Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 78:17-20

17 Wọ́n sì tún tẹ̀síwájú láti dẹ́ṣẹ̀ sí i
    ní ìṣọ̀tẹ̀ sí Ọ̀gá-ògo ní aginjù.
18 Wọ́n mọ̀ ọ́n mọ̀ dán Ọlọ́run wò
    nípa bíbéèrè fún oúnjẹ tí wọn bẹ̀bẹ̀ fún
19 Wọ́n sọ̀rọ̀-òdì sí Ọlọ́run, wí pé
    “Ọlọ́run ha lè tẹ́ tábìlì ní aginjù?
20 Nígbà tí ó lu àpáta, omi tú jáde,
    odò sì sàn lọ́pọ̀lọpọ̀
ṣùgbọ́n òun ha lè fún wa lóúnjẹ
    ó ha le pèsè ẹran fún àwọn ènìyàn rẹ̀”

Saamu 78:52-55

52 Ṣùgbọ́n ó mú àwọn ènìyàn rẹ̀ jáde bí ọ̀wọ́ ẹran;
    ó ṣọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí àgùntàn nínú aginjù.
53 Ó dáàbò bò wọ́n dáradára, nítorí náà ni ẹ̀rù kò ṣe bà wọ́n
    ṣùgbọ́n Òkun padé mọ́ àwọn ọ̀tá wọn.
54 Bákan náà ni ó mú wọn wá sí etí ilẹ̀ mímọ́ rẹ̀
    òkè tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ti gbà
55 Ó lé kèfèrí jáde níwájú wọn
    ó sì fi títa okùn pín ilẹ̀ náà fún wọn gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìní;
    ó mú àwọn ẹ̀yà Israẹli jókòó ní ilẹ̀ wọn.

Eksodu 33:7-23

Àgọ́ àjọ

Mose máa ń gbé àgọ́ náà, ó sì pa á sí ìta ibùdó, ó jìnnà díẹ̀ sí ibùdó, ó pè é ni “Àgọ́ àjọ.” Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń béèrè Olúwa yóò lọ sí ibi àgọ́ àjọ náà ní ìta ibùdó. Nígbàkúgbà tí Mose bá jáde lọ sí ibi àgọ́, gbogbo ènìyàn á dìde, wọ́n á sì dúró sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ wọn, wọn yóò máa wo Mose títí yóò fi wọ inú àgọ́ náà. Bí Mose ṣe wọ inú àgọ́ náà, ọ̀wọ́n àwọsánmọ̀ yóò sọ̀kalẹ̀, yóò sì dúró sí ẹnu ọnà, nígbà tí Olúwa ń sọ̀rọ̀ pẹ̀lú Mose. 10 Nígbàkígbà tí àwọn ènìyàn bá rí i ti ọ̀wọ́n àwọsánmọ̀ bá dúró ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́, gbogbo wọn yóò dìde wọn yóò sì sìn, olúkúlùkù ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ rẹ̀. 11 (A)Olúwa máa ń bá Mose sọ̀rọ̀ lójúkojú, gẹ́gẹ́ bí i pé ènìyàn ń bá ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀. Nígbà náà ni Mose yóò tún padà lọ sí ibùdó, ṣùgbọ́n ọ̀dọ́mọkùnrin Joṣua ìránṣẹ́ rẹ̀ ọmọ Nuni kò fi àgọ́ sílẹ̀.

Mose àti ògo Olúwa

12 Mose sọ fún Olúwa pé, “Ìwọ ti ń sọ fún mi, ‘Darí àwọn ènìyàn wọ̀nyí,’ ṣùgbọ́n ìwọ kò jẹ́ kí ń mọ ẹni tí ìwọ yóò rán pẹ̀lú mi. Ìwọ ti wí pé, ‘Èmi mọ̀ ọ́n nípa orúkọ, ìwọ sì ti rí ojúrere mi pẹ̀lú.’ 13 Bí ìwọ bá ní inú dídùn pẹ̀lú mi, kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ, kí èmi kí ó lè mọ̀ ọ́n, kí n sì le máa wá ojúrere rẹ pẹ̀lú. Rántí wí pé orílẹ̀-èdè yìí ènìyàn rẹ ni.”

14 Olúwa dáhùn wí pé, “Ojú mi yóò máa bá ọ lọ, èmi yóò sì fún ọ ní ìsinmi.”

15 Nígbà náà ni, Mose wí fún un pé, “Bí ojú rẹ kò bá bá wa lọ, má ṣe rán wa gòkè láti ìhín lọ. 16 Báwo ni ẹnikẹ́ni yóò ṣe mọ̀ pé inú rẹ dùn pẹ̀lú mi àti pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ àyàfi ti o bá bá wa lọ? Kí ni yóò lè yà mí àti àwọn ènìyàn rẹ kúrò lára gbogbo ènìyàn tí ó wà ní ayé?”

17 Olúwa sì sọ fún Mose pé, “Èmi yóò ṣe ohun gbogbo tí ìwọ ti béèrè, nítorí inú mi dún sí o, èmi sì mọ̀ ọ́n nípa orúkọ rẹ̀.”

18 Mose sì wí pé “Nísinsin yìí fi ògo rẹ hàn mí.”

19 (B)Olúwa sì wí pé, “Èmi yóò sì mú gbogbo ìre mí kọjá níwájú rẹ, Èmi yóò sì pòkìkí orúkọ Olúwa níwájú rẹ. Èmi yóò ṣàánú fún ẹni tí èmi yóò ṣàánú fún, èmi yóò sì ṣoore-ọ̀fẹ́ fún ẹni tí èmi yóò ṣoore-ọ̀fẹ́ fún. 20 Ṣùgbọ́n,” ó wí pé, “Ìwọ kò le è rí ojú mi, nítorí kò sí ènìyàn kan tí ń rí mi, tí ó lè yè.”

21 Olúwa sì wí pé, “Ibìkan wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀dọ̀ mi, níbi tí o ti lè dúró lórí àpáta. 22 Nígbà tí ògo mi bá kọjá, èmi yóò gbé ọ sínú pàlàpálá àpáta, èmi yóò sì bò ọ́ pẹ̀lú ọwọ́ mi títí èmi yóò fi rékọjá. 23 Nígbà tí èmi yóò mú ọwọ́ mi kúrò, ìwọ yóò sì rí ẹ̀yìn mi; ṣùgbọ́n ojú mi ni o kò ní rí.”

Ìṣe àwọn Aposteli 7:30-34

30 (A)“Nígbà tí ogójì ọdún sì pé, angẹli Olúwa fi ara han Mose ní ijù, ní òkè Sinai, nínú ọ̀wọ́-iná nínú igbó. 31 Nígbà tí Mose sì rí i, ẹnu yà á sí ìran náà; nígbà tí ó sì súnmọ́ ọn láti wò ó fín, ohùn Olúwa kọ sí i, 32 Wí pé ‘Èmi ni Ọlọ́run àwọn baba rẹ, Ọlọ́run Abrahamu àti Ọlọ́run Isaaki, àti Ọlọ́run Jakọbu,’ Mose sì wárìrì pẹ̀lú ìbẹ̀rù, kò sì dáṣà láti wò ó mọ́.

33 “Olúwa sì wí fún un pé, ‘bọ́ bàtà rẹ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ, nítorí ibi tí ìwọ dúró sí i nì ilẹ̀ mímọ́ ni. 34 Ní rí rí mo ti rí ìpọ́njú àwọn ènìyàn mi tí ń bẹ ni Ejibiti, mo sì ti gbọ́ ìkérora wọn, Mo sì sọ̀kalẹ̀ wá láti gbà wọ́n. Wá nísinsin yìí, Èmi ó sì rán ọ lọ sí ilẹ̀ Ejibiti.’

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.