Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Adúra ti Dafidi.
86 Gbọ́, Olúwa, kí o sì dá mi lóhùn,
nítorí mo jẹ́ tálákà àti aláìní.
2 Dáàbò bò ayé mi, nítorí a ti yà mí sọ́tọ̀ fún ọ:
ìwọ ni Ọlọ́run mi,
gbà ìránṣẹ́ rẹ là
tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ.
3 Ṣàánú fún mi, Olúwa,
nítorí èmi ń pè ọ́ ní gbogbo ọjọ́.
4 Mú ayọ̀ wà fún ìránṣẹ́ rẹ,
nítorí ìwọ, Olúwa,
ni mo gbé ọkàn mí sókè sí.
5 Ìwọ ń dáríjì, ìwọ sì dára, Olúwa,
ìwọ sì ṣàánú fún gbogbo àwọn tí ń ké pè ọ́,
6 Gbọ́ àdúrà mi, Olúwa;
tẹ́tí sí ẹkún mi fún àánú.
7 Ní ọjọ́ ìpọ́njú mi èmi yóò pè ọ́,
nítorí ìwọ yóò dá mi lóhùn.
8 Nínú àwọn òrìṣà kò sí ẹni tí ó dàbí i rẹ, Olúwa:
kò sí àwọn iṣẹ́ tí a lè fiwé tìrẹ.
9 Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ìwọ dá
yóò wá, láti wá jọ́sìn níwájú rẹ, Olúwa;
wọn ó mú ògo wà fún orúkọ rẹ̀.
10 Nítorí pé ìwọ tóbi, ìwọ sì ń ṣe ohun ìyanu;
ìwọ nìkan ni Ọlọ́run.
Jakọbu padà sí Beteli
35 (A)Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún Jakọbu pé, “Gòkè lọ sí Beteli kí o sì tẹ̀dó síbẹ̀, kí ó mọ pẹpẹ níbẹ̀ fún Ọlọ́run tó farahàn ọ́ nígbà tí o ń sálọ kúrò níwájú Esau arákùnrin rẹ.”
2 Nítorí náà, Jakọbu wí fún gbogbo ará ilé rẹ̀ pé, “Ẹ mú gbogbo àjèjì òrìṣà tí ó wà lọ́dọ̀ yín kúrò, kí ẹ ya ara yín sí mímọ́, kí ẹ sì pààrọ̀ aṣọ yín. 3 Nígbà náà ni kí ẹ wá, kí ẹ jẹ́ kí a lọ sí Beteli, níbi tí n ó ti mọ pẹpẹ fún Ọlọ́run, tí ó dá mi lóhùn ní ọjọ́ ìpọ́njú mi tí ó sì ti ń pẹ̀lú mi níbi gbogbo tí mo ń lọ.” 4 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n fún Jakọbu ní gbogbo àjèjì òrìṣà tí ó wà lọ́wọ́ wọn, àti yẹtí etí wọn, Jakọbu sì bo gbogbo wọn mọ́lẹ̀ sábẹ́ igi óákù ní Ṣekemu.
Wọ́n ṣe inúnibíni sí àwọn aposteli
17 Nígbà náà ni ẹ̀mí owú gbígbóná gbé olórí àlùfáà àti gbogbo àwọn tí wọn wà lọ́dọ̀ rẹ̀ tí ì ṣe ẹ̀yà tí àwọn Sadusi wọ̀. 18 Wọ́n sì nawọ́ mú àwọn aposteli wọn sì fi wọ́n sínú túbú. 19 Ṣùgbọ́n ní òru, angẹli Olúwa ṣí ìlẹ̀kùn túbú; ó sì mú wọn jáde. 20 Ó sì wí pé “Ẹ lọ dúró nínú tẹmpili kí ẹ sì máa ṣọ́ ọ̀rọ̀ ìyè yìí ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ fún àwọn ènìyàn.”
21 Nígbà tí wọ́n sì gbọ́ èyí, wọ́n wọ tẹmpili lọ ní kùtùkùtù, wọ́n sì ń kọ́ni.
Nígbà tí olórí àlùfáà àti àwọn ti ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ dé, wọn sì pè àpéjọ ìgbìmọ̀, àti gbogbo àwọn àgbàgbà àwọn ọmọ Israẹli, wọn sì ránṣẹ́ sí ilé túbú láti mú àwọn aposteli wá. 22 Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn olùṣọ́ dé ibẹ̀ wọn kò sì rí wọn nínú túbú, wọn padà wá, wọn sísọ fún wọn pé, 23 “Àwa bá ilé túbú ni títí pinpin, àti àwọn olùṣọ́ dúró lóde níwájú ìlẹ̀kùn; ṣùgbọ́n nígbà tí àwa ṣí ìlẹ̀kùn, àwa kò bá ẹnìkan nínú túbú.” 24 Nígbà tí olórí ẹ̀ṣọ́ tẹmpili àti àwọn olórí àlùfáà sí gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, wọ́n dààmú nítorí wọn kò mọ ibi tí ọ̀rọ̀ yìí yóò yọrí sí.
25 Nígbà náà ni ẹnìkan dé, ó wí fún wọn pé, “Wò ó, àwọn ọkùnrin tí ẹ̀yin fi sínú túbú wà ní tẹmpili, wọn dúró wọ́n sì ń kọ́ àwọn ènìyàn.” 26 Nígbà náà ni olórí ẹ̀ṣọ́ lọ pẹ̀lú àwọn olùṣọ́, ó sì mú àwọn aposteli wá. Wọn kò fi ipá mú wọn, nítorí tí wọn bẹ̀rù àwọn ènìyàn kí a má ba à sọ wọ́n ní òkúta.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.