Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 119:1-8

119 Ìbùkún ni fún àwọn ẹni tí ọ̀nà wọn wà láìlẹ́ṣẹ̀,
    ẹni tí í rìn ní ìbámu pẹ̀lú òfin Olúwa,
Ìbùkún ni fún àwọn ẹni tí ń pa òfin rẹ̀ mọ́
    tí wọn sì ń wá a pẹ̀lú gbogbo ọkàn wọn.
Wọn kò ṣe ohun tí kò dára;
    wọ́n rìn ní ọ̀nà rẹ̀.
Ìwọ ti la ìlànà rẹ̀ sílẹ̀
    kí a sì pa wọ́n mọ́ gidigidi.
Ọ̀nà mi ìbá dúró ṣinṣin
    láti máa pa òfin rẹ̀ mọ́!
Nígbà náà, ojú kò ní tì mí
    nígbà tí mo bá ń kíyèsi àṣẹ rẹ̀ gbogbo.
Èmi yóò yìn ọ́ pẹ̀lú ọkàn ìdúró ṣinṣin
    bí èmi bá ti kọ́ òfin òdodo rẹ̀.
Èmi yóò gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ̀:
    Má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀ pátápátá.

Deuteronomi 30:1-9

Àlàáfíà lẹ́yìn ìyípadà sí Ọlọ́run

30 Nígbà tí gbogbo ìbùkún àti ègún wọ̀nyí tí mo ti gbé kalẹ̀ síwájú u yín bá wá sórí i yín àti tí o bá mú wọn sí àyà rẹ níbikíbi tí Olúwa Ọlọ́run rẹ bá tú ọ ká sí láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, àti nígbà tí ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ bá yípadà sí Olúwa Ọlọ́run rẹ tí o sì gbọ́rọ̀ sí pẹ̀lú gbogbo àyà rẹ àti gbogbo ọkàn rẹ gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí mo ti paláṣẹ fún un yín lónìí. Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò mú ohun ìní rẹ bọ̀ sípò yóò sì ṣàánú fún ọ, yóò sì tún ṣà yín jọ láti gbogbo orílẹ̀-èdè níbi tí ó ti fọ́n yín ká sí. (A)Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti lé ẹni rẹ kan sí ilẹ̀ tí ó jìnnà jù lábẹ́ ọ̀run, láti ibẹ̀ Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò ṣà yín jọ yóò sì tún mú u yín padà. Yóò mú ọ wá sí ilẹ̀ tí ó jẹ́ ti àwọn baba yín, ìwọ yóò sì mú ìní níbẹ̀. Olúwa yóò mú ọ wà ní àlàáfíà kíkún, yóò mú ọ pọ̀ sí i ju àwọn baba yín lọ. Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò kọ ọkàn rẹ ní ilà àti ọkàn àwọn ọmọ yín, nítorí kí o lè fẹ́ ẹ pẹ̀lú gbogbo àyà rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ, àti ayé rẹ. Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò mú gbogbo ègún yín wá sórí àwọn ọ̀tá à rẹ tí wọ́n kórìíra àti tí wọ́n ṣe inúnibíni rẹ. Ìwọ yóò tún gbọ́rọ̀ sí Olúwa àti tẹ̀lé gbogbo àṣẹ rẹ̀ tí mò ń fún ọ lónìí. Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò mú ọ ṣe rere nínú gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ ọ̀ rẹ, àti nínú gbogbo ọmọ inú rẹ, agbo ẹran ọ̀sìn rẹ àti èso ilẹ̀ rẹ. Olúwa yóò tún mú inú dídùn sínú rẹ yóò sì mú ọ ṣe déédé, gẹ́gẹ́ bí ó ti fi inú dídùn sínú àwọn baba rẹ.

Matiu 15:1-9

Ohun mímọ́ àti ohun àìmọ́

15 (A)Nígbà náà ní àwọn Farisi àti àwọn olùkọ́ òfin tọ Jesu wá láti Jerusalẹmu, wọn béèrè pé, “Èéṣe tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ fi ń rú òfin àtayébáyé àwọn alàgbà? Nítorí tí wọn kò wẹ ọwọ́ wọn kí wọ́n tó jẹun!”

Jesu sì dá wọn lóhùn pé, “Èéha ṣe tí ẹ̀yin fi rú òfin Ọlọ́run, nítorí àṣà yín? Nítorí Ọlọ́run wí pé, ‘Bọ̀wọ̀ fún Baba òun ìyá rẹ,’ àti pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ ọ̀rọ̀-òdì sí baba tàbí ìyá rẹ̀, ní láti kú.’ Ṣùgbọ́n ẹ̀yin wí pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá wí fún baba tàbí ìyá rẹ̀ pé, ‘Ẹ̀bùn fún Ọlọ́run ni ohunkóhun tí ìwọ ìbá fi jèrè lára mi;’ Tí Òun kò sì bọ̀wọ̀ fún baba tàbí ìyá rẹ̀, ó bọ́; bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin sọ òfin Ọlọ́run di asán nípa àṣà yín. Ẹ̀yin àgàbàgebè, ní òtítọ́ ni Wòlíì Isaiah sọtẹ́lẹ̀ nípa yín wí pé:

(B)“ ‘Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ń fi ẹnu lásán bu ọlá fún mi,
    ṣùgbọ́n ọkàn wọn jìnnà réré sí mi.
Lásán ni ìsìn wọn;
    nítorí pé wọ́n ń fi òfin ènìyàn kọ́ ni ní ẹ̀kọ́.’ ”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.