Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 32

Ti Dafidi. Maskili.

32 (A)Ìbùkún ni fún àwọn
    tí a dárí ìrékọjá wọn jì,
    tí a sì bo ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀.
Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà
    ẹni tí Ọlọ́run kò ka ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ sí i lọ́rùn
    àti nínú ẹ̀mí ẹni tí kò sí ẹ̀tàn.

Nígbà tí mo dákẹ́,
    egungun mi di gbígbó dànù
    nípa ìkérora mi ní gbogbo ọjọ́.
Nítorí pé ni ọ̀sán àti ní òru
    ọwọ́ rẹ̀ wúwo sí mi lára;
agbára mi gbẹ tán
    gẹ́gẹ́ bí ooru ẹ̀ẹ̀rùn. Sela.

Èmi jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi sí ọ
    àti pé èmi kò sì fi àìṣòdodo mi pamọ́.
Èmi wí pé, “Èmi yóò jẹ́wọ́
    ẹ̀ṣẹ̀ mi fún Olúwa,”
ìwọ sì dárí
    ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí. Sela.

Nítorí náà jẹ́ kí gbogbo àwọn olódodo máa gbà àdúrà sí ọ
    ní ìgbà tí a lè rí ọ;
nítòótọ́ nígbà tí ìṣàn omi ńlá bá ru sókè,
    wọn kì yóò lè dé ọ̀dọ̀ rẹ̀.
Ìwọ ni ibi ìpamọ́ mi;
    ìwọ yóò pa mí mọ́ kúrò nínú ìyọnu;
    ìwọ yóò fi orin ìgbàlà yí mi ka. Sela.

Èmi yóò kọ́ ọ, èmi yóò sì fi ẹsẹ̀ rẹ lé ọ̀nà tí ìwọ yóò rìn
    èmi yóò máa gbà ọ́ ní ìyànjú, èmi yóò sì máa fi ojú mi tọ́ ọ.
Má ṣe dàbí ẹṣin tàbí ìbáaka,
    tí kò ní òye
ẹnu ẹni tí a gbọdọ̀ fi ìjánu bọ̀,
    kí wọn má ba à súnmọ́ ọ.
10 Ọ̀pọ̀ ìkáàánú ní yóò wà fún ènìyàn búburú,
    ṣùgbọ́n ìfẹ́ Olúwa tí ó dúró ṣinṣin
    ni yóò yí àwọn tí ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa ká.

11 Ẹ yọ̀ nínú Olúwa, kí ẹ sì ní inú dídùn, ẹ̀yìn olódodo;
    ẹ sì máa kọrin, gbogbo ẹ̀yìn tí àyà yín dúró ṣinṣin.

1 Ọba 19:1-8

Elijah sálọ sí Horebu

19 Ahabu sì sọ gbogbo ohun tí Elijah ti ṣe fún Jesebeli àti bí ó ti fi idà pa gbogbo àwọn wòlíì. Nítorí náà Jesebeli rán oníṣẹ́ kan sí Elijah wí pé, “Kí àwọn òrìṣà kí ó ṣe sí mi àti jù bẹ́ẹ̀ lọ pẹ̀lú, bí èmi kò bá ṣe ẹ̀mí rẹ bí ọ̀kan nínú wọn ní ìwòyí ọ̀la.”

Elijah sì bẹ̀rù, ó sá fún ẹ̀mí rẹ̀. Nígbà tí ó sì dé Beerṣeba ti Juda, ó sì fi ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ sílẹ̀ níbẹ̀, nígbà tí òun tìkára rẹ̀ sì lọ ní ìrìn ọjọ́ kan sí aginjù, ó sì wá sí ibi igi ọwọ̀ kan, ó sì jókòó lábẹ́ rẹ̀, ó sì gbàdúrà kí òun bá le kú, wí pé, “Mo ti ní tó, Olúwa, gba ẹ̀mí mi kúrò; nítorí èmi kò sàn ju àwọn baba mi lọ” Nígbà náà ni ó dùbúlẹ̀ lábẹ́ igi, ó sì sùn lọ.

Sì wò ó, angẹli fi ọwọ́ tọ́ ọ, ó sì wí pé, “Dìde, kí o jẹun.” Ó sì wò ó yíká, àkàrà tí a dín lórí ẹ̀yín iná, àti orù-omi wà lẹ́bàá orí rẹ̀. Ó sì jẹ, ó sì mu, ó sì tún dùbúlẹ̀.

Angẹli Olúwa sì tún padà wá lẹ́ẹ̀kejì, ó sì tún fi ọwọ́ tọ́ ọ, ó sì wí pé, “Dìde, kí ó jẹun, nítorí ìrìnàjò náà jì fún ọ.” Ó si dìde, ó sì jẹ, ó mu, o sì fi agbára oúnjẹ yìí lọ ní ogójì ọ̀sán àti ogójì òru sí Horebu, òkè Ọlọ́run.

Heberu 2:10-18

10 Nítorí pé ó yẹ fún Ọlọ́run, nítorí nípasẹ̀ ẹni tí ohun gbogbo ṣẹ̀ wà, láti mú àwọn ọmọ púpọ̀ wá sínú ògo, láti ṣe balógun ìgbàlà wọn ni àṣepé nípa ìjìyà. 11 Nítorí àti ẹni tí ń sọ ni di mímọ́ àti àwọn tí a ń sọ di mímọ́, láti ọ̀dọ̀ ẹnìkan ṣoṣo ni gbogbo wọn ti wá: Nítorí èyí ni kò ṣe tijú láti pè wọ́n ni arákùnrin. 12 (A)Àti wí pé,

“Èmi ó sọ̀rọ̀ orúkọ rẹ̀ fún àwọn ará mi,
    ni àárín ìjọ ni èmi yóò kọrin ìyìn rẹ̀.”

13 (B)Àti pẹ̀lú,

“Èmi yóò gbẹ́kẹ̀ mi lé e.”

Àti pẹ̀lú,

“Kíyèsi í, èmi rèé, èmi àti àwọn ọmọ tí Ọlọ́run fi fún mi.”

14 Ǹjẹ́ ni ìwọ̀n bí àwọn ọmọ tí ṣe alábápín ará àti ẹ̀jẹ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni òun pẹ̀lú sì ṣe alábápín nínú ohun kan náà; kí ó lè ti ipa ikú rẹ̀ pa ẹni tí ó ní agbára ikú run, èyí ni èṣù. 15 Kí o sì lè gba gbogbo àwọn tí ó tìtorí ìbẹ̀rù ikú wà lábẹ́ ìdè lọ́jọ́ ayé wọn gbogbo kúrò lọ́wọ́ ìbẹ̀rù. 16 (C)Nítorí pé, nítòótọ́, kì í ṣe àwọn angẹli ni ó ṣe ìrànlọ́wọ́ fún, ṣùgbọ́n àwọn irú-ọmọ Abrahamu ni ó ṣe ìrànlọ́wọ́ fún. 17 Nítorí náà, ó yẹ pé nínú ohun gbogbo kí ó dàbí àwọn ará rẹ̀, kí ó lè jẹ́ aláàánú àti olóòtítọ́ alábojútó Àlùfáà nínú ohun tí i ṣe ti Ọlọ́run, kí o lè ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn. 18 Nítorí níwọ̀n bí òun tìkára rẹ̀ ti jìyà tí a sì ti dán an wò, òun ní agbára láti ran àwọn tí a ń dánwò lọ́wọ́.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.