Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Isaiah 58:1-9

Àwẹ̀ tòótọ́

58 “Kígbe rẹ̀ sókè, má ṣe fàsẹ́yìn.
    Gbé ohùn rẹ sókè bí i ti fèrè.
Jẹ́ kí ó di mí mọ̀ fún àwọn ènìyàn mi, ọ̀tẹ̀ wọn
    àti fún ilé Jakọbu ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
Nítorí ọjọ́ dé ọjọ́ ni wọ́n ń wá mi kiri;
    wọ́n ṣe bí ẹni ní ìtara láti mọ ọ̀nà mi,
àfi bí ẹni pé wọ́n jẹ́ orílẹ̀-èdè kan tí ń ṣe ohun tí ó tọ̀nà
    tí òun kò sì tí ì kọ àṣẹ Ọlọ́run rẹ̀.
Wọ́n ń béèrè lọ́wọ́ mi fún ìpinnu nìkan
    wọ́n sì ṣe bí ẹni ń tara fún Ọlọ́run láti súnmọ́ ọ̀dọ̀ wọn.
‘Èéṣe tí àwa fi ń gbààwẹ̀,’ ni wọ́n wí,
    ‘tí ìwọ kò sì tí ì rí?
Èéṣe tí àwa fi rẹra wa sílẹ̀,
    tí ìwọ kò sì tí ì ṣe àkíyèsí?’

“Síbẹ̀síbẹ̀ ní ọjọ́ àwẹ̀ yín, ẹ̀yin ń ṣe bí ó ti wù yín
    ẹ sì ń pọ́n àwọn òṣìṣẹ́ yín gbogbo lójú.
Àwẹ̀ yín sì parí nínú ìjà àti asọ̀,
    àti lílu ọmọnìkejì ẹni pa pẹ̀lú ìkùùkuu.
Ẹ̀yin kò le è gbààwẹ̀ bí ẹ ti ń ṣe lónìí
    kí ẹ sì retí kí a gbọ́ ohùn un yín ní ibi gíga.
Ǹjẹ́ èyí ha ni irú àwẹ̀ tí mo yàn bí,
    ọjọ́ kan ṣoṣo fún ènìyàn láti rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀?
Ó ha jẹ pe kí ènìyàn tẹ orí rẹ̀ ba bí i koríko lásán ni bí
    àti sísùn nínú aṣọ ọ̀fọ̀ àti eérú?
Ṣé ohun tí ẹ̀ ń pè ní àwẹ̀ nìyí,
    ọjọ́ ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa?

(A)“Ǹjẹ́ irú àwẹ̀ tí mo ti yàn kọ́ ni èyí:
    láti já gbogbo ẹ̀wọ̀n àìṣòdodo
àti láti tú gbogbo okùn àjàgà,
    láti tú gbogbo àwọn ti à ń ni lára sílẹ̀
    àti láti fọ́ gbogbo àjàgà?
Kì í ha á ṣe láti pín oúnjẹ yín fún àwọn tí ebi ń pa
    àti láti pèsè ibùgbé fún àwọn òtòṣì tí ń rìn káàkiri.
Nígbà tí ẹ bá rí ẹni tí ó wà níhòhò, láti daṣọ bò ó,
    àti láti má ṣe lé àwọn ìbátan yín sẹ́yìn?
Nígbà náà ni ìmọ́lẹ̀ rẹ yóò tàn jáde bí òwúrọ̀
    àti ìmúláradá rẹ yóò farahàn kíákíá;
nígbà náà ni òdodo rẹ yóò sì lọ níwájú rẹ,
    ògo Olúwa yóò sì jẹ́ ààbò lẹ́yìn rẹ.
Nígbà yìí ni ẹ̀yin yóò pè, tí Olúwa yóò sì dáhùn;
    ẹ̀yin yóò kígbe fún ìrànlọ́wọ́, òun yóò sì wí pé: Èmi nìyí.

“Bí ìwọ bá mú àjàgà aninilára,
    nínà ìka àlébù àti sísọ ọ̀rọ̀ asán kúrò láàrín rẹ,

Isaiah 58:9-12

Nígbà yìí ni ẹ̀yin yóò pè, tí Olúwa yóò sì dáhùn;
    ẹ̀yin yóò kígbe fún ìrànlọ́wọ́, òun yóò sì wí pé: Èmi nìyí.

“Bí ìwọ bá mú àjàgà aninilára,
    nínà ìka àlébù àti sísọ ọ̀rọ̀ asán kúrò láàrín rẹ,
10 àti bí ẹ̀yin bá ná ara yín bí owó nítorí àwọn tí ebi ń pa
    tí ẹ sì tẹ́ ìfẹ́ àwọn tí à ń ni lára lọ́rùn,
nígbà náà ni ìmọ́lẹ̀ yín yóò ràn nínú òkùnkùn,
    àti òru yín yóò dàbí ọ̀sán gangan.
11 Olúwa yóò máa tọ́ ọ yín nígbà gbogbo;
    òun yóò tẹ́ gbogbo àìní yín lọ́rùn ní ilẹ̀ tí oòrùn ń tan ìmọ́lẹ̀
yóò sì fún egungun rẹ lókun.
    Ìwọ yóò sì dàbí ọgbà tí a bomirin dáradára,
    àti bí orísun tí omi rẹ̀ kì í gbẹ.
12 Àwọn ènìyàn rẹ yóò tún ahoro àtijọ́ kọ́
    wọn yóò sì gbé ìpìlẹ̀ àtijọ́-tijọ́ ró
a ó sì pè ọ́ ní alátúnṣe ògiri tí ó ti wó
    àti olùmúbọ̀sípò àwọn òpópónà tí ènìyàn gbé inú rẹ̀.

Saamu 112:1-9

112 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run,
    tí ó ní inú dídùn ńlá sí àwọn òfin rẹ̀.

Irú-ọmọ rẹ̀ yóò jẹ́ alágbára ní ayé:
    ìran àwọn olóòtítọ́ ni a ó bùkún fún.
Ọlá àti ọrọ̀ yóò wà nínú ilé rẹ̀;
    òdodo rẹ̀ sì dúró láé.
Fún olóòótọ́ ni ìmọ́lẹ̀ yóò tàn fún ní òkùnkùn:
    olóore-ọ̀fẹ́ àti aláàánú àti òdodo.
Ènìyàn rere fi ojúrere hàn,
    a sì wínni;
    ìmòye ni yóò máa fi la ọ̀nà iṣẹ́ rẹ̀.

Dájúdájú a kì yóò le yí ní ipò padà láéláé:
    olódodo ni a ó máa ṣe ìrántí rẹ láéláé.
Òun kì yóò béèrè ìyìn búburú:
    ọkàn rẹ̀ ti dúró, ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa.
Ó ti mú ọkàn rẹ̀ gbilẹ̀, ẹ̀rù kí yóò bà á,
    títí yóò fi rí ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀.
(A)Ó ti pín ká, ó ti fi fún àwọn olùpọ́njú;
    Nítorí òdodo rẹ̀ dúró láé;
    ìwo rẹ̀ ní a ó gbé sókè pẹ̀lú ọlá.

Saamu 112:10

10 Ènìyàn búburú yóò ri, inú wọn yóò sì bàjẹ́,
    yóò sì pa eyín keke, yó sì yọ dànù:
    èròǹgbà ọkàn ènìyàn búburú ni yóò ṣègbé.

1 Kọrinti 2:1-12

(A)Nígba tí èmí tọ̀ yín wá, ẹ̀yin ará, kì í ṣe nípa ọ̀rọ̀ gíga àti ọgbọ́n gíga ni mo fi bá yín sọ̀rọ̀, nígbà tí èmi ń sọ̀rọ̀ ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run fún un yín. (B)Èmi ti pinnu láti má mọ ohunkóhun nígbà ti mo wà láàrín yín bí kò ṣe Jesu Kristi, ẹni tí a kàn mọ́ àgbélébùú. (C)Èmi sì tọ̀ yín wá ni àìlera, àti ní ẹ̀rù, àti ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwárìrì. (D)Ìwàásù mi àti ẹ̀kọ́ mi, kì í ṣe nípa ọgbọ́n ènìyàn àti ọ̀rọ̀ tí a fi ń yí ènìyàn lọ́kàn padà, bí kò ṣe nípa ìfihàn agbára Ẹ̀mí. (E)Kí ìgbàgbọ́ yín kí ó má ṣe dúró lórí ọgbọ́n ènìyàn, ṣùgbọ́n kí ó dúró lórí agbára Ọlọ́run.

Ọgbọ́n láti ọ̀dọ̀ ẹ̀mí wá

(F)Ṣùgbọ́n àwa ń sọ̀rọ̀ ọgbọ́n láàrín àwọn tí a pè; ṣùgbọ́n kì í ṣe ọgbọ́n ti ayé yìí tàbí ti àwọn olórí ayé yìí, èyí tí yóò di asán (G)Bẹ́ẹ̀ kọ́, àwa ń sọ̀rọ̀ ọgbọ́n ti Ọlọ́run tó fi ara sin, ọgbọ́n tí ó ti fi ara pamọ́, èyí tí Ọlọ́run ti lànà sílẹ̀ ṣáájú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé fún ògo wa. (H)Èyí ti ẹnikẹ́ni nínú àwọn aláṣẹ ayé yìí kò mọ̀. Ìbá ṣe pé wọ́n mọ̀ ọ́n, wọn kì bá tún kan Olúwa ògo mọ́ àgbélébùú. (I)Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé:

“Ojú kò tí ì rí,
    etí kò tí í gbọ́,
kò sì ọkàn ènìyàn tí ó tí í mọ̀
ohun tí Ọlọ́run tí pèsè sílẹ̀ fún àwọn tí o fẹ́ Ẹ.”

10 (J)Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti fi í hàn fún wa nípasẹ̀ Ẹ̀mí rẹ̀.

Ẹ̀mí á máa wádìí ohun gbogbo, kódà àwọn àṣírí Ọlọ́run tó jinlẹ̀ jùlọ. 11 Ta ni nínú ènìyàn tí ó mọ èrò ọkàn ènìyàn kan, bí kò ṣe ẹ̀mí ènìyàn tí ó wà nínú rẹ̀? Bákan náà, kò sí ẹni ti ó mọ àwọn èrò Ọlọ́run, bí kò ṣe Ẹ̀mí Ọlọ́run fúnrarẹ̀. 12 (K)Àwa kò gbà ẹ̀mí ti ayé yìí, bí kò ṣe Ẹ̀mí ẹni tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wa, kí a lè ní òye ohun tí Ọlọ́run fi fún wa lọ́fẹ̀ẹ́.

1 Kọrinti 2:13-16

13 (A)Èyí ni àwa ń wí, kì í ṣe èyí tí a ń kọ nípa ọ̀rọ̀ ọgbọ́n ènìyàn, ṣùgbọ́n èyí tí Ẹ̀mí Mímọ́ fi ń kọ ènìyàn, èyí tí a ń fi ohun Ẹ̀mí wé ohun Ẹ̀mí. 14 (B)Ṣùgbọ́n ènìyàn nípa ti ara kò gba ohun ti Ẹ̀mí Ọlọ́run wọ̀n-ọ́n-nì, nítorí pé wèrè ni wọ́n jásí fún un, òun kò sì le mọ̀ wọ́n, nítorí nípa tí Ẹ̀mí ní a fi ń wádìí wọn. 15 (C)Ṣùgbọ́n ẹni tí ó wà nípa ti ẹ̀mí ń wádìí ohun gbogbo, ṣùgbọ́n kò sí ẹnikẹ́ni tí í wádìí rẹ̀.

16 (D)“Nítorí ta ni ó mọ ọkàn Olúwa,
    ti yóò fi máa kọ́ Ọ?”

Ṣùgbọ́n àwa ní inú Kristi.

Matiu 5:13-20

Iyọ̀ àti ìmọ́lẹ̀

13 (A)“Ẹ̀yin ni iyọ̀ ayé. Ṣùgbọ́n bí iyọ̀ bá di òbu kí ni a ó fi mú un dùn? Kò tún wúlò fún ohunkóhun mọ́, bí kò ṣe pé kí a dàánù, kí ó sì di ohun tí ènìyàn ń fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀.

14 (B)“Ẹyin ni ìmọ́lẹ̀ ayé. Ìlú tí a tẹ̀dó sórí òkè kò lè fi ara sin. 15 (C)Bẹ́ẹ̀ ni a kì í tan fìtílà tán, kí a sì gbé e sí abẹ́ òṣùwọ̀n; bí kò ṣe sí orí ọ̀pá fìtílà, a sì tan ìmọ́lẹ̀ fún gbogbo ẹni tí ń bẹ nínú ilé. 16 Bákan náà, ẹ jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ yín kí ó mọ́lẹ̀ níwájú ènìyàn, kí wọ́n lè máa rí iṣẹ́ rere yín, kí wọn lè máa yin baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run lógo.

Ìmúṣẹ òfin

17 “Ẹ má ṣe rò pé, èmí wá láti pa òfin àwọn wòlíì run, èmi kò wá láti pa wọn rẹ́, bí kò ṣe láti mú wọn ṣẹ. 18 (D)Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, títí ọ̀run òun ayé yóò fi kọjá, ààmì kínkínní tí a fi gègé ṣe kan kì yóò parẹ́ kúrò nínú gbogbo òfin tó wà nínú ìwé òfin títí gbogbo rẹ̀ yóò fi wá sí ìmúṣẹ. 19 (E)Ẹnikẹ́ni ti ó bá rú òfin tí ó tilẹ̀ kéré jùlọ, tí ó sì kọ́ ẹlòmíràn láti ṣe bẹ́ẹ̀, òun ni yóò kéré jùlọ ní ìjọba ọ̀run, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe wọ́n, tí ó sì ń kọ́ wọn, ni yóò jẹ́ ẹni ńlá ní ìjọba ọ̀run. 20 Nítorí náà ni mo ti wí fún yín pé àfi bí òdodo yín bá ju ti àwọn Farisi àti ti àwọn olùkọ́ òfin lọ, dájúdájú ẹ̀yin kì yóò le wọ ìjọba ọ̀run.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.