Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 51

Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi. Nígbà ti wòlíì Natani tọ wá, lẹ́yìn tí Dafidi dá ẹ̀ṣẹ̀ àgbèrè rẹ̀ pẹ̀lú Batṣeba.

51 Ṣàánú fún mi, Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí
    ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ rẹ̀,
gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ àánú rẹ̀
    kí o sì pa gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi rẹ́.
Wẹ gbogbo àìṣedéédéé mi nù kúrò
    kí o sì wẹ̀ mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi!

Nítorí mo mọ̀ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi,
    nígbà gbogbo ni ẹ̀ṣẹ̀ mi wà níwájú mi.
(A)Sí ọ, ìwọ nìkan ṣoṣo, ni mo dẹ́ṣẹ̀ sí
    ni mo sì ṣe búburú níwájú rẹ̀,
kí a lè dá ọ láre nígbà tí ìwọ bá ń sọ̀rọ̀,
    kí o sì le wà láìlẹ́bi, nígbà tí ìwọ bá ń ṣe ìdájọ́.
Nítòótọ́, nínú ẹ̀ṣẹ̀ ni a ti bí mi,
    nínú ẹ̀ṣẹ̀ ni ìyá mí sì lóyún mi.
Nítòótọ́ ìwọ fẹ́ òtítọ́ ní inú;
    ìwọ kọ́ mi ní ọgbọ́n ní ìhà ìkọ̀kọ̀.

Wẹ̀ mí pẹ̀lú ewé hísópù, èmi yóò sì mọ́;
    fọ̀ mí, èmi yóò sì funfun ju yìnyín lọ.
Jẹ́ kí n gbọ́ ayọ̀ àti inú dídùn;
    jẹ́ kí gbogbo egungun tí ìwọ ti run kí ó máa yọ̀.
Pa ojú rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi
    kí o sì pa gbogbo àwọn àìṣedéédéé mi rẹ́.

10 Dá ọkàn mímọ́ sí inú mi, Ọlọ́run,
    kí o sì tún ẹ̀mí dídúró ṣinṣin ṣe sínú mi.
11 Má ṣe jù mi nù kúrò níwájú rẹ,
    kí o má ṣe gba ẹ̀mí mímọ́ rẹ lọ́wọ́ mi.
12 Mú ayọ̀ ìgbàlà rẹ tọ̀ mí wá,
    kí o sì fún mi ní ẹ̀mí ìfẹ́, tí yóò mú mi dúró.

13 Nígbà náà ni èmi yóò máa kọ́ àwọn olùrékọjá ní ọ̀nà rẹ,
    àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yóò sì yí padà sí ọ.
14 Gbà mí kúrò lọ́wọ́ ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀, Ọlọ́run,
    ìwọ Ọlọ́run ìgbàlà mi,
ahọ́n mi yóò sì máa kọrin òdodo rẹ kíkan.
15 Olúwa, ṣí mi ní ètè mi gbogbo,
    àti ẹnu mi yóò sì máa kéde ìyìn rẹ.
16 Nítorí ìwọ kò ní inú dídùn sí ẹbọ, tí èmi kò bá mú wá;
    Ìwọ kò ní inú dídùn sí ọrẹ ẹbọ sísun.
17 Ẹbọ Ọlọ́run ni ìròbìnújẹ́ ọkàn ìròbìnújẹ́ àti ìrora àyà.

18 Ṣe rere ní dídùn inú rẹ sí Sioni,
    ṣe rere; tún odi Jerusalẹmu mọ.
19 Nígbà náà ni inú rẹ yóò dùn sí ẹbọ òdodo,
    pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ sísun àti ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ọrẹ ẹbọ sísun,
    nígbà náà ni wọn yóò fi akọ màlúù rú ẹbọ lórí pẹpẹ rẹ.

Isaiah 58:1-12

Àwẹ̀ tòótọ́

58 “Kígbe rẹ̀ sókè, má ṣe fàsẹ́yìn.
    Gbé ohùn rẹ sókè bí i ti fèrè.
Jẹ́ kí ó di mí mọ̀ fún àwọn ènìyàn mi, ọ̀tẹ̀ wọn
    àti fún ilé Jakọbu ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
Nítorí ọjọ́ dé ọjọ́ ni wọ́n ń wá mi kiri;
    wọ́n ṣe bí ẹni ní ìtara láti mọ ọ̀nà mi,
àfi bí ẹni pé wọ́n jẹ́ orílẹ̀-èdè kan tí ń ṣe ohun tí ó tọ̀nà
    tí òun kò sì tí ì kọ àṣẹ Ọlọ́run rẹ̀.
Wọ́n ń béèrè lọ́wọ́ mi fún ìpinnu nìkan
    wọ́n sì ṣe bí ẹni ń tara fún Ọlọ́run láti súnmọ́ ọ̀dọ̀ wọn.
‘Èéṣe tí àwa fi ń gbààwẹ̀,’ ni wọ́n wí,
    ‘tí ìwọ kò sì tí ì rí?
Èéṣe tí àwa fi rẹra wa sílẹ̀,
    tí ìwọ kò sì tí ì ṣe àkíyèsí?’

“Síbẹ̀síbẹ̀ ní ọjọ́ àwẹ̀ yín, ẹ̀yin ń ṣe bí ó ti wù yín
    ẹ sì ń pọ́n àwọn òṣìṣẹ́ yín gbogbo lójú.
Àwẹ̀ yín sì parí nínú ìjà àti asọ̀,
    àti lílu ọmọnìkejì ẹni pa pẹ̀lú ìkùùkuu.
Ẹ̀yin kò le è gbààwẹ̀ bí ẹ ti ń ṣe lónìí
    kí ẹ sì retí kí a gbọ́ ohùn un yín ní ibi gíga.
Ǹjẹ́ èyí ha ni irú àwẹ̀ tí mo yàn bí,
    ọjọ́ kan ṣoṣo fún ènìyàn láti rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀?
Ó ha jẹ pe kí ènìyàn tẹ orí rẹ̀ ba bí i koríko lásán ni bí
    àti sísùn nínú aṣọ ọ̀fọ̀ àti eérú?
Ṣé ohun tí ẹ̀ ń pè ní àwẹ̀ nìyí,
    ọjọ́ ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa?

(A)“Ǹjẹ́ irú àwẹ̀ tí mo ti yàn kọ́ ni èyí:
    láti já gbogbo ẹ̀wọ̀n àìṣòdodo
àti láti tú gbogbo okùn àjàgà,
    láti tú gbogbo àwọn ti à ń ni lára sílẹ̀
    àti láti fọ́ gbogbo àjàgà?
Kì í ha á ṣe láti pín oúnjẹ yín fún àwọn tí ebi ń pa
    àti láti pèsè ibùgbé fún àwọn òtòṣì tí ń rìn káàkiri.
Nígbà tí ẹ bá rí ẹni tí ó wà níhòhò, láti daṣọ bò ó,
    àti láti má ṣe lé àwọn ìbátan yín sẹ́yìn?
Nígbà náà ni ìmọ́lẹ̀ rẹ yóò tàn jáde bí òwúrọ̀
    àti ìmúláradá rẹ yóò farahàn kíákíá;
nígbà náà ni òdodo rẹ yóò sì lọ níwájú rẹ,
    ògo Olúwa yóò sì jẹ́ ààbò lẹ́yìn rẹ.
Nígbà yìí ni ẹ̀yin yóò pè, tí Olúwa yóò sì dáhùn;
    ẹ̀yin yóò kígbe fún ìrànlọ́wọ́, òun yóò sì wí pé: Èmi nìyí.

“Bí ìwọ bá mú àjàgà aninilára,
    nínà ìka àlébù àti sísọ ọ̀rọ̀ asán kúrò láàrín rẹ,
10 àti bí ẹ̀yin bá ná ara yín bí owó nítorí àwọn tí ebi ń pa
    tí ẹ sì tẹ́ ìfẹ́ àwọn tí à ń ni lára lọ́rùn,
nígbà náà ni ìmọ́lẹ̀ yín yóò ràn nínú òkùnkùn,
    àti òru yín yóò dàbí ọ̀sán gangan.
11 Olúwa yóò máa tọ́ ọ yín nígbà gbogbo;
    òun yóò tẹ́ gbogbo àìní yín lọ́rùn ní ilẹ̀ tí oòrùn ń tan ìmọ́lẹ̀
yóò sì fún egungun rẹ lókun.
    Ìwọ yóò sì dàbí ọgbà tí a bomirin dáradára,
    àti bí orísun tí omi rẹ̀ kì í gbẹ.
12 Àwọn ènìyàn rẹ yóò tún ahoro àtijọ́ kọ́
    wọn yóò sì gbé ìpìlẹ̀ àtijọ́-tijọ́ ró
a ó sì pè ọ́ ní alátúnṣe ògiri tí ó ti wó
    àti olùmúbọ̀sípò àwọn òpópónà tí ènìyàn gbé inú rẹ̀.

Matiu 18:1-7

Ẹni tí ó tóbi jù ní ìjọba Ọ̀run

18 (A)Ní àkókò náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu tọ̀ ọ́ wá, wọ́n bi í léèrè pé, “Ta ni ẹni ti ó pọ̀jù ní ìjọba ọ̀run?”

Jesu sì pe ọmọ kékeré kan sí ọ̀dọ̀ ara rẹ̀. Ó sì mú un dúró láàrín wọn. (B)Ó wí pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, àfi bí ẹ̀yin bá yí padà kí ẹ sì dàbí àwọn ọmọdé, ẹ̀yin kì yóò lè wọ ìjọba ọ̀run. Nítorí náà, ẹni tí ó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọmọdé yìí, ni yóò pọ̀ jùlọ ní ìjọba ọ̀run. (C)Àti pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ọmọ kékeré bí èyí nítorí orúkọ mi, gbà mí.

“Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni nínú yín tí ó bá mú ọ̀kan nínú àwọn ọmọ kékeré wọ̀nyí tí ó gbà mí gbọ́ ṣìnà, yóò sàn fún un kí a so òkúta ńlá mọ́ ọn ní ọrùn, kí a sì rì í sí ìsàlẹ̀ ibú omi Òkun. Ègbé ni fún ayé nítorí gbogbo ohun ìkọ̀sẹ̀ rẹ̀! Ohun ìkọ̀sẹ̀ kò le ṣe kó má wà, ṣùgbọ́n ègbé ni fún ọkùnrin náà nípasẹ̀ ẹni tí ìkọ̀sẹ̀ náà ti wá!

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.