Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 121

Orin fún ìgòkè.

121 Èmi yóò gbé ojú mi sórí òkè wọ̀n-ọn-nì—
    níbo ni ìrànlọ́wọ́ mi yóò ti wá
Ìrànlọ́wọ́ mi tí ọwọ́ Olúwa
    Ẹni tí ó dá ọ̀run òun ayé.

Òun kì yóò jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ kí ó yẹ̀;
    ẹni tí ó pa ọ́ mọ́ kì í tòògbé.
Kíyèsi, ẹni tí ń pa Israẹli mọ́,
    kì í tòògbé bẹ́ẹ̀ ni kì í sùn.

Olúwa ni olùpamọ́ rẹ;
    Olúwa ní òjìji rẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ
Oòrùn kì yóò pa ọ́ ní ìgbà ọ̀sán
    tàbí òṣùpá ní ìgbà òru.

Olúwa yóò pa ọ́ mọ́ kúrò nínú ibi gbogbo
    yóò pa ọkàn rẹ mọ́
Olúwa yóò pa àlọ àti ààbọ̀ rẹ mọ́
    láti ìgbà yìí lọ àti títí láéláé.

Isaiah 51:4-8

“Tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin ènìyàn mi;
    gbọ́ tèmi, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè mi:
Òfin yóò ti ọ̀dọ̀ mi jáde wá;
    ìdájọ́ mi yóò di ìmọ́lẹ̀ sí àwọn orílẹ̀-èdè.
Òdodo mi ń bọ̀ wá kíkankíkan,
    ìgbàlà mi ń bọ̀ lójú ọ̀nà,
àti apá mi yóò sì mú ìdájọ́ wá
    sí àwọn orílẹ̀-èdè.
Àwọn erékùṣù yóò wò mí
    wọn yóò sì dúró ní ìrètí fún apá mi.
(A)Gbé ojú rẹ sókè sí àwọn ọ̀run,
    wo ilẹ̀ ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀;
Àwọn ọ̀run yóò pòórá bí èéfín,
    ilẹ̀ yóò sì gbó bí ẹ̀wù
àwọn olùgbé inú rẹ̀ yóò kú gẹ́gẹ́ bí àwọn eṣinṣin.
    Ṣùgbọ́n ìgbàlà mi yóò wà títí láé,
    òdodo mi kì yóò yẹ̀ láé.

“Ẹ gbọ́ mi, ẹ̀yin tí ó mọ ohun òtítọ́,
    ẹ̀yin ènìyàn tí ó ní òfin mi ní àyà yín:
Ẹ má ṣe bẹ̀rù ẹ̀gàn àwọn ènìyàn
    tàbí kí ẹ̀rù èébú wọn já a yín láyà.
Nítorí kòkòrò yóò mú wọn lá bí aṣọ;
    Ìdin yóò sì mú wọn jẹ bí ẹ̀gbọ̀n òwú.
Ṣùgbọ́n òdodo mi yóò wà títí ayérayé,
    àti ìgbàlà mi láti ìrandíran.”

Luku 7:1-10

Ìgbàgbọ́ ọ̀gágun Romu kan

(A)Nígbà tí ó sì parí gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀ fun àwọn ènìyàn, ó wọ Kapernaumu lọ. Ọmọ ọ̀dọ̀ balógun ọ̀rún kan, tí ó ṣọ̀wọ́n fún un, ṣàìsàn, ó sì ń kú lọ. Nígbà tí ó sì gbúròó Jesu, ó rán àwọn àgbàgbà Júù sí i, ó ń bẹ̀ ẹ́ pé kí ó wá mú ọmọ ọ̀dọ̀ òun láradá. Nígbà tí wọ́n sì dé ọ̀dọ̀ Jesu, wọ́n fi ìtara bẹ̀ ẹ́, pé, “Ó yẹ ní ẹni tí òun ìbá ṣe èyí fún: (B)Nítorí tí ó fẹ́ràn orílẹ̀-èdè wa, ó sì ti kọ́ Sinagọgu kan fún wa.” Jesu sì ń bá wọn lọ.

Nígbà tí kò sì jìn sí etí ilé mọ́, balógun ọ̀rún náà rán àwọn ọ̀rẹ́ sí i, pé, “Olúwa, má ṣe yọ ara rẹ lẹ́nu: nítorí tí èmi kò yẹ tí ìwọ ìbá fi wọ abẹ́ òrùlé mi: Nítorí náà èmi kò sì rò pé èmi náà yẹ láti tọ̀ ọ́ wá: ṣùgbọ́n sọ ní gbólóhùn kan, a ó sì mú ọmọ ọ̀dọ̀ mi láradá. Nítorí èmi náà pẹ̀lú jẹ́ ẹni tí a fi sí abẹ́ àṣẹ, tí ó ní ọmọ-ogun lẹ́yìn mi, mo sì wí fún ọ̀kan pé, ‘Lọ,’ a sì lọ; àti fún òmíràn pé, ‘Wá,’ a sì wá; àti fún ọmọ ọ̀dọ̀ mi pé, ‘Ṣe èyí,’ a sì ṣe é.”

Nígbà tí Jesu gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, ẹnu sì yà, ó sì yípadà sí ìjọ ènìyàn tí ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, ó wí pé, “Mo wí fún yín pé èmi kò rí irú ìgbàgbọ́ ńlá bí èyí nínú àwọn ènìyàn Israẹli.” 10 Nígbà tí àwọn oníṣẹ́ sì padà sí ilé, wọ́n bá ọmọ ọ̀dọ̀ náà tí ń ṣàìsàn, ara rẹ̀ ti dá.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.