Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
112 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run,
tí ó ní inú dídùn ńlá sí àwọn òfin rẹ̀.
2 Irú-ọmọ rẹ̀ yóò jẹ́ alágbára ní ayé:
ìran àwọn olóòtítọ́ ni a ó bùkún fún.
3 Ọlá àti ọrọ̀ yóò wà nínú ilé rẹ̀;
òdodo rẹ̀ sì dúró láé.
4 Fún olóòótọ́ ni ìmọ́lẹ̀ yóò tàn fún ní òkùnkùn:
olóore-ọ̀fẹ́ àti aláàánú àti òdodo.
5 Ènìyàn rere fi ojúrere hàn,
a sì wínni;
ìmòye ni yóò máa fi la ọ̀nà iṣẹ́ rẹ̀.
6 Dájúdájú a kì yóò le yí ní ipò padà láéláé:
olódodo ni a ó máa ṣe ìrántí rẹ láéláé.
7 Òun kì yóò béèrè ìyìn búburú:
ọkàn rẹ̀ ti dúró, ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa.
8 Ó ti mú ọkàn rẹ̀ gbilẹ̀, ẹ̀rù kí yóò bà á,
títí yóò fi rí ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀.
9 (A)Ó ti pín ká, ó ti fi fún àwọn olùpọ́njú;
Nítorí òdodo rẹ̀ dúró láé;
ìwo rẹ̀ ní a ó gbé sókè pẹ̀lú ọlá.
10 Ènìyàn búburú yóò ri, inú wọn yóò sì bàjẹ́,
yóò sì pa eyín keke, yó sì yọ dànù:
èròǹgbà ọkàn ènìyàn búburú ni yóò ṣègbé.
13 (A)Olúwa wí pé:
“Àwọn ènìyàn yìí súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi pẹ̀lú ẹnu wọn,
wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún mi pẹ̀lú ètè wọn,
ṣùgbọ́n ọkàn wọn jìnnà sí mi.
Ìsìn wọn si mi
ni a gbé ka orí òfin tí àwọn
ọkùnrin kọ́ ni.
14 (B)Nítorí náà lẹ́ẹ̀kan sí i èmi yóò ya
àwọn ènìyàn yìí lẹ́nu
pẹ̀lú ìyanu lórí ìyanu;
ọgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n ni yóò ṣègbé,
ìmọ̀ àwọn onímọ̀ ni yóò pòórá.”
15 Ègbé ni fún àwọn tí ó lọ sí ọ̀gbun
láti fi ètò wọn pamọ́ kúrò lójú Olúwa,
tí wọ́n ń ṣe iṣẹ́ ẹ wọn nínú òkùnkùn
tí wọ́n sì rò pé,
“Ta ló rí wa? Ta ni yóò mọ̀?”
16 (C)Ẹ̀yin dojú nǹkan délẹ̀,
bí ẹni pé wọ́n rò pé amọ̀kòkò dàbí amọ̀!
Ǹjẹ́ ohun tí a ṣe le sọ fún olùṣe pé
“Òun kọ́ ló ṣe mí”?
Ǹjẹ́ ìkòkò lè sọ nípa amọ̀kòkò pé,
“kò mọ nǹkan”?
Mímọ́ àti àìmọ́
7 (A)Àwọn Farisi sì péjọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, àti àwọn kan nínú àwọn akọ̀wé, tí ó wá láti Jerusalẹmu, 2 wọ́n sì ṣe àkíyèsí wí pé díẹ̀ nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu ń fi ọwọ́ àìmọ́ jẹun, èyí yìí ni wẹ ọwọ́. 3 (Àwọn Farisi, àti gbogbo àwọn Júù, bí wọ́n kò bá wẹ ọwọ́ wọn gidigidi, wọn kì í jẹun nítorí wọ́n ti pa òfin àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn àgbà mọ́. 4 (B)Nígbà tí wọ́n bá sì ti ọjà dé sílé, wọn kò gbọdọ̀ fi ọwọ́ kan oúnjẹ àfi tí wọ́n bá bu omi wẹ ara wọn. Èyí sì jẹ́ ọ̀kan nínú ogunlọ́gọ̀ àpẹẹrẹ òfin àti ìlànà tí wọ́n ti dì mú fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn, bí i fífọ kọ́ọ̀bù, àwọn ìkòkò, àti kẹ́tù.)
5 (C)Nítorí èyí àwọn Farisi àti àwọn olùkọ́ òfin béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Èéṣe tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kò tẹ̀lé àwọn òfin àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn àgbà nítorí wọ́n fi ọwọ́ àìmọ́ jẹun.”
6 (D)Jesu dá wọn lóhùn wí pé, “Ẹyin àgàbàgebè yìí, òtítọ́ ni wòlíì Isaiah ń sọtẹ́lẹ̀ nípa tí ẹ̀yin àgàbàgebè, bí a ti kọ ọ́ pé:
“ ‘Àwọn ènìyàn wọ̀nyí fi ẹnu wọn bu ọlá fún mi
ṣùgbọ́n ọkàn wọn jìnà sí mi.
7 Ìsìn wọn jẹ́ lásán,
ìkọ́ni wọ́n jẹ́ kìkìdá òfin tí àwọn ènìyàn fi ń kọ́ni.’
8 Nítorí tí ẹ̀yin fi òfin Ọlọ́run sí apá kan, ẹ̀yin ń tẹ̀lé àṣà àwọn ènìyàn.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.