Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
116 Èmi fẹ́ràn Olúwa, nítorí ó gbọ́ ohùn mi;
ó gbọ́ ẹkún mi fún àánú.
2 Nítorí ó yí etí rẹ̀ padà sí mi,
èmi yóò máa pè é ni wọ́n ìgbà tí mo wà láààyè.
3 Okùn ikú yí mi ká,
ìrora isà òkú wá sórí mi;
ìyọnu àti ìbànújẹ́ borí mi.
4 Nígbà náà ni mo ké pe orúkọ Olúwa:
“Olúwa, èmi bẹ̀ ọ́, gba ọkàn mi!”
12 Kí ni èmi yóò san fún Olúwa
nítorí gbogbo rere rẹ̀ sí mi?
13 Èmi yóò gbé ago ìgbàlà sókè
èmi yóò sì máa ké pe orúkọ Olúwa.
14 Èmi yóò mú ìlérí mi ṣẹ sí Olúwa
ní ojú àwọn ènìyàn rẹ̀.
15 Iyebíye ní ojú Olúwa
àti ikú àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀.
16 Olúwa, nítòótọ́ ìránṣẹ́ rẹ ni mo jẹ́;
èmi ni ìránṣẹ́ rẹ, ọmọ ìránṣẹ́bìnrin rẹ;
ó ti tú mi sílẹ̀ nínú ìdè mi.
17 Èmi yóò rú ẹbọ ọpẹ́ sí ọ
èmi yóò sì ké pe orúkọ Olúwa
18 Èmi yóò mú ìlérí mi sẹ sí Olúwa
ní ojú gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀,
19 Nínú àgbàlá ilé Olúwa
ní àárín rẹ̀, ìwọ Jerusalẹmu.
Ẹ yin Olúwa.
6 Ní orí òkè yìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun
yóò ti pèsè
àsè oúnjẹ àdídùn kan fún gbogbo ènìyàn
àpèjẹ ti ọtí wáìnì àtijọ́
ti ẹran tí ó dára jù àti ti ọtí wáìnì
tí ó gbámúṣé.
7 Ní orí òkè yìí ni yóò pa
aṣọ òkú tí ó ti ń di gbogbo ènìyàn,
abala tí ó bo gbogbo orílẹ̀-èdè mọ́lẹ̀;
8 (A)Òun yóò sì gbé ikú mì títí láé.
Olúwa Olódùmarè yóò sì nu gbogbo omijé nù,
kúrò ní ojú gbogbo wọn;
Òun yóò sì mú ẹ̀gàn àwọn ènìyàn rẹ̀ kúrò
ní gbogbo ilẹ̀ ayé.
Olúwa ni ó ti sọ ọ́.
9 Ní ọjọ́ náà wọn yóò sọ pé,
“Nítòótọ́ eléyìí ni Ọlọ́run wa;
àwa ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú rẹ̀, òun sì gbà wá là.
Èyí ni Olúwa, àwa gbẹ́kẹ̀lé e,
ẹ jẹ́ kí a yọ̀ kí inú wa sì dùn nínú ìgbàlà rẹ̀.”
12 (A)Nígbà náà ni ó sì wí fún alásè tí ó pè é pé, “Nígbà tí ìwọ bá ṣe àsè má ṣe pe àwọn arákùnrin rẹ tàbí àwọn ìbátan rẹ, tàbí àwọn ọlọ́rọ̀ aládùúgbò rẹ̀; nítorí kí wọn má ṣe pè ọ́ padà láti san ẹ̀san padà. 13 (B)Ṣùgbọ́n nígbà tí ìwọ bá ṣe àsè, pe àwọn tálákà, àwọn alábùkún ara, àwọn amúnkùn ún, àti àwọn afọ́jú: 14 Ìwọ ó sì jẹ́ alábùkún fún; nítorí wọn kò ní ohun tí wọn ó fi san án fún ọ: ṣùgbọ́n a ó san án fún ọ ní àjíǹde, àwọn olóòtítọ́.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.