Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 62

Fún adarí orin. Fun Jedutuni. Saamu Dafidi.

62 Nínú Ọlọ́run nìkan ni ọkàn mi ti rí ìsinmi;
    ìgbàlà mi ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá.
Òun nìkan ní àpáta mi àti ìgbàlà mi;
    Òun ni ààbò mi, a kì yóò sí mi ní ipò padà.

Ẹ̀yin ó ti máa kọ́lú ènìyàn kan pẹ́ tó?
    Gbogbo yín ni ó fẹ́ pa á,
    bí ògiri tí ó fẹ́ yẹ̀, àti bí ọgbà tí ń wó lọ?
Kìkì èrò wọn ni láti bì ṣubú
    kúrò nínú ọlá rẹ̀;
    inú wọn dùn sí irọ́.
Wọ́n ń fi ẹnu wọn súre,
    ṣùgbọ́n wọ́n ń gégùn ún nínú ọkàn wọn. Sela.

Nínú Ọlọ́run nìkan ni ìsinmi wà, ìwọ Ọlọ́run mi.
    Ìrètí mi wá láti ọ̀dọ̀ rẹ.
Òun nìkan ní àpáta àti ìgbàlà mi;
    Òun ni ààbò mi, a kì yóò ṣí mi ní ipò.
Ìgbàlà mi àti ògo mi dúró nínú Ọlọ́run;
    Òun ní àpáta ńlá mi, àti ààbò mi.
Gbẹ́kẹ̀lé ní gbogbo ìgbà, ẹ̀yin ènìyàn;
    tú ọkàn rẹ jáde sí i,
nítorí Ọlọ́run ni ààbò wa.

Nítòótọ́, asán ni àwọn ọmọ ènìyàn, èké
    sì ni àwọn olóyè, wọ́n gòkè nínú ìwọ̀n,
    lápapọ̀ wọ́n jẹ́ èémí.
10 Má ṣe gbẹ́kẹ̀lé ìnilára,
    tàbí gbéraga nínú olè jíjà,
nítòótọ́ bí ọrọ̀ rẹ̀ ń pọ̀ sí i,
    má ṣe gbẹ́kẹ̀ rẹ lé wọn.

11 Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kejì, ni mo
    gbọ́ èyí pé, ti Ọlọ́run ni agbára
12 (A)Pẹ̀lúpẹ̀lú, Olúwa, tìrẹ ni àánú
    nítorí tí ìwọ san án fún olúkúlùkù ènìyàn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀.

Amosi 6:8-14

Olúwa Kórìíra Ìgbéraga Ọmọ Israẹli

Olúwa Olódùmarè ti búra fúnrarẹ̀, Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun sì ti wí pé:

“Mo kórìíra ìgbéraga Jakọbu
    n kò sì ní inú dídùn sí odi alágbára rẹ̀
Èmi yóò sì fa ìlú náà lé wọn lọ́wọ́
    àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀.”

Bí Ọkùnrin mẹ́wàá bá ṣẹ́kù nínú ilé kan, àwọn náà yóò kú 10 Bí ẹbí tí ó yẹ kí ó gbé òkú wọn jáde fún sínsin bá wọlé, bí o ba sì béèrè pé ǹjẹ́ ẹnìkan wa tí ó fi ara pamọ́ níbẹ̀, “Ǹjẹ́ ẹnìkankan wà lọ́dọ̀ yín?” tí ó bá sì dáhùn wí pé, “Rárá,” nígbà náà ni yóò wí pé, “Pa ẹnu rẹ mọ́ àwa kò gbọdọ̀ dárúkọ Olúwa.”

11 Nítorí Olúwa tí pa àṣẹ náà,
    Òun yóò sì wó ilé ńlá náà lulẹ̀ túútúú
    Àti àwọn ilé kéékèèkéé sí wẹ́wẹ́.

12 Ǹjẹ́ ẹṣin a máa sáré lórí àpáta bí?
    Ǹjẹ́ ènìyàn a máa fi akọ màlúù kọ ilẹ̀ níbẹ̀?
Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti yí òtítọ́ padà sí májèlé
    ẹ sì ti sọ èso òdodo di ìkorò.
13 Ẹ̀yin yọ̀ torí ìṣẹ́gun lórí Lo-Debari
    Ẹ̀yin sì wí pé, “Ṣé kì í ṣe agbára wa ni àwa fi gba Karnaimu?”

14 Nítorí Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun wí pé,
    “Èmi yóò gbé orílẹ̀-èdè kan dìde sí ọ ìwọ Israẹli,
wọn yóò pọ́n yín lójú ní gbogbo ọ̀nà,
    láti Lebo-Hamati, títí dé pẹ̀tẹ́lẹ̀ Arabah.”

Ìfihàn 3:14-22

Sí ìjọ Laodikea

14 (A)“Àti sí angẹli ìjọ ní Laodikea kọ̀wé:

Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni ẹni tí ń jẹ́ Àmín wí, ẹlẹ́rìí olódodo àti olóòtítọ́, olórí ìṣẹ̀dá Ọlọ́run:

15 Èmi mọ̀ iṣẹ́ rẹ, pé ìwọ kò gbóná bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò tútù: èmi ìbá fẹ́ pé kí ìwọ kúkú tutù, tàbí kí ìwọ kúkú gbóná. 16 Ǹjẹ́ nítorí tí ìwọ lọ wọ́ọ́rọ́, tí o kò si gbóná, bẹ́ẹ̀ ni tí o kò tutù, èmi yóò pọ̀ ọ́ jáde kúrò ni ẹnu mi. 17 (B)Nítorí tí ìwọ wí pé, Èmi ní ọrọ̀, èmi sì ń pọ̀ sí i ni ọrọ̀, èmi kò sì ṣe aláìní ohunkóhun; tí ìwọ kò sì mọ̀ pé, òsì ni ìwọ, ẹni-ìkáàánú, tálákà, afọ́jú, àti ẹni ìhòhò: 18 Èmi fún ọ ni ìmọ̀ràn pé kí o ra wúrà lọ́wọ́ mi tí a ti dà nínú iná, kí ìwọ lè di ọlọ́rọ̀; àti aṣọ funfun, kí ìwọ lè fi wọ ara rẹ̀, àti kí ìtìjú ìhòhò rẹ̀ má ba hàn kí ìwọ sì fi ohun ìkunra kun ojú rẹ̀, kí ìwọ lè ríran.

19 (C)Gbogbo àwọn ti èmi bá fẹ́ ni èmi ń bá wí, tí mo sì ń nà: nítorí náà, ní ìtara, kì ìwọ sì ronúpìwàdà. 20 Kíyèsi i, èmi dúró ni ẹnu ìlẹ̀kùn, èmi sì ń kànkùn, bí ẹnikẹ́ni bá gbọ́ ohun mi, tí ó sì ṣí ìlẹ̀kùn, èmi yóò sì wọlé tọ̀ ọ́ wá, èmi yóò sì máa bá a jẹun, àti òun pẹ̀lú mi.

21 Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun ni èmi yóò fi fún láti jókòó pẹ̀lú mi lórí ìtẹ́ mi, bí èmi pẹ̀lú ti ṣẹ́gun, tí mo sì jókòó pẹ̀lú Baba mi lórí ìtẹ́ rẹ̀. 22 Ẹni tí ó bá létí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.