Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Miktamu ti Dafidi.
16 Pa mí mọ́, Ọlọ́run,
nítorí nínú rẹ ni ààbò mi wà.
2 Mo sọ fún Olúwa, “ìwọ ni Olúwa mi,
lẹ́yìn rẹ èmi kò ní ìre kan.”
3 Sí àwọn ènìyàn tí ó wà ní ayé,
àwọn ni ológo nínú èyí tí ayọ̀ mí wà.
4 Ìṣòro àwọn wọ̀n-ọn-nì yóò pọ̀ sí i, àní àwọn tí ń tọ ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn.
Ẹbọ ohun mímu ẹ̀jẹ̀ wọn ni èmi kì yóò ta sílẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò dá orúkọ wọn lẹ́nu mi.
5 Olúwa, ni ìpín ìní mi tí mo yàn àti ago mi,
ó ti pa ohun tí í ṣe tèmi mọ́.
6 Okùn ààlà ilẹ̀ ti bọ́ sí ọ̀dọ̀ mi ní ibi dídára;
nítòótọ́ mo ti ní ogún rere.
7 Èmi yóò yin Olúwa, ẹni tí ó gbà mí ní ìyànjú;
ní òru, ọkàn mí ń bá mi sọ̀rọ̀.
8 (A)Mo ti gbé Ọlọ́run síwájú mi ní ìgbà gbogbo.
Nítorí tí ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún mi, a kì yóò mì mí.
9 Nítorí èyí, ọkàn mi yọ̀, ahọ́n mi pẹ̀lú ń fò fáyọ̀;
ara mi pẹ̀lú yóò sinmi ní ààbò,
10 (B)nítorí ìwọ kò ní fi ọ̀kan sílẹ̀ nínú isà òkú,
tàbí kí ìwọ jẹ́ kí ẹni mímọ́ rẹ kí ó rí ìdíbàjẹ́.
11 Ìwọ ti fi ipa ọ̀nà ìyè hàn mí;
Ìwọ yóò kún mi pẹ̀lú ayọ̀ ní iwájú rẹ,
pẹ̀lú ìdùnnú ayérayé ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ.
8 Gbọ́ ohùn olùfẹ́ mi!
Wò ó! Ibí yìí ni ó ń bọ̀.
Òun ń fò lórí àwọn òkè ńlá,
Òun bẹ́ lórí àwọn òkè kéékèèkéé
9 Olùfẹ́ mi dàbí abo egbin tàbí ọmọ àgbọ̀nrín
Wò ó! Níbẹ̀ ni ó wà lẹ́yìn ògiri wa
Ó yọjú ní ojú fèrèsé
Ó ń fi ara rẹ̀ hàn lójú fèrèsé ọlọ́nà
10 Olùfẹ́ mi fọhùn ó sì sọ fún mi pé,
“Dìde, Olólùfẹ́ mi,
arẹwà mi, kí o sì wà pẹ̀lú mi.
11 Wò ó! Ìgbà òtútù ti kọjá;
òjò ti rọ̀ dawọ́, ó sì ti lọ.
12 Àwọn òdòdó fi ara hàn lórí ilẹ̀
àsìkò ìkọrin àwọn ẹyẹ dé
a sì gbọ́ ohùn àdàbà ní ilẹ̀ wa.
13 Igi ọ̀pọ̀tọ́ mú èso tuntun jáde,
àwọn àjàrà nípa ìtànná wọ́n fún ni ní òórùn dídùn,
Dìde, wá, Olólùfẹ́ mi;
Arẹwà mi nìkan ṣoṣo, wá pẹ̀lú mi.”
Olùfẹ́
14 Àdàbà mi wà nínú pàlàpálá òkúta,
ní ibi ìkọ̀kọ̀ ní orí òkè gíga,
fi ojú rẹ hàn mí,
jẹ́ kí èmi gbọ́ ohùn rẹ;
Nítorí tí ohùn rẹ dùn,
tí ojú rẹ sì ní ẹwà.
15 Bá wa mú àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀,
àní àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ kéékèèkéé
tí ń ba ọgbà àjàrà jẹ́,
àwọn ọgbà àjàrà wa tó ní ìtànná.
Àwọn ìlànà fún ìjọ
2 Ẹ fi ara yín jì fún àdúrà gbígbà, kí ẹ ṣọ́ra kí ẹ sì máa dúpẹ́; 3 Ẹ máa gbàdúrà fún wa pẹ̀lú, kí Ọlọ́run lè ṣí ìlẹ̀kùn fún wa fún ọ̀rọ̀ náà, láti máa sọ ohun ìjìnlẹ̀ Kristi, nítorí èyí tí mo ṣe wà nínú ìdè pẹ̀lú: 4 Ẹ gbàdúrà pé kí èmi le è máa kéde rẹ̀ kedere gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́ fún mi. 5 (A)Ẹ jẹ́ ọlọ́gbọ́n ní ti bí ẹ ti ń ṣe pẹ̀lú àwọn tí ń bẹ lóde, kí ẹ sì máa ṣe ṣí àǹfààní tí ẹ bá nílò.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.