Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 116:1-2

116 Èmi fẹ́ràn Olúwa, nítorí ó gbọ́ ohùn mi;
    ó gbọ́ ẹkún mi fún àánú.
Nítorí ó yí etí rẹ̀ padà sí mi,
    èmi yóò máa pè é ni wọ́n ìgbà tí mo wà láààyè.

Saamu 116:12-19

12 Kí ni èmi yóò san fún Olúwa
    nítorí gbogbo rere rẹ̀ sí mi?

13 Èmi yóò gbé ago ìgbàlà sókè
    èmi yóò sì máa ké pe orúkọ Olúwa.
14 Èmi yóò mú ìlérí mi ṣẹ sí Olúwa
    ní ojú àwọn ènìyàn rẹ̀.

15 Iyebíye ní ojú Olúwa
    àti ikú àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀.
16 Olúwa, nítòótọ́ ìránṣẹ́ rẹ ni mo jẹ́;
    èmi ni ìránṣẹ́ rẹ, ọmọ ìránṣẹ́bìnrin rẹ;
    ó ti tú mi sílẹ̀ nínú ìdè mi.

17 Èmi yóò rú ẹbọ ọpẹ́ sí ọ
    èmi yóò sì ké pe orúkọ Olúwa
18 Èmi yóò mú ìlérí mi sẹ sí Olúwa
    ní ojú gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀,
19 Nínú àgbàlá ilé Olúwa
    ní àárín rẹ̀, ìwọ Jerusalẹmu.

Ẹ yin Olúwa.

Gẹnẹsisi 24:1-9

Isaaki àti Rebeka

24 Abrahamu sì ti di arúgbó ní àkókò yìí, Olúwa sì ti bùkún fún un ni gbogbo ọ̀nà, Abrahamu wí fún olórí àwọn ìránṣẹ́ ilẹ̀ rẹ̀, tí ó jẹ́ alábojútó ohun gbogbo tí ó ní pé, “Fi ọwọ́ rẹ sí abẹ́ itan mi. Èmi yóò mú ọ búra lórúkọ Olúwa Ọlọ́run ọ̀run àti ayé, pé, ìwọ kì yóò fẹ́ aya fún ọmọ mi nínú àwọn ọmọbìnrin ará Kenaani, láàrín àwọn ẹni tí èmi ń gbé. Ṣùgbọ́n, ìwọ yóò lọ sí orílẹ̀-èdè mi, láàrín àwọn ará mi láti fẹ́ aya fún Isaaki, ọmọ mi.”

Ìránṣẹ́ náà bi í wí pé, “Ǹjẹ́ bí ọmọbìnrin náà bá kọ̀ láti bá mi wá sí ilẹ̀ yìí ńkọ́? Ǹjẹ́ mo lè mú ọmọ rẹ padà lọ sí orílẹ̀-èdè níbi tí ìwọ ti wá?”

Abrahamu sì wí fún un pé, “Rí i dájú pé ìwọ kò mú ọmọ mi padà lọ sí ibẹ̀.” Olúwa, Ọlọ́run ọ̀run tí ó mú mi jáde láti ilẹ̀ baba mi àti ní ilẹ̀ tí a bí mi, tí ó bá mi sọ̀rọ̀ tí ó sì búra fún mi pé, ‘Irú-ọmọ rẹ ni n ó fi ilẹ̀ yìí fún,’ yóò rán angẹli rẹ̀ ṣáájú rẹ, kí ìwọ kí ó lè rí aya fẹ́ wá fún ọmọ mi láti ibẹ̀. Bí obìnrin náà kò bá fẹ́ tẹ̀lé ọ wá, nígbà náà ni a tú ọ sílẹ̀ kúrò nínú ìbúra yìí, ṣùgbọ́n pàtàkì ni pé ìwọ kò gbọdọ̀ mú ọmọ mi padà lọ sí ibẹ̀.” Ìránṣẹ́ náà sì fi ọwọ́ rẹ̀ sí abẹ́ itan Abrahamu olúwa rẹ̀, ó sì búra fún nítorí ọ̀rọ̀ náà.

Ìṣe àwọn Aposteli 7:35-43

35 (A)“Mose náà yìí tí wọ́n kọ̀, wí pé, ‘Ta ni ó fi jẹ olórí àti onídàájọ́?’ Òun náà ni Ọlọ́run rán lọ láti ọwọ́ angẹli, tí ó farahàn án ní pápá, láti ṣe olórí àti olùdáǹdè. 36 (B)Òun ni ó mú wọn jáde, lẹ́yìn ìgbà tí ó ṣe iṣẹ́ ìyanu àti iṣẹ́ ààmì ní ilẹ̀ Ejibiti, àti ni Òkun pupa, àti ni aginjù ní ogójì ọdún.

37 (C)“Èyí ni Mose náà ti ó wí fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Ọlọ́run yóò gbé wòlíì kan bí èmi dìde nínú àwọn ènìyàn yín.’ 38 (D)Èyí náà ni ẹni tí ó wà nínú ìjọ ní ijù pẹ̀lú angẹli náà tí ó bá a sọ̀rọ̀ ní orí òkè Sinai, àti pẹ̀lú àwọn baba wa; ẹni ti ó gba ọ̀rọ̀ ìyè láti fi fún wa.

39 (E)“Ṣùgbọ́n àwọn baba wa kò fẹ́ gbọ́ tirẹ̀. Dípò bẹ́ẹ̀, wọ́n kọ̀ ọ́ sílẹ̀, àti pé nínú ọkàn wọn, wọn fẹ́ yípadà lọ sí ilẹ̀ Ejibiti; 40 (F)Wọ́n wí fún Aaroni pé, ‘Dá òrìṣà fún wa tí yóò máa tọ́nà ṣáájú wa; nítorí bí ó ṣe ti Mose yìí tí ó mú wa jáde wá láti ilẹ̀ Ejibiti, a kò mọ̀ ohun tí ó ṣe é.’ 41 (G)Wọ́n sì yá ère ẹgbọrọ màlúù ni ọjọ́ wọ̀nyí. Wọ́n sì rú ẹbọ sí ère náà, wọ́n sì ń yọ̀ nínú ohun tí wọ́n fi ọwọ́ ara wọn ṣe. 42 Ọlọ́run sì padà, ó fi wọn sílẹ̀ láti máa sin ogun ọ̀run: òòrùn, òṣùpá àti ìràwọ̀. Èyí wà ní ìbámu pẹ̀lú bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé àwọn wòlíì pé:

“ ‘Ẹ̀yin ha mú ẹran tí a pa àti ẹbọ wa fún mi
    ní ogójì ọdún ní ijù bí, ìwọ ilé Israẹli?
43 Ẹ̀yin sì tẹ́wọ́gbà àgọ́ Moleki,
    àti ìràwọ̀ Refani òrìṣà yín,
    àwòrán tí ẹ̀yin ṣe láti máa bọ wọ́n.
Nítorí náà èmi yóò kó yín lọ sí ìgbèkùn rékọjá Babeli.’

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.