Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 112:1-9

112 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run,
    tí ó ní inú dídùn ńlá sí àwọn òfin rẹ̀.

Irú-ọmọ rẹ̀ yóò jẹ́ alágbára ní ayé:
    ìran àwọn olóòtítọ́ ni a ó bùkún fún.
Ọlá àti ọrọ̀ yóò wà nínú ilé rẹ̀;
    òdodo rẹ̀ sì dúró láé.
Fún olóòótọ́ ni ìmọ́lẹ̀ yóò tàn fún ní òkùnkùn:
    olóore-ọ̀fẹ́ àti aláàánú àti òdodo.
Ènìyàn rere fi ojúrere hàn,
    a sì wínni;
    ìmòye ni yóò máa fi la ọ̀nà iṣẹ́ rẹ̀.

Dájúdájú a kì yóò le yí ní ipò padà láéláé:
    olódodo ni a ó máa ṣe ìrántí rẹ láéláé.
Òun kì yóò béèrè ìyìn búburú:
    ọkàn rẹ̀ ti dúró, ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa.
Ó ti mú ọkàn rẹ̀ gbilẹ̀, ẹ̀rù kí yóò bà á,
    títí yóò fi rí ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀.
(A)Ó ti pín ká, ó ti fi fún àwọn olùpọ́njú;
    Nítorí òdodo rẹ̀ dúró láé;
    ìwo rẹ̀ ní a ó gbé sókè pẹ̀lú ọlá.

Saamu 112:10

10 Ènìyàn búburú yóò ri, inú wọn yóò sì bàjẹ́,
    yóò sì pa eyín keke, yó sì yọ dànù:
    èròǹgbà ọkàn ènìyàn búburú ni yóò ṣègbé.

Isaiah 29:1-12

Ègbé ni fún ìlú Dafidi

29 Ègbé ni fún ọ, Arieli, Arieli,
    ìlú níbi tí Dafidi tẹ̀dó sí!
Fi ọdún kún ọdún
    sì jẹ́ kí àwọn àkọlùkọgbà àjọ̀dún un rẹ tẹ̀síwájú.
Síbẹ̀síbẹ̀ èmi yóò dó ti Arieli
    òun yóò ṣọ̀fọ̀ yóò sì sọkún,
    òun yóò sì dàbí pẹpẹ ọkàn sí mi.
Èmi yóò sì wà ní bùba yí ọ ká níbi gbogbo;
    Èmi yóò sì fi ilé ìṣọ́ yí ọ ká:
    èmi yóò sì fi iṣẹ́ ìdó ti ni mi dojúkọ ọ́.
Ní ìrẹ̀sílẹ̀, ìwọ ó sì máa sọ̀rọ̀ láti ilẹ̀ wá;
    ọ̀rọ̀ rẹ yóò sì máa kùn jáde láti inú erùpẹ̀.
Ohun rẹ yóò máa jáde bí i ti ẹnìkan tó ní ẹ̀mí àfọ̀ṣẹ láti ilẹ̀ jáde wá,
    láti inú erùpẹ̀ ni ohùn rẹ
    yóò máa wá wúyẹ́wúyẹ́.

Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀tá rẹ, yóò dàbí yanrìn kíkúnná,
    agbo àwọn aláìláàánú bí ìyàngbò tí a fẹ́ dànù.
    Lójijì, ní ìṣẹ́jú kan,
Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò wá
    pẹ̀lú àrá, ilẹ̀-rírì àti ariwo ńlá
àti ẹ̀fúùfù líle àti iná ajónirun
    Lẹ́yìn náà,
    ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ènìyàn tí gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó bá Arieli jà,
tí ó dojú ìjà kọ òun àti ilé olódi rẹ̀
    tí ó sì dó tì í,
yóò dàbí ẹni pé nínú àlá,
    bí ìran ní òru
àti bí ìgbà tí ẹni tí ebi ń pa ń lá àlá pé òun ń jẹun,
    ṣùgbọ́n ó jí, ebi rẹ̀ sì wà pẹ̀lú rẹ̀;
tàbí bí ìgbà tí ẹni tí òǹgbẹ ń gbẹ lá àlá pé òun ń mu omi,
    ṣùgbọ́n nígbà tí ó jí, sì wò ó, ó dákú, òǹgbẹ sì ń gbẹ ọkàn rẹ̀.
Bẹ́ẹ̀ ni yóò sì rí fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè
    tí ń bá òkè Sioni jà.

Ẹ bẹ̀rù kí ẹnu kí ó yà yín,
    ẹ fọ́ ara yín lójú kí ẹ má sì ríran;
ẹ mutí yó kì í ṣe ọtí wáìnì,
    ẹ ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n, ṣùgbọ́n kì í ṣe ti ọtí líle.
10 Olúwa ti mú oorun ìjìká wá sórí i yín:
    ó ti dì yín lójú ẹ̀yin wòlíì;
    ó ti bo orí yín ẹ̀yin aríran.

11 Fún un yín gbogbo ìran yìí kò yàtọ̀ sí àwọn ọ̀rọ̀ tí a fi èdìdì dì sínú ìwé kíká. Bí ẹ bá sì fún ẹni tí ó lè ka ìwé kíká náà, tí ẹ sì sọ fún un pé, “Jọ̀wọ́ ka èyí,” òun yóò dáhùn pé, “Èmi kò lè kà á; a ti dì í ní èdìdì.” 12 Tàbí bí ẹ bá fún ẹni tí kò lè ka ìwé kíká náà tí ẹ sì sọ pé, “Jọ̀wọ́ ka èyí,” òun yóò dáhùn pé, “Èmi kò mọ̀ ọ́n kà.”

Jakọbu 3:13-18

Oríṣìí ọgbọ́n méjì

13 Ta ni ó gbọ́n tí ó sì ní ìmọ̀ nínú yín? Ẹ jẹ́ kí ó fi iṣẹ́ rẹ̀ hàn nípa ìwà rere, nípa ìwà tútù ti ọgbọ́n. 14 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá ní owú kíkorò àti ìjà ní ọkàn yín, ẹ má ṣe ṣe féfé, ẹ má sì ṣèké sí òtítọ́. 15 Ọgbọ́n yìí kì í ṣe èyí tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, ṣùgbọ́n ti ayé ni, ti ara ni, ti ẹ̀mí èṣù ni. 16 Nítorí níbi tí owú òun ìjà bá gbé wà, níbẹ̀ ni rúdurùdu àti iṣẹ́ búburú gbogbo wà.

17 Ṣùgbọ́n ọgbọ́n tí ó ti òkè wá jẹ́ mímọ́ ní àkọ́kọ́, ti àlàáfíà, àti ti ìrẹ̀lẹ̀, kì í sì í ṣòro láti bẹ̀, ó kún fún àánú àti fún èso rere, kì í ṣe ojúsàájú, a sì máa sọ òtítọ́. 18 Àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ àlàáfíà a sì máa gbin èso àlàáfíà ní àlàáfíà.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.