayé, gbogbo ohun àìlèfojúrí rẹ̀: bí agbára ayérayé àti ìwà-bí-Ọlọ́run rẹ̀ ni a rí gbangba tí a sì ń fi òye ohun tí a dá mọ̀ ọ́n kí ènìyàn má ba à wá àwáwí.
21 (C)Lóòótọ́, wọn ní òye nípa Ọlọ́run dáradára, ṣùgbọ́n wọn kò yìn ín lógo bí Ọlọ́run, wọ́n kò sí dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀; wọ́n ń ro èrò asán, ọkàn aṣiwèrè wọn sì ṣókùnkùn. 22 Níwọ́n bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé wọ́n pe ara wọn ní ọlọ́gbọ́n ṣùgbọ́n wọ́n di òmùgọ̀ pátápátá, 23 (D)wọ́n sì yí ògo Ọlọ́run tí kì í díbàjẹ́ sí àwọn àwòrán ère bí i ti ènìyàn tí í díbàjẹ́ àti ti ẹyẹ, àti ti ẹranko ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́rin àti ti ẹranko afàyàfà.
24 Nítorí náà Ọlọ́run fà wọ́n lé ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn wọn lọ́wọ́ láti máa ṣe ohun ìríra pẹ̀lú ara wọn èyí tí kò tọ́. 25 Wọ́n yí òtítọ́ Ọlọ́run sí èké, wọ́n sì ń foríbalẹ̀ láti máa sin ẹ̀dá dípò ẹlẹ́dàá—ẹni tí ìyìn tọ́ sí láéláé. Àmín.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.