Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Peteru wàásù sí ọ̀pọ̀ ènìyàn
14 Nígbà náà ni Peteru dìde dúró pẹ̀lú àwọn mọ́kànlá yòókù, ó gbé ohùn rẹ̀ sókè, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin Júù ènìyàn mi àti gbogbo ẹ̀yin tí ń gbé Jerusalẹmu, ẹ jẹ́ kí èyí kí ó yé yin; kí ẹ sì fetísí ọ̀rọ̀ mi.
36 “Ǹjẹ́ kí gbogbo ilé Israẹli mọ̀ dájúdájú pé: Ọlọ́run ti fi Jesu náà, ti ẹ̀yin kàn mọ́ àgbélébùú, ṣe Olúwa àti Kristi.”
37 Nígbà tí wọ́n sì gbọ́, ọkàn wọn gbọgbẹ́, wọn sì wí fún Peteru àti àwọn aposteli yòókù pé, “Ará, kín ni àwa yóò ṣe?”
38 Peteru sì wí fún wọn pé, “Ẹ ronúpìwàdà, kí a sì bamitiisi olúkúlùkù yín ní orúkọ Jesu Kristi fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ yín. Ẹ̀yin yóò sì gba ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ 39 (A)Nítorí fún yín ni ìlérí náà, àti fún àwọn ọmọ yín, àti fún gbogbo àwọn tí ó jìnnà réré, àní gbogbo àwọn tí Olúwa Ọlọ́run wa yóò pè.”
40 Pẹ̀lú ọ̀rọ̀ púpọ̀ mìíràn ni ó fi ń kìlọ̀ tí ó sì ń fi ń rọ̀ wọ́n wí pé, “Ẹ gba ara yín là lọ́wọ́ ìran àrékérekè yìí.” 41 Nítorí náà àwọn tí ó fi ayọ̀ gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ a bamitiisi wọn, lọ́jọ́ náà a sì kà ìwọ̀n ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ọkàn kún wọn.
116 Èmi fẹ́ràn Olúwa, nítorí ó gbọ́ ohùn mi;
ó gbọ́ ẹkún mi fún àánú.
2 Nítorí ó yí etí rẹ̀ padà sí mi,
èmi yóò máa pè é ni wọ́n ìgbà tí mo wà láààyè.
3 Okùn ikú yí mi ká,
ìrora isà òkú wá sórí mi;
ìyọnu àti ìbànújẹ́ borí mi.
4 Nígbà náà ni mo ké pe orúkọ Olúwa:
“Olúwa, èmi bẹ̀ ọ́, gba ọkàn mi!”
12 Kí ni èmi yóò san fún Olúwa
nítorí gbogbo rere rẹ̀ sí mi?
13 Èmi yóò gbé ago ìgbàlà sókè
èmi yóò sì máa ké pe orúkọ Olúwa.
14 Èmi yóò mú ìlérí mi ṣẹ sí Olúwa
ní ojú àwọn ènìyàn rẹ̀.
15 Iyebíye ní ojú Olúwa
àti ikú àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀.
16 Olúwa, nítòótọ́ ìránṣẹ́ rẹ ni mo jẹ́;
èmi ni ìránṣẹ́ rẹ, ọmọ ìránṣẹ́bìnrin rẹ;
ó ti tú mi sílẹ̀ nínú ìdè mi.
17 Èmi yóò rú ẹbọ ọpẹ́ sí ọ
èmi yóò sì ké pe orúkọ Olúwa
18 Èmi yóò mú ìlérí mi sẹ sí Olúwa
ní ojú gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀,
19 Nínú àgbàlá ilé Olúwa
ní àárín rẹ̀, ìwọ Jerusalẹmu.
Ẹ yin Olúwa.
17 Níwọ́n bí ẹ̀yin ti ń ké pe Baba, ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ olúkúlùkù láìṣe ojúsàájú, ẹ máa lo ìgbà àtìpó yin ni ìbẹ̀rù. 18 Níwọ̀n bí ẹ̀yin ti mọ̀ pé a kò fi ohun ìdíbàjẹ́ rà yín padà, bí fàdákà tàbí wúrà kúrò nínú ìwà asán yín, tí ẹ̀yin ti jogún láti ọ̀dọ̀ àwọn baba yín. 19 Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ iyebíye, bí i ti ọ̀dọ́-àgùntàn ti kò lábùkù, tí kò sì lábàwọ́n, àní, ẹ̀jẹ̀ Kristi. 20 Ẹni tí a ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ nítòótọ́ ṣáájú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, ṣùgbọ́n tí a fihàn ní ìgbà ìkẹyìn wọ̀nyí nítorí yín, 21 Àní ẹ̀yin tí o tipasẹ̀ rẹ̀ gba Ọlọ́run gbọ́, ẹni ti ó jí i dìde kúrò nínú òkú, tí ó sì fi ògo fún un; kí ìgbàgbọ́ àti ìrètí yín lè wà lọ́dọ̀ Ọlọ́run.
22 Níwọ́n bí ẹ̀yin ti wẹ ọkàn yin mọ́ nípa ìgbọ́ràn yín sí òtítọ́ sí ìfẹ́ ará ti kò ní ẹ̀tàn, ẹ fẹ́ ọmọnìkejì yín gidigidi láti ọkàn wá. 23 Bí a ti tún yín bí, kì í ṣe láti inú ìdíbàjẹ́ wá, bí kò ṣe èyí ti kì í díbàjẹ́ nípa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí ń bẹ láààyè tí ó sì dúró.
Ní ojú ọnà sí Emmausi
13 Sì kíyèsi i, àwọn méjì nínú wọn ń lọ ní ọjọ́ náà sí ìletò kan tí a ń pè ní Emmausi, tí ó jìnnà sí Jerusalẹmu níwọ̀n ọgọ́ta ibùsọ̀. 14 Wọ́n ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí ó ṣẹlẹ̀. 15 Ó sì ṣe, bí wọ́n ti ń bá ara wọn sọ̀rọ̀, tí wọ́n sì ń bá ara wọn jíròrò, Jesu tìkára rẹ̀ súnmọ́ wọn, ó sì ń bá wọn rìn lọ. 16 (A)Ṣùgbọ́n a rú wọn lójú, kí wọn má le mọ̀ ọ́n.
17 Ó sì bi wọ́n pé, “Ọ̀rọ̀ kín ni ẹ̀yin ń bá ara yín sọ, bí ẹ̀yin ti ń rìn?”
Wọ́n sì dúró jẹ́, wọ́n fajúro. 18 Ọ̀kan nínú wọn, tí a ń pè ní Kileopa, sì dáhùn wí fún un pé, “Àlejò sá à ni ìwọ ní Jerusalẹmu, tí ìwọ kò sì mọ ohun tí ó ṣẹ̀ níbẹ̀ ní ọjọ́ wọ̀nyí?”
19 (B)Ó sì bi wọ́n pé, “Kín ni?”
Wọ́n sì wí fún un pé, “Ní ti Jesu ti Nasareti, ẹni tí ó jẹ́ wòlíì, tí ó pọ̀ ní ìṣe àti ní ọrọ̀ níwájú Ọlọ́run àti gbogbo ènìyàn, 20 Àti bí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn alàgbà wa ti fi òun lé wọn lọ́wọ́ láti dá a lẹ́bi ikú, àti bí wọ́n ti kàn án mọ́ àgbélébùú. 21 Bẹ́ẹ̀ ni òun ni àwa ti ní ìrètí pé, òun ni ìbá dá Israẹli ní ìdè. Àti pẹ̀lú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, òní ni ó di ọjọ́ kẹta tí nǹkan wọ̀nyí ti ṣẹlẹ̀. 22 Àwọn obìnrin kan pẹ̀lú nínú ẹgbẹ́ wa, tí wọ́n lọ si ibojì ní kùtùkùtù, sì wá yà wá lẹ́nu: 23 Nígbà tí wọn kò sì rí òkú rẹ̀, wọ́n wá wí pé, àwọn rí ìran àwọn angẹli tí wọ́n wí pé, ó wà láààyè. 24 (C)Àti àwọn kan tí wọ́n wà pẹ̀lú wa lọ sí ibojì, wọ́n sì rí i gẹ́gẹ́ bí àwọn obìnrin náà ti wí: ṣùgbọ́n òun tìkára rẹ̀ ni wọn kò rí.”
25 Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin tí òye kò yé, tí ẹ sì yigbì ní àyà láti gba gbogbo èyí tí àwọn wòlíì ti wí gbọ́: 26 Kò ha yẹ kí Kristi ó jìyà nǹkan wọ̀nyí kí ó sì wọ inú ògo rẹ̀ lọ.” 27 (D)Ó sì bẹ̀rẹ̀ láti Mose àti gbogbo àwọn wòlíì wá, ó sì túmọ̀ nǹkan fún wọn nínú ìwé mímọ́ gbogbo nípa ti ara rẹ̀.
28 (E)Wọ́n sì súnmọ́ ìletò tí wọ́n ń lọ: ó sì ṣe bí ẹni pé yóò lọ sí iwájú. 29 Wọ́n sì rọ̀ ọ́, pé, “Bá wa dúró: nítorí ó di ọjọ́ alẹ́, ọjọ́ sì kọjá tán.” Ó sì wọlé lọ, ó bá wọn dúró.
30 (F)Ó sì ṣe, bí ó ti bá wọn jókòó ti oúnjẹ, ó mú àkàrà, ó súre sí i, ó sì bù ú, ó sì fi fún wọn. 31 Ojú wọn sì là, wọ́n sì mọ̀ ọ́n; ó sì nù mọ́ wọn ní ojú 32 Wọ́n sì bá ara wọn sọ pé, “Ọkàn wa kò ha gbiná nínú wa, nígbà tí ó ń bá wa sọ̀rọ̀ tí ó sì ń túmọ̀ ìwé mímọ́ fún wa!”
33 Wọ́n sì dìde ní wákàtí kan náà, wọ́n padà lọ sí Jerusalẹmu, wọ́n sì bá àwọn mọ́kànlá péjọ, àti àwọn tí ń bẹ lọ́dọ̀ wọn, 34 (G)Wọn si wí pé, “Olúwa jíǹde nítòótọ́, ó sì ti fi ara hàn fún Simoni!” 35 Àwọn náà sì ròyìn nǹkan tí ó ṣe ní ọ̀nà, àti bí ó ti di mí mọ̀ fún wọn ní bíbu àkàrà.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.