Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 92:1-4

Saamu. Orin. Fún ọjọ́ Ìsinmi

92 Ohun rere ni láti máa fi ọpẹ́ fún Olúwa
    àti láti máa kọrin sí orúkọ rẹ̀, Ọ̀gá-ògo,
Láti kéde ìfẹ́ rẹ̀ ní òwúrọ̀
    àti òtítọ́ rẹ̀ ní alẹ́
Lára ohùn èlò orin olókùn mẹ́wàá
    àti lára ohun èlò orin haapu.

Nítorí ìwọ ni ó mú inú mi dùn
    nípa iṣẹ́ rẹ Olúwa;
èmi kọrin ayọ̀ sí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.

Saamu 92:12-15

12 Olódodo yóò gbèrú bí i igi ọ̀pẹ,
    wọn yóò dàgbà bí i igi kedari Lebanoni;
13 Tí a gbìn sí ilé Olúwa,
    Wọn yóò rúwé nínú àgbàlá Ọlọ́run wa.
14 Wọn yóò máa so èso ní ìgbà ogbó,
    wọn yóò dúró ní àkọ̀tun, wọn yóò sì tutù nini,
15 Láti fihàn pé “Ẹni ìdúró ṣinṣin ni Olúwa;
    òun ni àpáta mi, kò sì ṣí aburú
    kankan nínú rẹ̀.”

Isaiah 30:8-17

Lọ nísinsin yìí, kí o sì kọ ọ́ sí ara wàláà fún wọn,
    tẹ̀ ẹ́ sí ara ìwé kíká,
pé fún àwọn ọjọ́ tí ó ń bọ̀
    kí ó sì lè jẹ́ ẹ̀rí ayérayé.
Àwọn wọ̀nyí jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ ènìyàn
    àti ẹlẹ́tanu ọmọ,
àwọn ọmọ tí wọn kò ṣetán láti tẹ́tí sí
    ìtọ́ni Olúwa.
10 Wọ́n sọ fún àwọn aríran pé,
    “Ẹ má ṣe rí ìran mọ́!”
Àti fún àwọn wòlíì,
    “Ẹ má ṣe fi ìran ohun tí ó tọ́ hàn wá mọ́!
Ẹ sọ ohun tí ó tura fún wa,
    ẹ sàsọtẹ́lẹ̀ ẹ̀tàn.
11 Ẹ fi ọ̀nà yìí sílẹ̀,
    ẹ kúrò ní ọ̀nà yìí
ẹ dẹ́kun à ń dojú ìjà kọ wá
    pẹ̀lú Ẹni Mímọ́ Israẹli!”

12 Nítorí náà, èyí ni ohun tí Ẹni Mímọ́ Israẹli wí:

“Nítorí pé ẹ ti kọ ọ̀rọ̀ yìí sílẹ̀,
    ẹ gbára lé ìnilára
    kí ẹ sì gbẹ́kẹ̀lé ẹ̀tàn,
13 ẹ̀ṣẹ̀ yìí yóò rí fún ọ
    gẹ́gẹ́ bí ògiri gíga, tí ó sán tí ó sì fì
    tí ó sì wó lójijì, àti ní ìṣẹ́jú kan.
14 Yóò sì fọ́ ọ sí wẹ́wẹ́ bí àpáàdì
    tí a fọ́ pátápátá
àti pé a kò ní rí ẹ̀rún kan nínú àfọ́kù rẹ̀,
    fún mímú èédú kúrò nínú ààrò
    tàbí gbígbọ́n omi jáde kúrò nínú àmù.”

15 Èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè, Ẹni Mímọ́ ti Israẹli wí:

“Nínú ìrònúpìwàdà àti ìsinmi ni ìgbàlà rẹ wà,
    ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé ni agbára rẹ wà,
    ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò ní ọ̀kankan nínú wọn.
16 Ẹ̀yin wí pé, ‘bẹ́ẹ̀ kọ́, àwa yóò sálọ lórí ẹṣin.’
    Nítorí náà ẹ̀yin yóò sá!
Ẹ̀yin wí pé, ‘Àwa yóò gun àwọn ẹṣin tí ó yára lọ.’
    Nítorí náà àwọn tí ń lé e yín yóò yára!
17 Ẹgbẹ̀rún yóò sá
    nípa ìdẹ́rùbà ẹnìkan;
nípa ìdẹ́rùbà ẹni márùn-ún
    gbogbo yín lẹ ó sálọ,
títí a ó fi yín sílẹ̀
    àti gẹ́gẹ́ bí igi àsíá ní orí òkè,
    gẹ́gẹ́ bí àsíá lórí òkè.”

Johanu 16:1-4

16 “Nǹkan wọ̀nyí ni mo ti sọ fún yín, kí a má ba à mú yín yapa kúrò. (A)Wọ́n ó yọ yín kúrò nínú Sinagọgu: àní, àkókò ń bọ̀, tí ẹnikẹ́ni tí ó bá pa yín, yóò rò pé òun ń ṣe ìsìn fún Ọlọ́run. Nǹkan wọ̀nyí ni wọ́n ó sì ṣe, nítorí tí wọn kò mọ Baba, wọn kò sì mọ̀ mí. Ṣùgbọ́n nǹkan wọ̀nyí ni mo ti sọ fún yín, pé nígbà tí wákàtí wọn bá dé, kí ẹ lè rántí wọn pé mo ti wí fún yín. Ṣùgbọ́n èmi kò sọ nǹkan wọ̀nyí fún yín láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ wá, nítorí tí mo wà pẹ̀lú yín.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.