Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Ti Dafidi. Saamu.
110 (A)Olúwa sọ fún Olúwa mi pé:
“Ìwọ jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi,
títí èmi yóò fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ
di àpótí ìtìsẹ̀ rẹ.”
2 Olúwa yóò na ọ̀pá agbára rẹ̀
láti Sioni wá, ìwọ jẹ ọba láàrín àwọn ọ̀tá rẹ.
3 Àwọn ènìyàn rẹ jẹ́ ọ̀rẹ́ àtinúwá
ní ọjọ́ ìjáde ogun rẹ, nínú ẹwà mímọ́,
láti inú òwúrọ̀ wá ìwọ ni ìrì ẹwà rẹ.
4 (B)Olúwa ti búra,
kò sì í yí ọkàn padà pé,
“Ìwọ ni àlùfáà,
ní ipasẹ̀ Melkisedeki.”
5 Olúwa, ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ni
yóò lu àwọn ọba bolẹ̀ ni ọjọ́ ìbínú rẹ̀
6 Yóò ṣe ìdájọ́ láàrín kèfèrí,
yóò kún ibùgbé wọn pẹ̀lú òkú ara;
yóò fọ́n àwọn olórí ká sí orí ilẹ̀ ayé tí ó gbòòrò.
7 Yóò mu nínú odò ṣíṣàn ní ọ̀nà:
nítorí náà ni yóò ṣe gbé orí sókè.
22 (A)Nígbà náà ni Farao pàṣẹ yìí fún gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀ pé; “Gbogbo ọmọkùnrin tí a bí ni kí ẹ gbé jù sínú odò Naili, ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ọmọbìnrin ni kí ẹ jẹ́ kí wọn ó wà láààyè.”
Ìbí Mose
2 Ó sì ṣe, ọkùnrin ará ilé Lefi kan fẹ́ ọmọbìnrin ará Lefi kan ni ìyàwó. 2 (B)Obìnrin náà sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan. Nígbà tí ó rí í pé ọmọ náà rẹwà, ó gbé ọmọ náà pamọ́ fún oṣù mẹ́ta. 3 Ṣùgbọ́n nígbà tí kò le è gbé e pamọ́ mọ́, ó fi ewé papirusi hun apẹ̀rẹ̀, ó sì fi ọ̀dà àti òjé igi sán apẹ̀rẹ̀ náà. Ó sì tẹ́ ọmọ náà sínú rẹ̀, ó sì gbe é sí inú eèsún ni etí odò Naili. 4 Arábìnrin rẹ̀ dúró ni òkèèrè láti wo ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí ọmọ náà.
5 (C)Nígbà náà ni ọmọbìnrin Farao sọ̀kalẹ̀ wá sí etí odò Naili láti wẹ̀, àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ sì ń rìn ni etí bèbè odò. Ó sì ri apẹ̀rẹ̀ náà ni àárín eèsún, ó sì rán ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin kan láti lọ gbé e wá, 6 ó ṣí i, ó sì rí ọmọ náà. Ọmọ náà ń sọkún, àánú ọmọ náà sì ṣe é. Ó wí pé “Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Heberu ni èyí.”
7 Nígbà náà ni arábìnrin rẹ̀ béèrè lọ́wọ́ ọmọbìnrin Farao pé “Ṣé kí èmi lọ wá ọ̀kan lára àwọn obìnrin Heberu wá fún ọ láti bá ọ tọ́jú ọmọ náà?”
8 Ó sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni; lọ.” Arábìnrin náà sì lọ, ó sì pe ìyá ọmọ náà wá, 9 Ọmọbìnrin Farao sì wí fún un pé, “Gba ọmọ yìí kí o sì tọ́jú rẹ̀ fún mi, èmi yóò san owó iṣẹ́ ẹ̀ rẹ fún ọ” Ọmọbìnrin náà sì gbé ọmọ náà lọ, ó sì tọ́jú rẹ̀. 10 Nígbà tí ọmọ náà sì dàgbà, ó mú un tọ ọmọbìnrin Farao wá, ó sì di ọmọ rẹ̀. Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Mose, ó wí pé “Nítorí tí mo fà á jáde nínú omi.”
23 (A)Nípa ìgbàgbọ́ ní àwọn òbí Mose pa a mọ́ fún oṣù mẹ́ta nígbà tí a bí i, nítorí tiwọn rí i ní arẹwà ọmọ; wọn kò sì bẹ̀rù àṣẹ ọba.
24 (B)Nípa ìgbàgbọ́ ni Mose, nígbà tí o dàgbà, ó kọ̀ ki a máa pé òun ni ọmọ ọmọbìnrin Farao; 25 o kúkú yàn láti máa ba àwọn ènìyàn Ọlọ́run jìyà, ju jíjẹ fàájì ẹ̀ṣẹ̀ fún ìgbà díẹ̀. 26 Ó ka ẹ̀gàn Kristi si ọrọ̀ tí ó pọ̀jù àwọn ìṣúra Ejibiti lọ: Nítorí tí ó ń wo èrè náà.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.