Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 29

Saamu ti Dafidi.

29 Ẹ fi fún Olúwa, ẹ̀yin ẹ̀dá ọ̀run,
    Ẹ fi fún Olúwa, ògo àti alágbára.
Fi fún Olúwa, àní ògo orúkọ rẹ̀;
    sin Olúwa nínú ẹwà ìwà mímọ́.

Ohùn Olúwa n ré àwọn omi kọjá;
    Ọlọ́run ògo sán àrá,
    Olúwa san ara.
Ohùn Olúwa ní agbára;
    ohùn Olúwa kún fún ọláńlá.
Ohùn Olúwa fa igi kedari;
    Olúwa náà ló fọ́ igi kedari Lebanoni ya.
Ó mú Lebanoni fo bí i ọmọ màlúù,
    àti Sirioni bí ọmọ àgbáǹréré.
Ohùn Olúwa ń ya
    bí ọwọ́ iná mọ̀nà
Ohùn Olúwa ń mi aginjù.
    Olúwa mi aginjù Kadeṣi.
Ohùn Olúwa ní ó lọ igi óákù, ó n mú abo àgbọ̀nrín bí,
    ó sì bọ́ igi igbó sí ìhòhò.
Àti nínú tẹmpili rẹ̀ gbogbo ohùn wí pé “Ògo!”

10 Olúwa jókòó, Ó sì jẹ ọba lórí ìṣàn omi;
    Olúwa jókòó lórí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba títí láéláé.
11 Olúwa fi agbára fún àwọn ènìyàn rẹ̀;
    bùkún àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú àlàáfíà.

Jobu 39:26-40:5

26 “Àwòdì ha máa ti ipa ọgbọ́n rẹ̀ fò sókè,
    tí ó sì na ìyẹ́ apá rẹ̀ sí ìhà gúúsù?
27 Idì ha máa fi àṣẹ rẹ̀ fò sókè,
    kí ó sì lọ tẹ́ ìtẹ́ rẹ̀ sí òkè gíga?
28 Ó ń gbé, ó sì ń wò ní orí àpáta,
    lórí pàlàpálá òkúta àti ibi orí òkè.
29 Láti ibẹ̀ lọ ni ó ti ń wá oúnjẹ kiri,
    ojú rẹ̀ sì ríran rí òkè réré.
30 Àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú a máa mu ẹ̀jẹ̀,
    níbi tí òkú bá gbé wà, níbẹ̀ ni òun wà pẹ̀lú.”

Jobu rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀

40 Olúwa dá Jobu lóhùn sí pẹ̀lú, ó sì wí pé:

“Ẹni tí ń bá Olódùmarè wíjọ́ yóò ha kọ ní ẹ̀kọ́?
    Ẹni tí ń bá Ọlọ́run wí jẹ́ kí ó dáhùn!”

Nígbà náà ni Jobu dá Olúwa lóhùn wá ó sì wí pé,

“Kíyèsi i, ẹ̀gbin ni èmi—ohun kí ni èmi ó dà?
    Èmi ó fi ọwọ́ mi le ẹnu mi.
Ẹ̀ẹ̀kan ní mo sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n èmi kì yóò tún sọ mọ́;
    lẹ́ẹ̀kejì ni, èmi kò sì le ṣe é mọ́.”

Johanu 14:25-26

25 “Nǹkan wọ̀nyí ni èmi ti sọ fún yín, nígbà tí mo ń bá yín gbé. 26 Ṣùgbọ́n Olùtùnú náà, Ẹ̀mí Mímọ́, ẹni tí Baba yóò rán ní orúkọ mi, òun ni yóò kọ́ yín ní ohun gbogbo, yóò sì rán yín létí ohun gbogbo tí mo ti sọ fún yín.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.