); Isaiah 51:1-3 (Look to Abraham and Sarah); Matthew 11:20-24 (Jesus prophesies against the cities) (Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn)
Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu.
47 Ẹ pàtẹ́wọ́, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn
ẹ hó sí Ọlọ́run pẹ̀lú orin ayọ̀ tó rinlẹ̀.
2 Báwo ni Olúwa Ọ̀gá-ògo ti ní ẹ̀rù tó
ọba ńlá lórí gbogbo ayé.
3 Ṣe ìkápá àwọn orílẹ̀-èdè lábẹ́ wa
àwọn ènìyàn lábẹ́ ẹsẹ̀ wa
4 Ó mú ilẹ̀ ìní wa fún wa
ọlá Jakọbu, ẹni tí ó fẹ́ wa.
5 Ọlọ́run tó gòkè lọ tí òun tayọ̀,
Olúwa ti òun ti ariwo ìpè.
6 Ẹ kọrin ìyìn sí Ọlọ́run, ẹ kọrin ìyìn.
Ẹ kọrin ìyìn sí ọba wa, ẹ kọrin ìyìn!
7 Nítorí Ọlọ́run ni ọba gbogbo ayé,
ẹ kọrin ìyìn pẹ̀lú Saamu!
8 Ọlọ́run jẹ ọba lórí gbogbo kèfèrí;
Ọlọ́run jókòó lórí ìtẹ́ ìwà mímọ́ rẹ̀.
9 Àwọn aládé ayé kó ara wọn jọ
gẹ́gẹ́ bí ènìyàn Ọlọ́run Abrahamu
nítorí asà ayé ti Ọlọ́run ni,
òun ni ó ga jùlọ.
Ìgbàlà ayérayé fún Sioni
51 “Tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin tí ó ń lépa òdodo
àti ẹ̀yin tí ń wá Olúwa:
Wo àpáta, nínú èyí tí a ti gé yín jáde
àti ihò òkúta níbi tí a ti gbẹ́ yín jáde;
2 ẹ wo Abrahamu baba yín,
àti Sara, ẹni tó bí i yín.
Nígbà tí mo pè é, òun nìkan ni,
Èmi sì bùkún un, mo sì ṣọ́ ọ di ọ̀pọ̀lọpọ̀.
3 Dájúdájú, Olúwa yóò tu Sioni nínú
yóò sì bojú àánú wo gbogbo ahoro rẹ̀;
Òun yóò sọ gbogbo aṣálẹ̀ rẹ̀ di Edeni,
àti aṣálẹ̀ rẹ̀ yóò rí bí ọgbà Olúwa.
Ayọ̀ àti inú dídùn ni a ó rí nínú rẹ̀,
ọpẹ́ àti ariwo orín kíkọ.
Ègbé ni fún àwọn ìlú tí kò ronúpìwàdà
20 (A)Nígbà náà ni Jesu bẹ̀rẹ̀ sí í bá ìlú tí ó ti ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ wí, nítorí wọn kò ronúpìwàdà. 21 Ó wí pé, “Ègbé ni fún ìwọ Koraṣini, ègbé ni fún ìwọ Betisaida! Ìbá ṣe pé a ti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu tí a ṣe nínú yín ní a ṣe ni Tire àti Sidoni, àwọn ènìyàn wọn ìbá ti ronúpìwàdà ti pẹ́ nínú aṣọ ọ̀fọ̀ àti eérú. 22 Ṣùgbọ́n mo wí fún yín, yóò sàn fún Tire àti Sidoni ní ọjọ́ ìdájọ́ jù fún yín. 23 Àti ìwọ Kapernaumu, a ó ha gbé ọ ga sókè ọ̀run? Rárá, a ó rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ sí ipò òkú. Nítorí, ìbá ṣe pé a ti ṣe iṣẹ́ ìyanu tí a ṣe nínú rẹ ní Sodomu, òun ìbá wà títí di òní. 24 Lóòótọ́ yóò sàn fún ilẹ̀ Sodomu ní ọjọ́ ìdájọ́ jù fún ìwọ lọ.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.