Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
116 Èmi fẹ́ràn Olúwa, nítorí ó gbọ́ ohùn mi;
ó gbọ́ ẹkún mi fún àánú.
2 Nítorí ó yí etí rẹ̀ padà sí mi,
èmi yóò máa pè é ni wọ́n ìgbà tí mo wà láààyè.
3 Okùn ikú yí mi ká,
ìrora isà òkú wá sórí mi;
ìyọnu àti ìbànújẹ́ borí mi.
4 Nígbà náà ni mo ké pe orúkọ Olúwa:
“Olúwa, èmi bẹ̀ ọ́, gba ọkàn mi!”
12 Kí ni èmi yóò san fún Olúwa
nítorí gbogbo rere rẹ̀ sí mi?
13 Èmi yóò gbé ago ìgbàlà sókè
èmi yóò sì máa ké pe orúkọ Olúwa.
14 Èmi yóò mú ìlérí mi ṣẹ sí Olúwa
ní ojú àwọn ènìyàn rẹ̀.
15 Iyebíye ní ojú Olúwa
àti ikú àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀.
16 Olúwa, nítòótọ́ ìránṣẹ́ rẹ ni mo jẹ́;
èmi ni ìránṣẹ́ rẹ, ọmọ ìránṣẹ́bìnrin rẹ;
ó ti tú mi sílẹ̀ nínú ìdè mi.
17 Èmi yóò rú ẹbọ ọpẹ́ sí ọ
èmi yóò sì ké pe orúkọ Olúwa
18 Èmi yóò mú ìlérí mi sẹ sí Olúwa
ní ojú gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀,
19 Nínú àgbàlá ilé Olúwa
ní àárín rẹ̀, ìwọ Jerusalẹmu.
Ẹ yin Olúwa.
Orin ìyìn kan
26 Ní ọjọ́ náà ni a ó kọ orin yìí ní ilẹ̀ Juda:
Àwa ní ìlú alágbára kan,
Ọlọ́run fi ìgbàlà ṣe
ògiri àti ààbò rẹ̀.
2 Ṣí àwọn ìlẹ̀kùn
kí àwọn olódodo orílẹ̀-èdè kí ó lè wọlé,
orílẹ̀-èdè tí ó pa ìgbàgbọ́ mọ́.
3 Ìwọ yóò pa á mọ́ ní àlàáfíà pípé
ọkàn ẹni tí ó dúró ṣinṣin,
nítorí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ.
4 Gbẹ́kẹ̀lé Olúwa títí láé,
nítorí Olúwa, Olúwa ni àpáta
ayérayé náà.
Ẹ jẹ́ mímọ́
13 Nítorí náà, ẹ múra ọkàn yín sílẹ̀, ẹ kó ara yín ní ìjánu, kí ẹ sì fi ìrètí yín ní kíkún sí oore-ọ̀fẹ́, èyí tí a ń mu bọ̀ fún yin ni ìgbà ìfarahàn Jesu Kristi. 14 Bí àwọn ọmọ tí ń gbọ́rọ̀, ẹ ma ṣe da ara yín pọ̀ mọ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àìmọ́ yín ti àtijọ́. 15 Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹni tí o pè yin ti jẹ mímọ́; bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin náà jẹ mímọ́. 16 (A)Nítorí a ti kọ ọ pé, “Ẹ jẹ́ mímọ́: nítorí tí Èmi jẹ mímọ́!”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.