Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Ti Solomoni
72 Fi ìdájọ́ fún àwọn ọba, Ọlọ́run,
ọmọ-aládé ni ìwọ fi òdodo rẹ fún
2 Yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú òdodo,
yóò sì máa fi ẹ̀tọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn tálákà rẹ̀.
3 Àwọn òkè ńlá yóò máa mú àlàáfíà fún àwọn ènìyàn
àti òkè kéékèèkéé nípa òdodo
4 Yóò dáàbò bo àwọn tí a pọ́n lójú láàrín àwọn ènìyàn
yóò gba àwọn ọmọ aláìní;
yóò sì fa àwọn aninilára ya.
5 Àwọn òtòṣì àti aláìní
yóò máa fi ọ̀wọ̀ ńlá fún ọ nígbà gbogbo,
níwọ̀n ìgbà tí oòrùn àti òṣùpá bá ń ràn,
yóò ti pẹ́ tó, láti ìrandíran.
6 Yóò dàbí òjò tí ó ń rọ̀ sórí pápá ìrẹ́mọ́lẹ̀
Bí ọwọ́ òjò tó ń rin ilẹ̀
7 Àwọn olódodo yóò gbilẹ̀ ni ọjọ́ rẹ̀
ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà yóò sì wà;
títí tí òṣùpá kò fi ní sí mọ́.
8 Yóò máa jẹ ọba láti Òkun dé Òkun
àti láti odò Eufurate títí dé òpin ayé.
9 Àwọn tí ó wà ní aginjù yóò tẹríba fún un
àwọn ọ̀tá rẹ̀ yóò máa lá erùpẹ̀ ilẹ̀.
10 Àwọn ọba Tarṣiṣi àti ti erékùṣù
wọn yóò mú ọrẹ wá fún un;
àwọn ọba Ṣeba àti Seba
wọn ó mú ẹ̀bùn wá fún un.
11 Gbogbo ọba yóò tẹríba fún un
àti gbogbo orílẹ̀-èdè yóò sìn ín.
12 Nítorí yóò gba àwọn aláìní
nígbà tí ó bá ń ké,
tálákà àti ẹni tí kò ní olùrànlọ́wọ́.
13 Yóò káàánú àwọn aláìlera àti aláìní
yóò pa aláìní mọ́ kúrò nínú ikú.
14 Yóò ra ọkàn wọn padà lọ́wọ́ ẹ̀tàn àti ipá
nítorí ẹ̀jẹ̀ wọn ṣọ̀wọ́n níwájú rẹ̀.
15 Yóò sì pẹ́ ní ayé!
A ó sì fún un ní wúrà Ṣeba.
Àwọn ènìyàn yóò sì máa gbàdúrà fún un nígbà gbogbo
kí a sì bùkún fún un lójoojúmọ́.
16 Kí ìkúnwọ́ ọkà wà lórí ilẹ̀;
ní orí òkè ni kí ó máa dàgbà
kí èso rẹ̀ kí o gbilẹ̀ bí ti Lebanoni
yóò máa gbá yìn bí i koríko ilẹ̀.
17 Kí orúkọ rẹ̀ kí ó wà títí láé;
orúkọ rẹ̀ yóò máa gbilẹ̀ níwọ̀n bí oòrùn yóò ti pẹ́ tó.
Wọn ó sì máa bùkún fún ara wọn nípasẹ̀ rẹ.
Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ní yóò máa pè mí ní alábùkún fún.
18 Olùbùkún ni Olúwa Ọlọ́run, Ọlọ́run Israẹli,
ẹnìkan ṣoṣo tí ó ń ṣe ohun ìyanu.
19 Olùbùkún ni orúkọ rẹ̀ tí ó lógo títí láé;
kí gbogbo ayé kún fún ògo rẹ̀.
Àmín àti Àmín.
20 Èyí ni ìparí àdúrà Dafidi ọmọ Jese.
Àlá Jakọbu ní Beteli
10 Jakọbu kúrò ní Beerṣeba, ó sì kọrí sí ìlú Harani. 11 Nígbà tí ó dé ibìkan, ó dúró ní òru náà nítorí tí ilẹ̀ ti ń ṣú, ó sì gbé òkúta kan ó fi ṣe ìrọ̀rí, ó sì sùn. 12 (A)Ó sì lá àlá pé, a gbé àkàsọ̀ kan dúró ti ó fi ìdí lélẹ̀, orí rẹ̀ sì kan ọ̀run, àwọn angẹli Ọlọ́run sì ń gòkè, wọ́n sì ń sọ̀kalẹ̀ lórí rẹ̀. 13 (B)Olúwa sì dúró lókè rẹ̀, ó sì wí pé, “Èmi ni Olúwa, Ọlọ́run baba rẹ Abrahamu àti Ọlọ́run Isaaki, ìwọ àti ìran rẹ ni èmi yóò fi ilẹ̀ tí ìwọ dùbúlẹ̀ sórí rẹ̀ yìí fún. 14 (C)Ìran rẹ yóò pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀, ìwọ yóò sì tànkálẹ̀ dé ìlà-oòrùn àti ìwọ̀-oòrùn, àti dé gúúsù àti àríwá. A ó sì bùkún gbogbo orílẹ̀-èdè ayé nípasẹ̀ ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ. 15 Èmi wà pẹ̀lú rẹ, èmi yóò sì pa ọ mọ́ ní ibikíbi tí ìwọ bá lọ, èmi yóò sì mú ọ padà wá sí ilẹ̀ yìí ní àlàáfíà. Èmi kì yóò fi ọ sílẹ̀ ní ìgbà kan, títí tí èmi yóò fi mú gbogbo ìlérí mi ṣẹ.”
16 Nígbà tí Jakọbu jí lójú oorun rẹ̀, ó rò nínú ara rẹ̀ pé, “Dájúdájú Olúwa ń bẹ ní ìhín yìí, èmi kò sì mọ̀.” 17 Ẹ̀rù sì bà á, ó sì wí pé, “Ìhín yìí ní ẹ̀rù gidigidi; ibí kì í ṣe ibòmíràn bí kò ṣe ilé Ọlọ́run, àní ẹnu ibodè ọ̀run nìyìí.”
18 Jakọbu sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀, ó sì gbé òkúta tí ó fi ṣe ìrọ̀rí lélẹ̀ bí ọ̀wọ́n, ó sì da òróró si lórí. 19 Ó sì pe orúkọ ibẹ̀ ní Beteli (Ilé Ọlọ́run) bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìlú náà ń jẹ́ Lusi tẹ́lẹ̀ rí.
20 Jakọbu sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ níbẹ̀ pé, “Bí Ọlọ́run yóò bá wà pẹ̀lú mi, tí yóò sì pa mí mọ́ ní ìrìnàjò mi tí mo ń lọ, tí yóò sì fún mi ní oúnjẹ láti jẹ àti aṣọ láti wọ̀, 21 tí mo sì padà sílé baba mi ní àlàáfíà, nígbà náà Olúwa ni yóò jẹ́ Ọlọ́run mi, 22 Òkúta yìí tí mo gbé kalẹ̀ bí ọ̀wọ́n yóò jẹ́ ilé Ọlọ́run, nínú gbogbo ohun tí ìwọ ó fi fún mi, èmi yóò sì fi ìdámẹ́wàá rẹ̀ fún ọ.”
13 (A)Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni ó kú nínú ìgbàgbọ́, láìrí àwọn ìlérí náà gbà, ṣùgbọ́n tí wọn rí wọn ni òkèrè réré, tí wọ́n sì gbá wọn mú, tí wọ́n sì jẹ́wọ́ pé àlejò àti àjèjì ni àwọn lórí ilẹ̀ ayé. 14 Nítorí pé àwọn tí o ń sọ irú ohun bẹ́ẹ̀ fihàn gbangba pé, wọn ń ṣe àfẹ́rí ìlú kan tí i ṣe tiwọn. 15 Àti nítòótọ́, ìbá ṣe pé wọ́n fi ìlú tiwọn tí jáde wá sí ọkàn, wọn ìbá ti rí ààyè padà. 16 (B)Ṣùgbọ́n nísinsin yìí wọ́n ń fẹ́ ìlú kan tí o dára jù bẹ́ẹ̀ lọ, èyí yìí ni ti ọ̀run: nítorí náà ojú wọn kò ti Ọlọ́run, pé kí a máa pé òun ni Ọlọ́run wọn; nítorí tí o ti pèsè ìlú kan sílẹ̀ fún wọn.
17 (C)Nípa ìgbàgbọ́ ni Abrahamu, nígbà tí a dán an wò láti, fi Isaaki rú ẹbọ: àní òun ẹni tí ó rí ìlérí gba múra tan láti fi ọmọ bíbí rẹ kan ṣoṣo rú ẹbọ. 18 (D)Nípa ẹni tí wí pé, “Nínú Isaaki ni a ó ti pe irú-ọmọ rẹ̀:” 19 Ó sì rò ó si pé Ọlọ́run tilẹ̀ lè gbé e dìde kúrò nínú òkú, bẹ́ẹ̀ ni, bí a bá sọ ọ́ lọ́nà àpẹẹrẹ, ó gbà á padà.
20 (E)Nípa ìgbàgbọ́ ní Isaaki súre fún Jakọbu àti Esau ní ti ohun tí ń bọ̀.
21 (F)Nípa ìgbàgbọ́ ni Jakọbu, nígbà tí o ń ku lọ, ó súre fún àwọn ọmọ Josẹfu ni ọ̀kọ̀ọ̀kan; ó sì sinmi ní ìtẹríba lé orí ọ̀pá rẹ̀.
22 (G)Nípa ìgbàgbọ́ ni Josẹfu, nígbà tí ó ń ku lọ, ó rántí ìjáde lọ àwọn ọmọ Israẹli; ó sì pàṣẹ ní ti àwọn egungun rẹ̀.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.