Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 1

ÌWÉ KÌN-ÍN-NÍ

Saamu 1–41

(A)Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà,
    tí kò rìn ní ìmọ̀ àwọn ènìyàn búburú,
ti kò dúró ní ọ̀nà àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,
    tàbí tí kò sì jókòó ní ibùjókòó àwọn ẹlẹ́gàn.
Ṣùgbọ́n ayọ̀ inú rẹ̀ wà nínú òfin Olúwa
    àti nínú òfin rẹ̀ ni ó ń ṣe àṣàrò ní ọ̀sán àti òru.
Ó dàbí igi tí a gbìn sí etí odò tí ń sàn,
    tí ń so èso rẹ̀ jáde ní àkókò rẹ̀
tí ewé rẹ̀ kì yóò rẹ̀.
    Ohunkóhun tí ó dáwọ́lé, ni yóò máa yọrí sí rere.

Kò le rí bẹ́ẹ̀ fún àwọn ènìyàn búburú!
    Wọn yóò dàbí ìyàngbò ọkà
    tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ dànù.
Nítorí náà àwọn ènìyàn búburú kì yóò le è dìde dúró ní ìdájọ́,
    bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kì yóò le è dúró ní àwùjọ àwọn olódodo.

Nítorí Olúwa ń ṣọ́ ọ̀nà àwọn olódodo,
    ṣùgbọ́n ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú ni yóò ṣègbé.

Òwe 5

Ìkìlọ̀ láti yàgò fún àgbèrè

Ọmọ mi, fiyèsí ọgbọ́n mi,
    kí o sì dẹtí rẹ sí òye mi,
Kí ìwọ sì lè ní ìṣọ́ra
    kí ètè rẹ sì le pa ìmọ̀ mọ́.
Nítorí ètè àwọn àjèjì obìnrin a máa sun bi oyin,
    ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì kúnná ju òróró lọ.
Ṣùgbọ́n ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín, ó korò ju òróǹró lọ,
    ó mú bí idà olójú méjì.
Ẹsẹ̀ rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí ọ̀nà ikú
    ìgbésẹ̀ rẹ̀ lọ tààrà sí ibojì òkú.
Kí ìwọ má ba à já ipa ọ̀nà ìyè;
    ọ̀nà rẹ̀ rí pálapàla, ṣùgbọ́n kò tilẹ̀ mọ́.

Nítorí náà, ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ dẹtí sí mi,
    kí ẹ̀yin kí ó má ṣe yàgò kúrò nínú ọ̀rọ̀ tí mo sọ.
Rìn ní ọ̀nà tí ó jìnnà sí ti rẹ̀,
    má ṣe súnmọ́ ẹnu-ọ̀nà ilé rẹ̀
Àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ yóò gbé gbogbo ọlá rẹ lé ẹlòmíràn lọ́wọ́
    àti ọjọ́ ayé rẹ fún ìkà ènìyàn.
10 Kí a má ba à fi ọrọ̀ rẹ fún àjèjì ènìyàn,
    kí làálàá rẹ sì sọ ilé ẹlòmíràn di ọlọ́rọ̀.
11 Ní ìgbẹ̀yìn ayé rẹ ìwọ yóò kérora,
    nígbà tí agbára rẹ àti ara rẹ bá ti joro tán
12 Ìwọ yóò wí pé, “Mo ti kórìíra ẹ̀kọ́ tó!
    Ọkàn mi ṣe wá kórìíra ìbáwí!
13 N kò gbọ́rọ̀ sí àwọn olùkọ́ mi lẹ́nu,
    tàbí kí n fetí sí àwọn tí ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́.
14 Mo ti bẹ̀rẹ̀ ìparun pátápátá
    ní àárín gbogbo àwùjọ ènìyàn.”

15 Mu omi láti inú kànga tìrẹ
    Omi tí ń sàn láti inú kànga rẹ.
16 Ó ha yẹ kí omi ìsun rẹ kún àkúnya sí ojú ọ̀nà
    àti odò tí ń sàn lọ sí àárín ọjà?
17 Jẹ́ kí wọn jẹ́ tìrẹ nìkan,
    má ṣe ṣe àjọpín wọn pẹ̀lú àjèjì láéláé.
18 Jẹ́ kí orísun rẹ kí ó ní ìbùkún;
    kí ìwọ ó sì máa yọ nínú aya ìgbà èwe rẹ.
19 Abo àgbọ̀nrín tó dára, ìgalà tí ó wu ni jọjọ,
    Jẹ́ kí ọmú rẹ̀ kí ó máa fi ayọ̀ fún ọ nígbà gbogbo,
    kí o sì máa yọ̀ nínú ìfẹ́ rẹ̀ nígbàkúgbà.
20 Ọmọ mi, èéṣe tí ìwọ ó fi máa yọ̀ nínú ìfẹ́ obìnrin panṣágà,
    tí ìwọ ó sì fi dì mọ́ ìyàwó ẹlòmíràn?

21 Nítorí ọ̀nà ènìyàn kò fi ara sin rárá fún Olúwa
    Ó sì ń gbé gbogbo ọ̀nà rẹ̀ yẹ̀ wò
22 Ìwà búburú ènìyàn búburú ni yóò mú kó bọ́ sínú okùn;
    okùn ẹ̀ṣẹ̀ ara rẹ̀ yóò sì dìímú.
23 Yóò kú ní àìgba ẹ̀kọ́
    ìwà òmùgọ̀ ara rẹ̀ yóò sì mú kí ó máa ṣìnà kiri.

Luku 14:34-35

34 (A)“Iyọ̀ dára: ṣùgbọ́n bí iyọ̀ bá di òbu, kín ni a ó fi mú un dùn? 35 Kò yẹ fún ilẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò yẹ fún ààtàn; bí kò ṣe pé kí a kó o dànù.

“Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́ kí ó gbọ́.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.