Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Saamu ti Dafidi
15 Olúwa, ta ni yóò máa ṣe àtìpó nínú àgọ́ rẹ?
Ta ni yóò máa gbé ní òkè mímọ́ rẹ?
2 Ẹni tí ń rìn déédé
tí ó sì ń sọ òtítọ́,
láti inú ọkàn rẹ̀;
3 tí kò fi ahọ́n rẹ̀ sọ̀rọ̀ ẹni lẹ́yìn,
tí kò ṣe ibi sí aládùúgbò rẹ̀
tí kò sì sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí ẹnìkejì rẹ̀,
4 ní ojú ẹni tí ènìyànkénìyàn di gígàn
ṣùgbọ́n ó bọ̀wọ̀ fún àwọn tí ó bẹ̀rù Olúwa,
Ẹni tí ó búra sí ibi ara rẹ̀
àní tí kò sì yípadà,
5 tí ó ń yá ni lówó láìsí èlé
tí kò sì gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lòdì sí aláìlẹ́ṣẹ̀.
Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe èyí
ni a kì yóò mì láéláé.
Bíbá àwọn olórí àti àwọn wòlíì wí
3 Nígbà náà, ni mo wí pé,
“Ẹ gbọ́, ẹ̀yin olórí Jakọbu,
ẹ̀yin alákòóso ilé Israẹli.
Ǹjẹ́ ẹ̀yin kò ha ni í gba òdodo bí.
2 Ẹ̀yin tí ó kórìíra ìre, tí ẹ sì fẹ́ràn ibi;
Ẹ̀yin tí ẹ fa awọ ẹran-ara àwọn ènìyàn mi ya kúrò lára wọn
àti ẹran-ara wọn kúrò ní egungun wọn;
3 Àwọn tí ó jẹ ẹran-ara àwọn ènìyàn mi,
wọn sì bọ́ awọ ara wọn kúrò lára wọn.
Wọ́n sì fọ́ egungun wọn sí wẹ́wẹ́;
Wọn sì gé e sí wẹ́wẹ́ bí ẹran inú ìkòkò,
bí ẹran inú agbada?”
4 Nígbà náà ni wọn yóò kígbe sí Olúwa,
Ṣùgbọ́n òun kì yóò dá wọn lóhùn.
Ní àkókò náà ni òun yóò fi ojú rẹ̀ pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ wọn,
nítorí ibi tí wọ́n ti ṣe.
Jesu sọtẹ́lẹ̀ pé Peteru yóò sẹ́ òun
31 (A)Nítorí náà nígbà tí ó jáde lọ tan, Jesu wí pé, “Nísinsin yìí ni a yin Ọmọ ènìyàn lógo, a sì yin Ọlọ́run lógo nínú rẹ̀. 32 Bí a bá yin Ọlọ́run lógo nínú rẹ̀, Ọlọ́run yóò sì yìn ín lógo nínú òun tìkára rẹ̀, yóò sì yìn ín lógo nísinsin yìí.
33 (B)“Ẹ̀yin ọmọ mi, nígbà díẹ̀ sí i ni èmi wà pẹ̀lú yín. Ẹ̀yin yóò wá mi: àti gẹ́gẹ́ bí mo ti wí fún àwọn Júù pé, Níbi tí èmi gbé ń lọ, ẹ̀yin kì yóò le wà; bẹ́ẹ̀ ni mo sì wí fún yín nísinsin yìí.
34 (C)“Òfin tuntun kan ni mo fi fún yín, kí ẹ̀yin kí ó fẹ́ ọmọnìkejì yín; gẹ́gẹ́ bí èmi ti fẹ́ràn yín, kí ẹ̀yin kí ó sì fẹ́ràn ọmọnìkejì yín. 35 Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé, ọmọ-ẹ̀yìn mi ni ẹ̀yin ń ṣe, nígbà tí ẹ̀yin bá ní ìfẹ́ sí ọmọ ẹnìkejì yín.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.