Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
11 Kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ, Olúwa,
èmi ó sì máa rìn nínú òtítọ́ rẹ;
fún mi ní ọkàn tí kì í yapa,
kí èmi kí ó ba lè bẹ̀rù orúkọ rẹ.
12 Èmi ó yìn ọ́, Olúwa Ọlọ́run mi, pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi;
èmi ó fògo fún orúkọ rẹ títí láé
13 Nítorí títóbi ni ìfẹ́ rẹ si mi;
ìwọ ti gbà mí kúrò nínú ọ̀gbun isà òkú.
14 Àwọn onígbèéraga ń dojúkọ mí, Ọlọ́run;
àti ìjọ àwọn alágbára ń wá
ọkàn mi kiri,
wọn kò sì fi ọ́ pè.
15 Ṣùgbọ́n ìwọ, Olúwa, jẹ́ aláàánú àti Ọlọ́run olójúrere,
Ó lọ́ra láti bínú, Ó sì pọ̀ ní ìfẹ́ àti òtítọ́.
16 Yípadà sí mi kí o sì ṣàánú fún mi;
fún àwọn ènìyàn rẹ ní agbára
kí o sì gba ọ̀dọ́mọkùnrin ìránṣẹ́bìnrin rẹ là.
17 Fi ààmì hàn mí fún rere,
kí àwọn tí ó kórìíra mi lè ri,
kí ojú lè tì wọ́n, nítorí ìwọ Olúwa
ni ó ti tù mí nínú.
Àwọn ìran Iṣmaeli
12 Wọ̀nyí ni ìran Iṣmaeli, ọmọ Abrahamu ẹni tí Hagari ará Ejibiti, ọmọ ọ̀dọ̀ Sara bí fún un.
13 Wọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọ Iṣmaeli bí a ṣe bí wọn, bẹ̀rẹ̀ láti orí:
Nebaioti àkọ́bí,
Kedari, Adbeeli, Mibsamu,
14 Miṣima, Duma, Massa,
15 Hadadi, Tema, Jeturi,
Nafiṣi, àti Kedema.
16 Wọ̀nyí sì ni orúkọ àwọn ọmọ Iṣmaeli, wọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọba méjìlá gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà wọn.
17 Àpapọ̀ ọdún tí Iṣmaeli lò láyé jẹ́ ẹ̀tàdínlógóje (137) ọdún, a sì sin ín pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀. 18 Àwọn ìran rẹ̀ sì tẹ̀dó sí agbègbè Hafila títí tí ó fi dé Ṣuri, ní ẹ̀bá ààlà Ejibiti, bí ìwọ ti ń lọ sí ìhà Asiria. Ó sì kú níwájú àwọn arákùnrin rẹ̀ gbogbo.
Sí Ìjọ ní Smirna
8 (A)“Àti sí angẹli ìjọ ní Smirna kọ̀wé:
Nǹkan wọ̀nyí ni ẹni tí í ṣe ẹni ìṣáájú àti ẹni ìkẹyìn wí, ẹni tí ó ti kú, tí ó sì tún yè:
9 Èmi mọ iṣẹ́ rẹ, àti ìpọ́njú, àti àìní rẹ—ṣùgbọ́n ọlọ́rọ̀ ni ọ́, èmi sì mọ ọ̀rọ̀-òdì tí àwọn tí ń wí pé, Júù ni àwọn tìkára wọn, tí wọn kì sì í ṣe bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n tí wọ́n jẹ́ Sinagọgu ti Satani. 10 (B)Má ṣe bẹ̀rù ohunkóhun tí ìwọ ń bọ wá jìyà rẹ̀. Kíyèsi i, èṣù yóò gbé nínú yín jù sínú túbú, kí a lè dán yin wò; ẹ̀yin ó sì ní ìpọ́njú ní ọjọ́ mẹ́wàá: ìwọ ṣa ṣe olóòtítọ́ dé ojú ikú, èmi ó sì fi adé ìyè fún ọ.
11 Ẹni tí ó bá ní etí kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ. Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun kì yóò fi ara pa nínú ikú kejì.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.