Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
24 Iṣẹ́ rẹ ti pọ̀ tó, Olúwa!
Nínú ọgbọ́n ni ìwọ ṣe gbogbo wọn:
ayé kún fún àwọn ìṣẹ̀dá á rẹ.
25 Bẹ́ẹ̀ ni Òkun yìí tí ó tóbi, tí ó sì ni ìbú,
tí ó kún fún àwọn ẹ̀dá alààyè ní ìsàlẹ̀ láìníye
ohun alààyè tí tóbi àti kékeré.
26 Níbẹ̀ ni ọkọ̀ ń lọ síwá sẹ́yìn,
àti Lefitani, tí ìwọ dá láti ṣe àríyá nínú rẹ̀.
27 Àwọn wọ̀nyí ń wò ọ́
láti fún wọn ní oúnjẹ wọn lákòókò rẹ̀.
28 Nígbà tí ìwọ bá fi fún wọn,
wọn yóò kó jọ;
nígbà tí ìwọ bá la ọwọ́ rẹ̀,
a tẹ́ wọn lọ́rùn pẹ̀lú ohun rere.
29 Nígbà tí ìwọ bá pa ojú rẹ mọ́
ara kò rọ̀ wọ́n
nígbà tí ìwọ bá mú ẹ̀mí wọn lọ,
wọn ó kú, wọn ó sì padà sí erùpẹ̀.
30 Nígbà tí ìwọ rán ẹ̀mí rẹ,
ni a dá wọn,
ìwọ sì tún ojú ayé ṣe.
31 Jẹ́ kí ògo Olúwa wà pẹ́ títí láé;
kí inú Olúwa kí ó dùn ní ti iṣẹ́ rẹ̀
32 Ẹni tí ó wo ayé, tí ó sì wárìrì,
ẹni tí ó fọwọ́ tọ́ àwọn òkè, tí wọ́n yọ èéfín.
33 Ní gbogbo ayé mi ní n ó kọrin sí Olúwa:
èmi ó kọrin ìyìn sí Olúwa
níwọ̀n ìgbà tí mo wà láààyè.
34 Jẹ́ kí ẹ̀kọ́ mi kí ó tẹ́ ọ lọ́rùn
bí mo ti ń yọ̀ nínú Olúwa.
35 Ṣùgbọ́n kí ẹlẹ́ṣẹ̀ kúrò láyé
kí ènìyàn búburú má sì sí mọ́.
Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi.
Yin Olúwa.
7 “ ‘Èmi yóò sọ orúkọ mímọ́ mí di mí mọ̀ láàrín àwọn ènìyàn mì Israẹli. Èmi ki yóò jẹ́ kí orúkọ mímọ́ mi di aláìmọ́ àwọn orílẹ̀-èdè yóò mọ̀ pé èmi Olúwa, èmi ni ẹni mímọ́ ní Israẹli. 8 Ó ń bọ̀! Ó dájú pé yóò ṣẹlẹ̀, ni Olúwa Olódùmarè. Èyí yìí ni ọjọ́ tí mo sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.
21 “Èmi yóò ṣe àfihàn ògo mi láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, gbogbo orílẹ̀-èdè yóò sì rí ìyà tí mo fi jẹ wọ́n. 22 Láti ọjọ́ náà lọ, ilé Israẹli yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa Ọlọ́run wọn. 23 Àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì mọ̀ pé àwọn ènìyàn Israẹli lọ sí ìgbèkùn nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, nítorí pé wọ́n jẹ́ aláìṣòótọ́ sí mi. Nítorí náà mo mú ojú mi pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ wọn, mo sì fi wọn lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́, gbogbo wọn sì ṣubú nípasẹ̀ idà. 24 Mo ṣe sí wọn gẹ́gẹ́ bí àìmọ́ àti àìṣedéédéé wọn, mo sì mú ojú mi pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ wọn.
25 “Nítorí náà èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Èmi yóò mú Jakọbu padà kúrò ní oko ẹrú, èmi yóò ní ìyọ́nú si gbogbo ènìyàn Israẹli, èmi yóò sì ní ìtara fún orúkọ mímọ́ mi. 26 Wọn yóò gbàgbé ìtìjú wọn àti gbogbo àìṣòdodo tí wọ́n fihàn sí mi nígbà tí wọn ń gbé ni àìléwu ni ilẹ̀ wọn níbi tí kò ti sí ẹnikẹ́ni láti dẹ́rùbà wọ́n. 27 Nígbà tí mo ti mú wọn padà kúrò ní àwọn orílẹ̀-èdè, tí mo sì kó wọn jọ pọ̀ kúrò ni ìlú àwọn ọ̀tá wọn, èmi yóò fi ara mi hàn ni mímọ́ nípasẹ̀ wọn ní ojú àwọn orílẹ̀-èdè púpọ̀. 28 Nígbà náà, wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa Ọlọ́run wọn nítorí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo rán wọn lọ sí ìgbèkùn láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, èmi yóò kó wọn jọ sí orí ilẹ̀ wọn, láìfi nǹkan kan sẹ́yìn. 29 Èmi kì yóò sì fi ojú mi pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ wọn mọ nítorí èmi yóò tú èémí mi jáde sí ilé Israẹli, ní Olúwa Olódùmarè wí.”
26 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ẹ̀mí pẹ̀lú sì ń ran àìlera wa lọ́wọ́: nítorí a kò mọ bí a ti ń gbàdúrà gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ: ṣùgbọ́n ẹ̀mí tìkára rẹ̀ ń fi ìrora tí a kò le fi ẹnu sọ bẹ̀bẹ̀ fún wa. 27 (A)Ẹni tí ó sì ń wá inú ọkàn wò, ó mọ ohun ti ẹ̀mí, nítorí tí ó ń bẹ̀bẹ̀ fún àwọn ènìyàn mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọ́run.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.