Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 13

Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.

13 Yóò ti pẹ́ tó, Olúwa? Ìwọ o ha gbàgbé mi títí láé?
    Yóò tí pẹ́ tó tí ìwọ yóò máa fi ojú rẹ pamọ́ fún mi?
Yóò ti pẹ́ tó tí èmi ó máa bá èrò mi jà,
    àti ní ojoojúmọ́ ni èmi ń ní ìbànújẹ́ ní ọkàn mi?
    Yóò ti pẹ́ tó tí àwọn ọ̀tá mi yóò máa borí mi?

Wò mí kí o sì dá mi lóhùn, Olúwa Ọlọ́run mi.
    Fi ìmọ́lẹ̀ fún ojú mi, kí èmi ó má sún oorun ikú;
Ọ̀tá mi wí pé, “Èmi ti ṣẹ́gun rẹ̀,”
    àwọn ọ̀tá mi yóò yọ̀ tí mo bá ṣubú.

Ṣùgbọ́n mo gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà;
    ọkàn mi ń yọ̀ nínú ìgbàlà rẹ.
Èmi ó máa kọrin sí Olúwa,
    nítorí ó dára sí mi.

2 Kronika 20:5-12

Nígbà náà Jehoṣafati dìde dúró níwájú àpéjọ Juda àti Jerusalẹmu ní ilé Olúwa níwájú àgbàlá tuntun. O sì wí pé:

Olúwa, Ọlọ́run àwọn baba wa, ìwọ kì ha ṣe Ọlọ́run tí ń bẹ ní ọ̀run? Ìwọ ń ṣe alákòóso lórí gbogbo ìjọba àwọn orílẹ̀-èdè. Agbára àti ipá ń bẹ ní ọwọ́ rẹ, kò sì sí ẹnìkan tí ó lè kò ọ́ lójú. (A)Ìwọ ha kọ́ Ọlọ́run wa, tí o ti lé àwọn olùgbé ilẹ̀ yìí jáde níwájú àwọn ènìyàn Israẹli, tí o sì fi fún irú-ọmọ Abrahamu ọ̀rẹ́ rẹ láéláé? Wọ́n ti ń gbé nínú rẹ̀ wọ́n sì ti kọ́ sínú rẹ ibi mímọ́ fún orúkọ rẹ wí pé, ‘Tí ibi bá wá sí orí wa, bóyá idà ìjìyà tàbí àjàkálẹ̀-ààrùn àwọn yóò dúró níwájú rẹ níwájú ilé yìí tí ń jẹ́ orúkọ rẹ, àwa yóò sì sọkún jáde, ìwọ yóò sì gbọ́ wa. Ìwọ yóò sì gbà wá là?’

10 “Ṣùgbọ́n nísinsin yìí àwọn ọkùnrin nìyí láti Ammoni, Moabu àti òkè Seiri, agbègbè ibi ti ìwọ kò ti gba àwọn ọmọ Israẹli láyè láti gbóguntì nígbà tí wọn wá láti Ejibiti; Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n yípadà kúrò ní ọ̀dọ̀ wọn, wọn kò sì pa wọ́n run. 11 Sì kíyèsi i, bí wọ́n ti san án padà fún wa; láti wá lé wa jáde kúrò nínú ìní rẹ, tí ìwọ ti fi fún wa láti ní. 12 Ọlọ́run wa, ṣé ìwọ kò ní ṣe ìdájọ́ fún wọn? Nítorí àwa kò ní agbára láti dojúkọ àwọn ọ̀pọ̀ ogun ńlá yìí tí ń bọ̀ wá kó wa. Àwa kò mọ̀ ohun tó yẹ ká ṣe, ṣùgbọ́n ojú wa wà ní ọ̀dọ̀ rẹ.”

Galatia 5:7-12

Ẹ̀yin ti ń sáré dáradára. Ta ni dí yin lọ́wọ́ láti ṣe ìgbọ́ràn sí òtítọ́? Ìyípadà yìí kò ti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó pè yín wá. (A)Ìwúkàrà díẹ̀ ní í mú gbogbo ìyẹ̀fun wú. 10 Mo ní ìgbẹ́kẹ̀lé sí yín nínú Olúwa pé, ẹ̀yin kì yóò ní èrò ohun mìíràn; ṣùgbọ́n ẹni tí ń yọ yín lẹ́nu yóò ru ìdájọ́ tirẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ó wù kí ó jẹ́. 11 Ṣùgbọ́n, ará, bí èmi bá ń wàásù ìkọlà síbẹ̀, kín ni ìdí tí a fi ń ṣe inúnibíni sí mi síbẹ̀? Ǹjẹ́ ìkọ̀sẹ̀ àgbélébùú ti kúrò. 12 Èmi ìbá fẹ́ kí àwọn tí ń yọ yín lẹ́nu tilẹ̀ gé ẹ̀yà ara wọn kan kúrò.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.