Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 50:1-8

Saamu ti Asafu

50 Olúwa, Ọlọ́run alágbára
    sọ̀rọ̀ kí o sì pe ayé jọ
    láti ìlà-oòrùn títí dé ìwọ̀ rẹ̀.
Láti Sioni wá, pípé ni ẹwà,
    Ọlọ́run tí ń tan ìmọ́lẹ̀
Ọlọ́run ń bọ̀,
    bẹ́ẹ̀ ni kì yóò dákẹ́,
iná yóò máa jó níwájú rẹ̀,
    àti ní àyíká rẹ̀ ni ẹ̀fúùfù líle yóò ti máa jà ká.
Yóò sì pe àwọn ọ̀run láti òkè wá jọ àti ayé,
    kí o le máa ṣe ìdárò àwọn ènìyàn rẹ̀.
“Kó àwọn ènìyàn mímọ́ jọ fún mi
    àwọn tí wọn fi ẹbọ dá májẹ̀mú fún mi.”
Àwọn ọ̀run yóò sì sọ̀rọ̀ òdodo rẹ̀,
    Nítorí Ọlọ́run fúnrarẹ̀ ni onídàájọ́.

“Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ènìyàn mi, èmi yóò si sọ̀rọ̀, ìwọ Israẹli, èmi yóò jẹ́rìí sí ọ:
    èmi ní Ọlọ́run, àní Ọlọ́run rẹ.
Èmi kí yóò bá ọ wí
    nítorí àwọn ìrúbọ rẹ,
tàbí ọrẹ ẹbọ sísun rẹ, èyí tí ó wà níwájú mi
    ní ìgbà gbogbo.

Saamu 50:22-23

22 “Ǹjẹ́ ìwọ ro èyí wò, ẹ̀yin tí ó gbàgbé Ọlọ́run.
    Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ èmi yóò fa yin ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, láìsí ẹni tí yóò gbà yin sílẹ̀.
23 Ẹni tí ó ba ní ẹbọ ọrẹ-ọpẹ́ bu ọlá fún mi; kí ó sì tún ọ̀nà rẹ̀ ṣe,
    kí èmi kí ó le fi ìgbàlà Ọlọ́run hàn án.”

Isaiah 9:18-10:4

18 Nítòótọ́ ìwà búburú ń jóni bí iná,
    yóò jó ẹ̀wọ̀n àti ẹ̀gún run,
yóò sì rán nínú pàǹtí igbó,
    tó bẹ́ẹ̀ tí yóò fi gòkè lọ bí ọ̀wọ́n èéfín ti í gòkè.
19 Nípasẹ̀ ìbínú Olúwa àwọn ọmọ-ogun
    ilẹ̀ náà yóò di gbígbẹ
àwọn ènìyàn yóò sì di ohun ìdáná,
    ẹnìkan kì yóò sì dá arákùnrin rẹ̀ sí.
20 Ní apá ọ̀tún wọn yóò jẹrun,
    síbẹ̀ ebi yóò sì máa pa wọ́n,
ní apá òsì, wọn yóò jẹ
    ṣùgbọ́n, kò ní tẹ́ wọn lọ́rùn.
    Ẹnìkọ̀ọ̀kan yóò sì máa jẹ ẹran-ara apá rẹ̀.
21 Manase yóò máa jẹ Efraimu, nígbà tí Efraimu yóò jẹ Manase
    wọn yóò parapọ̀ dojúkọ Juda.

Síbẹ̀síbẹ̀, ìbínú un rẹ̀ kò yí kúrò
    Ọwọ́ọ rẹ̀ sì wà ní gbígbéró.

10 Ègbé ni fún àwọn ti ń ṣe òfin àìṣòdodo
láti dún àwọn aláìní ní ẹ̀tọ́ wọn
    àti láti fa ọwọ́ ìdájọ́ sẹ́yìn kúrò
níwájú àwọn olùpọ́njú ènìyàn mi,
    Wọ́n sọ àwọn ọ̀pọ̀ di ìjẹ fún wọn.
    Wọ́n sì ń ja àwọn aláìní baba lólè.
Kí ni ìwọ yóò ṣe ní ọjọ́ ìṣirò
    nígbà tí ìparun bá ti ọ̀nà jíjìn wá?
Ta ni ìwọ yóò sá tọ̀ fún ìrànlọ́wọ́?
    Níbo ni ìwọ yóò fi ọrọ̀ rẹ sí?
Ohunkóhun kò ní ṣẹ́kù mọ́ bí kò ṣe láti tẹ̀ ba láàrín àwọn ìgbèkùn
    tàbí kí o ṣubú sáàrín àwọn tí a pa.

Pẹ̀lú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ìbínú rẹ̀ kò kúrò,
    ọwọ́ rẹ̀ sì tún gbé sókè.

Ìṣe àwọn Aposteli 7:1-8

Ọ̀rọ̀ Stefanu sí àwọn àjọ ìgbìmọ̀

Nígbà náà ni olórí àlùfáà wí pé, “Òtítọ́ ha ni àwọn ẹ̀sùn tí wọ́ fi kàn ọ́ bí?”

(A)Ní ìdáhùn sí èyí ó wí pé, “Ẹ̀yin arákùnrin àti ẹ̀yin baba, ẹ fetísílẹ̀ sí mi! Ọlọ́run ògo fi ara hàn fún Abrahamu baba wa, nígbà tí ó wà ni Mesopotamia, kí ó to ṣe àtìpó ni Harani. (B)Ọlọ́run wí fún un pé, ‘Jáde kúrò ní orílẹ̀-èdè rẹ àti kúrò lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ, lọ sí ilẹ̀ kan tí èmi yóò fihàn ọ́.’

(C)“Nígbà náà ni ó jáde kúrò ní ilẹ̀ àwọn ará Kaldea, ó sì ṣe àtìpó ni Harani. Lẹ́yìn ìgbà tí baba rẹ̀ sì kú, Ọlọ́run mú un sípò padà wá sí ilẹ̀ yìí, níbi tí ẹ̀yin ń gbé báyìí. (D)Kò sí fún un ni ìní kan, ànító bi ìwọ̀n ààyè ẹsẹ̀ kan. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ṣe ìlérí fún pé, òun yóò fi ilẹ̀ ìní náà fún un àti fún àwọn irú-ọmọ rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀, nígbà tí kò tí ì ní ọmọ. (E)Ọlọ́run sì sọ báyìí pé: ‘Irú-ọmọ rẹ yóò ṣe àtìpó ní ilẹ̀ àjèjì; wọn ó sì sọ wọn di ẹrú, wọn ó sì pọ́n wọn lójú fún irínwó ọdún (400). (F)Ọlọ́run wí pé, Orílẹ̀-èdè náà tí wọn yóò máa sìn, ni èmi ó dá lẹ́jọ́; lẹ́yìn náà ni wọn ó sì jáde kúrò, wọn ó sì wá sìn mí níhìn-ín yìí.’ (G)Ó sì fún Abrahamu ni májẹ̀mú ìkọlà. Abrahamu bí Isaaki, ó kọ ọ́ ní ilà ni ọjọ́ kẹjọ tí ó bí i. Isaaki sí bí Jakọbu, Jakọbu sì bí àwọn baba ńlá méjìlá.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.